< Psalms 18 >

1 For the choirmaster. Of David the servant of the LORD, who sang this song to the LORD on the day the LORD had delivered him from the hand of all his enemies and from the hand of Saul. He said: I love You, O LORD, my strength.
Fún adarí orin. Ti Dafidi ìránṣẹ́ Olúwa tí ó kọ sí Olúwa, ọ̀rọ̀ orin tí ó kọ sí Olúwa fún ìdáǹdè kúrò lọ́wọ́ Saulu ọ̀tá rẹ̀. Ó wí pé. Mo fẹ́ ọ, Olúwa, agbára mi.
2 The LORD is my rock, my fortress, and my deliverer. My God is my rock, in whom I take refuge, my shield, and the horn of my salvation, my stronghold.
Olúwa ni àpáta àti odi mi, àti olùgbàlà mi; Ọlọ́run mi ni àpáta mi, ẹni tí mo fi ṣe ibi ìsádi mi. Òun ni àpáta ààbò àti ìwo ìgbàlà mi àti ibi ìsádi mi.
3 I will call upon the LORD, who is worthy to be praised; so shall I be saved from my enemies.
Mo ké pe Olúwa, ẹni tí ìyìn yẹ fún, a ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá à mi.
4 The cords of death encompassed me; the torrents of chaos overwhelmed me.
Ìrora ikú yí mi kà, àti ìṣàn omi àwọn ènìyàn búburú dẹ́rùbà mí.
5 The cords of Sheol entangled me; the snares of death confronted me. (Sheol h7585)
Okùn isà òkú yí mi ká, ìkẹ́kùn ikú dojúkọ mí. (Sheol h7585)
6 In my distress I called upon the LORD; I cried to my God for help. From His temple He heard my voice, and my cry for His help reached His ears.
Nínú ìpọ́njú mo ké pe Olúwa; mo sọkún sí Olúwa mi fún ìrànlọ́wọ́. Láti inú tẹmpili rẹ̀, ó gbọ́ igbe mi; ẹkún mi wá sí iwájú rẹ̀, sí inú etí rẹ̀.
7 Then the earth shook and quaked, and the foundations of the mountains trembled; they were shaken because He burned with anger.
Ayé wárìrì, ó sì mì tìtì, ìpìlẹ̀ àwọn òkè gíga sì ṣídìí; wọ́n wárìrì nítorí tí ó ń bínú.
8 Smoke rose from His nostrils, and consuming fire came from His mouth; glowing coals blazed forth.
Èéfín ti ihò imú rẹ̀ jáde wá; iná ajónirun ti ẹnu rẹ̀ jáde wá, ẹ̀yin iná bú jáde láti inú rẹ̀.
9 He parted the heavens and came down with dark clouds beneath His feet.
Ó pín àwọn ọ̀run, Ó sì jáde wá; àwọsánmọ̀ dúdú sì wà ní abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.
10 He mounted a cherub and flew; He soared on the wings of the wind.
Ó gun orí kérúbù, ó sì fò; ó ń rábàbà lórí ìyẹ́ apá afẹ́fẹ́.
11 He made darkness His hiding place, and storm clouds a canopy around Him.
Ó fi òkùnkùn ṣe ibojì rẹ̀, ó fi ṣe ìbòrí yí ara rẹ̀ ká kurukuru òjò dúdú ní ojú ọ̀run.
12 From the brightness of His presence His clouds advanced— hailstones and coals of fire.
Nípa ìmọ́lẹ̀ iwájú rẹ̀, àwọsánmọ̀ ṣíṣú dudu rẹ kọjá lọ pẹ̀lú yìnyín àti ẹ̀yín iná
13 The LORD thundered from heaven; the voice of the Most High resounded— hailstones and coals of fire.
Olúwa sán àrá láti ọ̀run wá; Ọ̀gá-ògo sì fọ ohun rẹ̀; yìnyín àti ẹ̀yin iná.
