< Psalms 57 >

1 For the choirmaster. To the tune of “Do Not Destroy.” A Miktam of David, when he fled from Saul into the cave. Have mercy on me, O God, have mercy, for in You my soul takes refuge. In the shadow of Your wings I will take shelter until the danger has passed.
Fún adarí orin. Ní ohùn “Má ṣe parun.” Ti Dafidi. Miktamu. Nígbà tí ó sá níwájú Saulu lọ sínú ihò òkúta. Ṣàánú fún mi, Ọlọ́run, ṣàánú fún mi, nítorí nínú rẹ ni ààbò ọkàn mí wà. Èmi o fi ààbò mí sí ibi ìyẹ́ apá rẹ títí tí ewu yóò fi kọjá lọ.
2 I cry out to God Most High, to God who fulfills His purpose for me.
Mo kígbe sókè sí Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo jùlọ, sí Ọlọ́run tó ń pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́ fún mi.
3 He reaches down from heaven and saves me; He rebukes those who trample me. (Selah) God sends forth His loving devotion and His truth.
Òun yóò ránṣẹ́ láti ọ̀run wá, yóò sì gbà mí, bí ẹni tí ń fẹ́ gbé mi mì tilẹ̀ ń kẹ́gàn mi. Ọlọ́run yóò rán àánú rẹ̀ àti òdodo rẹ̀ jáde.
4 My soul is among the lions; I lie down with ravenous beasts— with men whose teeth are spears and arrows, whose tongues are sharp swords.
Mo wà ní àárín àwọn kìnnìún; mo dùbúlẹ̀ ni abẹ́ àwọn ẹ̀dá búburú, àwọn ènìyàn tí eyín wọn dàbí ọ̀kọ̀ àti ọfà ẹni tí ahọ́n rẹ̀ jẹ́ idà mímú.
5 Be exalted, O God, above the heavens; may Your glory cover all the earth.
Kí a yìn ọ́ Ọlọ́run, ju ọ̀run lọ, kí ògo rẹ kò ju ti gbogbo ayé lọ.
6 They spread a net for my feet; my soul was despondent. They dug a pit before me, but they themselves have fallen into it!
Wọ́n ti ta àwọ̀n sílẹ̀ fún ẹsẹ̀ mi: a tẹ orí ọkàn mi ba nínú ìtìjú, wọ́n gbẹ́ kòtò sí ọ̀nà mi: ṣùgbọ́n wọ́n ti jì síbẹ̀ fún ara wọn.
7 My heart is steadfast, O God, my heart is steadfast. I will sing and make music.
Ọkàn mi ti múra Ọlọ́run; ọkàn mi ti múra, èmi ó kọrin, èmi ó si máa kọrin ìyìn.
8 Awake, my glory! Awake, O harp and lyre! I will awaken the dawn.
Jí, ìwọ ọkàn mi! Jí, ohun orin èlò àti dùùrù! Èmi tìkára mi, yóò sì jí ní kùtùkùtù.
9 I will praise You, O Lord, among the nations; I will sing Your praises among the peoples.
Èmi ó máa yìn ọ́, Olúwa, láàrín àwọn orílẹ̀-èdè; èmi ó máa kọrin sí ọ láàrín àwọn ènìyàn.
10 For Your loving devotion reaches to the heavens, and Your faithfulness to the clouds.
Nítorí títóbi ní ìfẹ́ rẹ, tí ó dé ọ̀run; òtítọ́ rẹ tàn dé àwọsánmọ̀.
11 Be exalted, O God, above the heavens; may Your glory cover all the earth.
Gbígbéga ni ọ́, Ọlọ́run, ju àwọn ọ̀run lọ; kí ògo rẹ kí ó ju gbogbo ayé lọ.

< Psalms 57 >