< Psalms 31 >

1 For the choirmaster. A Psalm of David. In You, O LORD, I have taken refuge; let me never be put to shame; save me by Your righteousness.
Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi. Nínú rẹ̀, Olúwa ni mo ti rí ààbò; má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí; gbà mí nínú òdodo rẹ.
2 Incline Your ear to me; come quickly to my rescue. Be my rock of refuge, the stronghold of my deliverance.
Tẹ́ etí rẹ sí mi, gbà mí kíákíá; jẹ́ àpáta ààbò mi, jẹ́ odi alágbára láti gbà mí.
3 For You are my rock and my fortress; lead me and guide me for the sake of Your name.
Ìwọ pàápàá ni àpáta àti ààbò mi, nítorí orúkọ rẹ, máa ṣe olùtọ́ mi, kí o sì ṣe amọ̀nà mi.
4 You free me from the net laid out for me, for You are my refuge.
Yọ mí jáde kúrò nínú àwọ̀n tí wọ́n dẹ pamọ́ fún mi, nítorí ìwọ ni ìsádi mi.
5 Into Your hands I commit my spirit; You have redeemed me, O LORD, God of truth.
Ní ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé; ìwọ ni o ti rà mí padà, Olúwa, Ọlọ́run òtítọ́.
6 I hate those who cling to worthless idols, but in the LORD I trust.
Èmi ti kórìíra àwọn ẹni tí ń fiyèsí òrìṣà tí kò níye lórí; ṣùgbọ́n èmi gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.
7 I will be glad and rejoice in Your loving devotion, for You have seen my affliction; You have known the anguish of my soul.
Èmi yóò yọ̀, inú mi yóò dùn nínú ìfẹ́ ńlá rẹ, nítorí ìwọ ti rí ìbìnújẹ́ mi ìwọ ti mọ̀ ọkàn mi nínú ìpọ́njú.
8 You have not delivered me to the enemy; You have set my feet in the open.
Pẹ̀lú, ìwọ kò sì fà mi lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́ ìwọ ti fi ẹsẹ̀ mi lé ibi ààyè ńlá.
9 Be merciful to me, O LORD, for I am in distress; my eyes fail from sorrow, my soul and body as well.
Ṣàánú fún mi, ìwọ Olúwa, nítorí mo wà nínú ìpọ́njú; ojú mi fi ìbìnújẹ́ sùn, ọkàn àti ara mi pẹ̀lú.
10 For my life is consumed with grief and my years with groaning; my iniquity has drained my strength, and my bones are wasting away.
Èmi fi ìbànújẹ́ lo ọjọ́ mi àti àwọn ọdún mi pẹ̀lú ìmí ẹ̀dùn; agbára mi ti kùnà nítorí òsì mi, egungun mi sì ti rún dànù.
11 Among all my enemies I am a disgrace, and among my neighbors even more. I am dreaded by my friends— they flee when they see me on the street.
Èmi di ẹni ẹ̀gàn láàrín àwọn ọ̀tá mi gbogbo, pẹ̀lúpẹ̀lú láàrín àwọn aládùúgbò mi, mo sì di ẹ̀rù fún àwọn ojúlùmọ̀ mi; àwọn tí ó rí mi ní òde ń yẹra fún mi.
12 I am forgotten like a dead man, out of mind. I am like a broken vessel.
Èmi ti di ẹni ìgbàgbé kúrò ní ọkàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ti kú; èmi sì dàbí ohun èlò tí ó ti fọ́.
13 For I hear the slander of many; there is terror on every side. They conspire against me and plot to take my life.
Nítorí mo gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpayà tí ó yí mi ká; tí wọn gbìmọ̀ pọ̀ sí mi, wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí mi láti gba ẹ̀mí mi.
14 But I trust in You, O LORD; I say, “You are my God.”
Ṣùgbọ́n èmí gbẹ́kẹ̀lé ọ, ìwọ Olúwa; mo sọ wí pé, “Ìwọ ní Ọlọ́run mi.”
15 My times are in Your hands; deliver me from my enemies and from those who pursue me.
Ìgbà mi ń bẹ ní ọwọ́ rẹ; gbà mí kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá mi àti àwọn onínúnibíni.
16 Make Your face shine on Your servant; save me by Your loving devotion.
Jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí ìránṣẹ́ rẹ lára; gbà mí nínú ìfẹ́ rẹ tí ó dúró ṣinṣin.
17 O LORD, let me not be ashamed, for I have called on You. Let the wicked be put to shame; let them lie silent in Sheol. (Sheol h7585)
Má ṣe jẹ́ kí ojú ki ó tì mí, Olúwa; nítorí pé mo ké pè ọ́; jẹ́ kí ojú kí ó ti ènìyàn búburú; jẹ́ kí wọ́n lọ pẹ̀lú ìdààmú sí isà òkú. (Sheol h7585)
18 May lying lips be silenced— lips that speak with arrogance against the righteous, full of pride and contempt.
Jẹ́ kí àwọn ètè irọ́ kí ó dákẹ́ jẹ́ẹ́, pẹ̀lú ìgbéraga àti ìkẹ́gàn, wọ́n sọ̀rọ̀ àfojúdi sí olódodo.
19 How great is Your goodness which You have laid up for those who fear You, which You have bestowed before the sons of men on those who take refuge in You!
Báwo ni títóbi oore rẹ̀ ti pọ̀ tó, èyí tí ìwọ ti ní ní ìpamọ́ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ, èyí tí ìwọ rọ̀jò rẹ̀ níwájú àwọn ènìyàn tí wọ́n fi ọ́ ṣe ibi ìsádi wọn.
20 You hide them in the secret place of Your presence from the schemes of men. You conceal them in Your shelter from accusing tongues.
Ní abẹ́ ìbòòji iwájú rẹ ni ìwọ pa wọ́n mọ́ sí kúrò nínú ìdìmọ̀lù àwọn ènìyàn; ní ibùgbé rẹ, o mú wọn kúrò nínú ewu kúrò nínú ìjà ahọ́n.
21 Blessed be the LORD, for He has shown me His loving devotion in a city under siege.
Olùbùkún ni Olúwa, nítorí pé ó ti fi àgbà ìyanu ìfẹ́ tí ó ní sí mi hàn, nígbà tí mo wà ní ìlú tí wọ́n rọ̀gbà yíká.
22 In my alarm I said, “I am cut off from Your sight!” But You heard my plea for mercy when I called to You for help.
Èmí ti sọ nínú ìdágìrì mi, “A gé mi kúrò ní ojú rẹ!” Síbẹ̀ ìwọ ti gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi fún àánú nígbà tí mo ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́.
23 Love the LORD, all His saints. The LORD preserves the faithful, but fully repays the arrogant.
Ẹ fẹ́ Olúwa, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn rẹ̀ mímọ́! Olúwa pa olódodo mọ́, ó sì san án padà fún agbéraga ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.
24 Be strong and courageous, all you who hope in the LORD.
Jẹ́ alágbára, yóò sì mú yín ní àyà le gbogbo ẹ̀yin tí ó dúró de Olúwa.

< Psalms 31 >