14 He shot His arrows and scattered the foes; He hurled lightning and routed them.
Ó ta àwọn ọfà rẹ̀, ó sì tú àwọn ọ̀tá náà ká, ọfà mọ̀nàmọ́ná ńlá sì dà wọ́n rú.
15 The channels of the sea appeared, and the foundations of the world were exposed, at Your rebuke, O LORD, at the blast of the breath of Your nostrils.
A sì fi ìsàlẹ̀ àwọn òkun hàn, a sì rí àwọn ìpìlẹ̀ ayé nípa ìbáwí rẹ, Olúwa, nípa fífún èémí ihò imú rẹ.
16 He reached down from on high and took hold of me; He drew me out of deep waters.
Ó sọ̀kalẹ̀ láti ibi gíga, ó sì dì mímú; Ó fà mí jáde láti inú omi jíjìn.
17 He rescued me from my powerful enemy, from foes too mighty for me.
Ó gbà mí kúrò lọ́wọ́ ọ̀tá mi alágbára, láti ọwọ́ àwọn ọ̀tá, ti ó lágbára jù fún mi.
18 They confronted me in my day of calamity, but the LORD was my support.
Wọ́n dojúkọ mí ní ọjọ́ ìpọ́njú mi; ṣùgbọ́n Olúwa ni alátìlẹ́yìn mi.
19 He brought me out into the open; He rescued me because He delighted in me.
Ó mú mi jáde wá sínú ibi ńlá; Ó gbà mí nítorí tí ó ní inú dídùn sí mi.
20 The LORD has rewarded me according to my righteousness; He has repaid me according to the cleanness of my hands.
Olúwa ti hùwà sí mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi; gẹ́gẹ́ bí mímọ́ ọwọ́ mi, ó ti fi èrè fún mi.
21 For I have kept the ways of the LORD and have not wickedly departed from my God.
Nítorí mo ti pa ọ̀nà Olúwa mọ́; èmi kò ṣe búburú nípa yíyí padà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run mi.
22 For all His ordinances are before me; I have not disregarded His statutes.
Gbogbo òfin rẹ̀ ni ó wà níwájú mi; èmi kò sì yípadà kúrò nínú ìlànà rẹ̀.
23 And I have been blameless before Him and kept myself from iniquity.
Mo ti jẹ́ aláìlẹ́bi níwájú rẹ̀; mo sì pa ara mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀.
24 So the LORD has repaid me according to my righteousness, according to the cleanness of my hands in His sight.
Olúwa san ẹ̀san fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi; gẹ́gẹ́ bí mímọ́ ọwọ́ mi níwájú rẹ̀.
25 To the faithful You show Yourself faithful, to the blameless You show Yourself blameless;
Fún olóòtítọ́ ni ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ní olóòtítọ́, sí aláìlẹ́bi, ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ní aláìlẹ́bi,
26 to the pure You show Yourself pure, but to the crooked You show Yourself shrewd.
sí ọlọ́kàn mímọ́, ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ní ọlọ́kàn mímọ́, ṣùgbọ́n sí ọlọ́kàn-wíwọ́, ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ní òǹrorò.
27 For You save an afflicted people, but You humble those with haughty eyes.
O pa onírẹ̀lẹ̀ mọ́, ṣùgbọ́n ó rẹ àwọn ti ń gbéraga sílẹ̀.
28 For You, O LORD, light my lamp; my God lights up my darkness.
Ìwọ, Olúwa, jẹ́ kí fìtílà mi kí ó máa tàn; Ọlọ́run mi, yí òkùnkùn mi padà sí ìmọ́lẹ̀.
29 For in You I can charge an army, and with my God I can scale a wall.
Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ rẹ̀, èmi sáré tọ ogun lọ; pẹ̀lú Ọlọ́run mi mo lè fo odi kan.
30 As for God, His way is perfect; the word of the LORD is flawless. He is a shield to all who take refuge in Him.
Bí ó ṣe ti Ọlọ́run mi, ọ̀nà rẹ̀ pé, a ti rídìí ọ̀rọ̀ Olúwa òun ni àpáta ààbò fún gbogbo àwọn tí ó fi ṣe ààbò.
