< Psalms 34 >
1 Of David, when he pretended to be insane before Abimelech, so that the king drove him away. I will bless the LORD at all times; His praise will always be on my lips.
Tí Dafidi. Nígbà tí ó díbọ́n bí ẹni tí ń ṣe wèrè níwájú Abimeleki, ẹni tí ó lé e lọ, ó sì jáde lọ. Èmi yóò máa fi ìbùkún fún Olúwa nígbà gbogbo; ìyìn rẹ̀ yóò máa wà ní ẹnu mi títí láé.
2 My soul boasts in the LORD; let the oppressed hear and rejoice.
Ọkàn mí yóò máa ṣògo nínú Olúwa; jẹ́ kí àwọn onírẹ̀lẹ̀ gbọ́ kí inú wọn kí ó sì máa dùn.
3 Magnify the LORD with me; let us exalt His name together.
Gbé Olúwa ga pẹ̀lú mi; kí ẹ sì jẹ́ kí a jọ gbé orúkọ rẹ̀ lékè.
4 I sought the LORD, and He answered me; He delivered me from all my fears.
Èmi wá Olúwa, ó sì dá mi lóhùn; Ó sì gbà mí kúrò nínú ìbẹ̀rù mi gbogbo.
5 Those who look to Him are radiant with joy; their faces shall never be ashamed.
Wọ́n wò ó, ìmọ́lẹ̀ sì mọ́ wọn; ojú kò sì tì wọ́n.
6 This poor man called out, and the LORD heard him; He saved him from all his troubles.
Ọkùnrin olùpọ́njú yí kígbe, Olúwa sì gbóhùn rẹ̀; ó sì gbà á là kúrò nínú gbogbo ìpọ́njú rẹ̀.
7 The angel of the LORD encamps around those who fear Him, and he delivers them.
Angẹli Olúwa yí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ká ó sì gbà wọ́n.
8 Taste and see that the LORD is good; blessed is the man who takes refuge in Him!
Tọ́ ọ wò kí o sì rí i wí pé Olúwa dára; ẹni ayọ̀ ni ọkùnrin náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé ààbò nínú rẹ̀.
9 Fear the LORD, you His saints, for those who fear Him lack nothing.
Ẹ bẹ̀rù Olúwa, ẹ̀yin ènìyàn rẹ̀ mímọ́, nítorí pé kò sí àìní fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.
10 Young lions go lacking and hungry, but those who seek the LORD lack no good thing.
Àwọn ọmọ kìnnìún a máa ṣe aláìní ebi a sì máa pa wọ́n; ṣùgbọ́n àwọn tí ó wá Olúwa kì yóò ṣe aláìní ohun tí ó dára.
11 Come, children, listen to me; I will teach you the fear of the LORD.
Wá, ẹ̀yin ọmọ mi, fi etí sí mi; èmi yóò kọ́ ọ yín ní ẹ̀rù Olúwa.
12 Who is the man who delights in life, who desires to see good days?
Ta ni nínú yín tí ń fẹ́ ìyè, tí ó sì ń fẹ́ ọjọ́ púpọ̀; kí ó lè gbádùn ọjọ́ rere?
13 Keep your tongue from evil and your lips from deceitful speech.
Pa ahọ́n rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi àti ètè rẹ̀ kúrò ní ẹ̀tàn sísọ.
14 Turn away from evil and do good; seek peace and pursue it.
Yà kúrò nínú ibi kí o sì ṣe rere; wá àlàáfíà, kí o sì lépa rẹ̀.
15 The eyes of the LORD are on the righteous, and His ears are inclined to their cry.
Ojú Olúwa ń bẹ lára àwọn olódodo; etí i rẹ̀ sì ṣí sí ẹkún wọn.
16 But the face of the LORD is against those who do evil, to wipe out all memory of them from the earth.
Ojú Olúwa korò sí àwọn tí ń ṣe búburú; láti ké ìrántí wọn kúrò lórí ilẹ̀.
17 The righteous cry out, and the LORD hears; He delivers them from all their troubles.
Nígbà tí olódodo bá ké fún ìrànlọ́wọ́, Olúwa a máa gbọ́, a sì yọ wọ́n jáde láti inú gbogbo wàhálà wọn.
18 The LORD is near to the brokenhearted; He saves the contrite in spirit.
Olúwa súnmọ́ etí ọ̀dọ̀ àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn; ó sì gba irú àwọn tí í ṣe oníròra ọkàn là.
19 Many are the afflictions of the righteous, but the LORD delivers him from them all.
Ìpọ́njú àwọn olódodo pọ̀, ṣùgbọ́n Olúwa gbà wọ́n kúrò nínú gbogbo rẹ̀.
20 He protects all his bones; not one of them will be broken.
Ó pa gbogbo egungun wọn mọ́; kò sí ọ̀kan tí ó dá nínú wọn.
21 Evil will slay the wicked, and the haters of the righteous will be condemned.
Ibi ni ó mú ikú ìkà wá, àti àwọn tí ó kórìíra olódodo ni yóò jẹ̀bi.
22 The LORD redeems His servants, and none who take refuge in Him will be condemned.
Olúwa ra ọkàn àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ padà; kò sí ọ̀kan nínú àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé tí yóò jẹ̀bi.