< Psalms 35 >
1 Of David. Contend with my opponents, O LORD; fight against those who fight against me.
Ti Dafidi. Olúwa, gbógun ti àwọn tí ń gbóguntì mí; kí o sì kọ ojú ìjà sí àwọn tí ó ń bá mi í jà!
2 Take up Your shield and buckler; arise and come to my aid.
Di asà àti àpáta mú, kí o sì dìde fún ìrànlọ́wọ́ mi!
3 Draw the spear and javelin against my pursuers; say to my soul: “I am your salvation.”
Fa idà àti ọ̀kọ̀ yọ kí o sì dojúkọ àwọn tí ń lé mi. Sọ fún ọkàn mi pé, “Èmi ni ìgbàlà rẹ.”
4 May those who seek my life be disgraced and put to shame; may those who plan to harm me be driven back and confounded.
Kí wọn kí ó dààmú, kí a sì ti àwọn tí ń lépa ọkàn mi lójú; kí a sì mú wọn padà, kí a sì dààmú àwọn tí ń gbèrò ìpalára mi.
5 May they be like chaff in the wind, as the angel of the LORD drives them away.
Jẹ́ kí wọn dàbí ìyàngbò níwájú afẹ́fẹ́, kí angẹli Olúwa kí ó máa lé wọn kiri.
6 May their path be dark and slick, as the angel of the LORD pursues.
Jẹ́ kí ọ̀nà wọn kí ó ṣókùnkùn, kí ó sì máa yọ́, kí angẹli Olúwa kí ó máa lépa wọn!
7 For without cause they laid their net for me; without reason they dug a pit for my soul.
Nítorí pé, ní àìnídìí ni wọ́n dẹ àwọ̀n wọn sílẹ̀ fún mi, ní àìnídìí ni wọ́n wa kòtò sílẹ̀ fún ọkàn mi.
8 May ruin befall them by surprise; may the net they hid ensnare them; may they fall into the hazard they created.
Kí ìparun kí ó wá sí orí rẹ̀ ní òjijì. Àwọ̀n rẹ̀ tí ó dẹ, kí ó mú òun tìkára rẹ̀; kí wọn ṣubú sínú kòtò sí ìparun ara rẹ̀.
9 Then my soul will rejoice in the LORD and exult in His salvation.
Nígbà náà ni ọkàn mi yóò yọ̀ nínú Olúwa, àní, yóò sì máa yọ̀ nínú ìgbàlà rẹ̀.
10 All my bones will exclaim, “Who is like You, O LORD, who delivers the afflicted from the aggressor, the poor and needy from the robber?”
Gbogbo egungun mi yóò wí pé, “Ta ni ó dàbí ì ìwọ Olúwa? O gba tálákà lọ́wọ́ àwọn tí ó lágbára jù ú lọ, tálákà àti aláìní lọ́wọ́ ẹni tí ń fi ṣe ìkógun?”
11 Hostile witnesses come forward; they make charges I know nothing about.
Àwọn ẹlẹ́rìí èké dìde; wọ́n ń bi mi ní ohun tí èmi kò mọ̀.
12 They repay me evil for good, to the bereavement of my soul.
Wọ́n fi búburú san ìre fún mi; láti sọ ọkàn mi di òfo.
13 Yet when they were ill, I put on sackcloth; I humbled myself with fasting, but my prayers returned unanswered.
Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi ni, nígbà tí wọn ń ṣe àìsàn, mo wọ aṣọ ọ̀fọ̀; mo fi àwẹ̀ pọ́n ara mi lójú. Mo gba àdúrà pẹ̀lú ìtẹríba ní oókan àyà mi;
14 I paced about as for my friend or brother; I was bowed down with grief, like one mourning for his mother.
èmí ń lọ kiri bí ẹni ń ṣọ̀fọ̀ bí i ẹni wí pé fún ọ̀rẹ́ tàbí ẹ̀gbọ́n mi ni. Èmí tẹríba nínú ìbànújẹ́ bí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ ìyà rẹ̀.
15 But when I stumbled, they assembled in glee; they gathered together against me. Assailants I did not know slandered me without ceasing.
