< Psalms 58 >

1 For the choirmaster. To the tune of “Do Not Destroy.” A Miktam of David. Do you indeed speak justly, O rulers? Do you judge uprightly, O sons of men?
Fún adarí orin. Tí ohùn “Má ṣe parun.” Ti Dafidi. Miktamu. Ẹ̀yin ha ń sọ òdodo nítòótọ́ ẹ̀yin ìjọ ènìyàn? Ǹjẹ́ ẹ̀yin ń ṣe ìdájọ́ tí ó ṣe títọ́ ẹ̀yìn ọmọ ènìyàn?
2 No, in your hearts you devise injustice; with your hands you mete out violence on the earth.
Bẹ́ẹ̀ kọ́, nínú ọkàn yín ẹ̀yìn ń gbèrò àìṣòdodo, ọwọ́ yín sì tú ìwà ipá jáde ni ayé.
3 The wicked are estranged from the womb; the liars go astray from birth.
Ní inú ìyá wọn wá ni ènìyàn búburú tí ṣìnà, lójúkan náà tí a ti bí wọn, wọn a máa ṣèké.
4 Their venom is like the venom of a snake, like a cobra that shuts its ears,
Oró wọn dàbí oró ejò, wọn dàbí adití ejò paramọ́lẹ̀ tí ó di ara rẹ̀ ni etí,
5 refusing to hear the tune of the charmer who skillfully weaves his spell.
tí kò ní gbọ́ ìpè àwọn atunilójú, bí ó ti wù kí ó máa fi ọgbọ́n ṣe ìtujú tó.
6 O God, shatter their teeth in their mouths; O LORD, tear out the fangs of the lions.
Ká eyín ẹnu wọn, Ọlọ́run; ní ẹnu wọn, ká ọ̀gàn àwọn ọmọ kìnnìún, Olúwa.
7 May they vanish like water that runs off; when they draw the bow, may their arrows be blunted.
Jẹ́ kí wọn parẹ́ bí omi tó ń sàn lọ; nígbà tí ó bá fa ọfà rẹ̀, kí ọ̀kọ̀ wọn kí ó ṣẹ́.
8 Like a slug that dissolves in its slime, like a woman’s stillborn child, may they never see the sun.
Jẹ́ kí wọn rí bí ìgbín tí rẹ̀ dànù tí ó sì ṣègbé bí ọmọ tí oṣù rẹ̀ kò pé, kí wọn má ṣe rí oòrùn.
9 Before your pots can feel the burning thorns— whether green or dry— He will sweep them away.
Kí ìkòkò yín kí ó tó mọ ìgbóná ẹ̀gún; bóyá ní tútù tàbí ní gbígbẹ, yóò fi ìjì gbá wọn lọ.
10 The righteous will rejoice when they see they are avenged; they will wash their feet in the blood of the wicked.
Olódodo yóò yọ̀ nígbà a bá ń gbẹ̀san wọn, nígbà tí wọn bá wẹ ẹsẹ̀ wọn nínú ẹ̀jẹ̀ ènìyàn búburú.
11 Then men will say, “There is surely a reward for the righteous! There is surely a God who judges the earth!”
Àwọn ènìyàn yóò wí pé, “Lóòtítọ́ èrè àwọn ń bẹ fún olódodo; lóòtítọ́ òun ni Ọlọ́run tí ń ṣe ìdájọ́ ní ayé.”

< Psalms 58 >