< Psalms 60 >
1 For the choirmaster. To the tune of “The Lily of the Covenant.” A Miktam of David for instruction. When he fought Aram-naharaim and Aram-zobah, and Joab returned and struck down 12,000 Edomites in the Valley of Salt. You have rejected us, O God; You have broken us; You have been angry; restore us!
Fún adarí orin. Tí ohùn “Lílì ti Májẹ̀mú.” Miktamu ti Dafidi. Fún ìkọ́ni. Nígbà tí ó bá Aramu-Naharaimu àti Siria-Soba jà, àti nígbà tí Joabu yípadà tí ó sì pa ẹgbẹ̀rún méjìlá àwọn ará Edomu ní àfonífojì Iyọ̀. Ìwọ ti kọ̀ wá sílẹ̀, Ọlọ́run, ìwọ ti tú wa ká, ìwọ ti bínú nísinsin yìí, tún ara rẹ yípadà sí wa.
2 You have shaken the land and torn it open. Heal its fractures, for it is quaking.
Ìwọ ti mú ilẹ̀ wárìrì, ìwọ ti fọ́ ọ; mú fífọ́ rẹ̀ bọ̀ sípò, nítorí tí ó mì.
3 You have shown Your people hardship; we are staggered from the wine You made us drink.
Ìwọ ti fi ìgbà ewu han àwọn ènìyàn rẹ; ìwọ fún wa ní wáìnì tí ó máa ń ta wá gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n.
4 You have raised a banner for those who fear You, that they may flee the bow.
Àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, ní ìwọ fi ọ̀págun fún kí a lè fihàn nítorí òtítọ́. (Sela)
5 Respond and save us with Your right hand, that Your beloved may be delivered.
Fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ gbà wá, kí o sì ràn wá lọ́wọ́, kí a lè gba àwọn tí o fẹ́ là.
6 God has spoken from His sanctuary: “I will triumph! I will parcel out Shechem and apportion the Valley of Succoth.
Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ láti ibi mímọ́ rẹ̀: “Ní ayọ̀, èmi ó pọ Ṣekemu jáde èmi ó sì wọ́n àfonífojì Sukkoti.
7 Gilead is Mine, and Manasseh is Mine; Ephraim is My helmet, Judah is My scepter.
Tèmi ni Gileadi, tèmi sì ni Manase; Efraimu ni àṣíborí mi, Juda sì ni ọ̀pá àṣẹ mi.
8 Moab is My washbasin; upon Edom I toss My sandal; over Philistia I shout in triumph.”
Moabu ní ìkòkò ìwẹsẹ̀ mi, lórí Edomu ní mo bọ́ bàtà mi sí; lórí Filistia ni mo kígbe ayọ̀.”
9 Who will bring me to the fortified city? Who will lead me to Edom?
Ta ni yóò mú mi wá sí ìlú olódi nì? Ta ni yóò tọ́ mí lọ sí Edomu?
10 Have You not rejected us, O God? Will You no longer march out, O God, with our armies?
Kì í ha ń ṣe ìwọ, Ọlọ́run, tí ó ti kọ̀ wá sílẹ̀ tí o kò sì bá ogun wa jáde mọ́?
11 Give us aid against the enemy, for the help of man is worthless.
Fún wa ní ìrànlọ́wọ́ lórí àwọn ọ̀tá, nítorí asán ni ìrànlọ́wọ́ ènìyàn.
12 With God we will perform with valor, and He will trample our enemies.
Nípa Ọlọ́run ni a óò ní ìṣẹ́gun, yóò sì tẹ àwọn ọ̀tá wa mọ́lẹ̀.