Ṣùgbọ́n nínú ìkọ̀sẹ̀ mi wọ́n sì yọ̀, wọ́n sì kó ara wọn jọ; wọ́n kó ara wọn jọ sí mi; àní àwọn tí èmi kò mọ̀. Wọ́n fà mí ya wọ́n kò sì dákẹ́.
16 Like godless jesters at a feast, they gnashed their teeth at me.
Bí àwọn àgàbàgebè tí ń ṣe ẹlẹ́yà ní àpèjẹ wọ́n pa eyín wọn keke sí mi.
17 How long, O Lord, will You look on? Rescue my soul from their ravages, my precious life from these lions.
Yóò ti pẹ́ tó Olúwa, tí ìwọ yóò máa wò wọ́n lọ? Yọ mí kúrò nínú ìparun wọn, àní ẹ̀mí ì mi kúrò lọ́wọ́ kìnnìún.
18 Then I will give You thanks in the great assembly; I will praise You among many people.
Nígbà náà ni èmi yóò ṣọpẹ́ fún Ọ nínú àjọ ńlá; èmi yóò máa yìn Ọ́ ní àwùjọ ọ̀pọ̀ ènìyàn.
19 Let not my enemies gloat over me without cause, nor those who hate me without reason wink in malice.
Má ṣe jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi kí ó yọ̀ lórí ì mi; bẹ́ẹ̀ ni kí o má ṣe àwọn tí ó kórìíra mi ní àìnídìí máa ṣẹ́jú sí mi.
20 For they do not speak peace, but they devise deceitful schemes against those who live quietly in the land.
Nítorí pé wọn kò sọ ọ̀rọ̀ àlàáfíà, ṣùgbọ́n wọ́n lóyún ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn sí àwọn ènìyàn dídákẹ́ ilẹ̀ náà.
21 They gape at me and say, “Aha, aha! Our eyes have seen!”
Wọ́n ya ẹnu wọn gbòòrò sí mi; wọ́n wí pé, “Háà! Háà! Ojú wa sì ti rí i.”
22 O LORD, You have seen it; be not silent. O Lord, be not far from me.
Ìwọ́ ti rí i Olúwa; má ṣe dákẹ́! Olúwa má ṣe jìnnà sí mi!
23 Awake and rise to my defense, to my cause, my God and my Lord!
Dìde! ru ara rẹ̀ sókè fún ààbò mi, àti sí ọ̀ràn mi, Ọlọ́run mi àti Olúwa mi!
24 Vindicate me by Your righteousness, O LORD my God, and do not let them gloat over me.
Ṣe ìdájọ́ mi, Olúwa Ọlọ́run mi, gẹ́gẹ́ bí òdodo rẹ, kí o má sì ṣe jẹ́ kí wọn kí ó yọ̀ lórí mi!
25 Let them not say in their hearts, “Aha, just what we wanted!” Let them not say, “We have swallowed him up!”
Má ṣe jẹ́ kí wọn wí nínú ara wọn pé, “Háà! A ti rí ohun tí ọkàn wa ń fẹ́!” Má ṣe jẹ́ kí wọn kí ó wí pé, “A ti gbé e mì.”
26 May those who gloat in my distress be ashamed and confounded; may those who exalt themselves over me be clothed in shame and reproach.
Kí ojú kí ó tì wọ́n, kí wọn kí ó sì dààmú pọ̀, àní àwọn tí ń yọ̀ sí ìyọnu mi kí a fi ìtìjú àti àbùkù wọ̀ wọ́n ní aṣọ tí ń gbéraga sí mi.
27 May those who favor my vindication shout for joy and gladness; may they always say, “Exalted be the LORD who delights in His servant’s well-being.”
Jẹ́ kí àwọn tí ó fẹ́ ìdáláre mi fò fún ayọ̀ àti ìdùnnú; kí wọn máa sọ ọ́ títí lọ, “Pé gbígbéga ni Olúwa, sí àlàáfíà ìránṣẹ́ rẹ̀.”
28 Then my tongue will proclaim Your righteousness and Your praises all day long.
Nígbà náà ni ahọ́n mi yóò máa sọ̀rọ̀ òdodo rẹ, àti ìyìn rẹ ní gbogbo ọjọ́.