31 For who is God besides the LORD? And who is the Rock except our God?
Nítorí ta ni ṣe Ọlọ́run bí kò ṣe Olúwa? Ta ní àpáta bí kò ṣe Olúwa wa?
32 It is God who arms me with strength and makes my way clear.
Ọlọ́run ni ẹni tí ó fi agbára dì mí ní àmùrè ó sì mú ọ̀nà mi pé.
33 He makes my feet like those of a deer and stations me upon the heights.
Ó ṣe ẹsẹ̀ mi gẹ́gẹ́ bi ẹsẹ̀ abo àgbọ̀nrín; ó jẹ́ ki n lè dúró lórí ibi gíga.
34 He trains my hands for battle; my arms can bend a bow of bronze.
Ó kọ́ ọwọ́ mi ni ogun jíjà; apá mi lè tẹ ọrùn idẹ.
35 You have given me Your shield of salvation; Your right hand upholds me, and Your gentleness exalts me.
Ìwọ fi asà ìṣẹ́gun rẹ̀ fún mi, ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ gbé mí dúró; àti ìwà pẹ̀lẹ́ rẹ̀ sọ mí di ńlá.
36 You broaden the path beneath me so that my ankles do not give way.
Ìwọ sọ ìrìn ẹsẹ̀ mi di ńlá ní ìsàlẹ̀ mi, kí kókó-ẹsẹ̀ mi má ṣe yẹ̀.
37 I pursued my enemies and overtook them; I did not turn back until they were consumed.
Èmi lépa àwọn ọ̀tá mi, èmi sì bá wọn èmi kò sì padà lẹ́yìn wọn títí a fi run wọ́n.
38 I crushed them so they could not rise; they have fallen under my feet.
Èmi sá wọn ní ọgbẹ́ tí wọn ko fi le è dìde; wọ́n ṣubú ní abẹ́ ẹsẹ̀ mi.
39 You have armed me with strength for battle; You have subdued my foes beneath me.
Nítorí ìwọ fi agbára dì mí ní àmùrè fún ogun náà; ìwọ ti mú àwọn tí ó dìde si mí tẹríba ní abẹ́ ẹsẹ̀ mi.
40 You have made my enemies retreat before me; I put an end to those who hated me.
Ìwọ yí ẹ̀yìn àwọn ọ̀tá mí padà sí mi èmi sì pa àwọn tí ó kórìíra mi run.
41 They cried for help, but there was no one to save them— to the LORD, but He did not answer.
Wọ́n kígbe fún ìrànlọ́wọ́, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó gbà wọ́n, àní sí Olúwa, ṣùgbọ́n kò dá wọn lóhùn.
42 I ground them as dust in the face of the wind; I trampled them like mud in the streets.
Mo lù wọ́n gẹ́gẹ́ bí eruku níwájú afẹ́fẹ́; mo dà wọ́n síta gẹ́gẹ́ bí ẹrọ̀fọ̀.
43 You have delivered me from the strife of the people; You have made me the head of nations; a people I had not known shall serve me.
Ìwọ ti gbà mí lọ́wọ́ ìkọlù àwọn ènìyàn; Ìwọ ti fi mí ṣe olórí àwọn orílẹ̀-èdè. Àwọn ènìyàn ti èmi kò mọ, yóò sì máa sìn mí,
44 When they hear me, they obey me; foreigners cower before me.
ni wéré ti wọ́n gbọ́ ohùn mi, wọ́n pa àṣẹ mi mọ́; àwọn ọmọ àjèjì yóò tẹríba fún mi.
45 Foreigners lose heart and come trembling from their strongholds.
Àyà yóò pá àlejò; wọn yóò sì fi ìbẹ̀rù jáde láti ibi kọ́lọ́fín wọn.
46 The LORD lives, and blessed be my Rock! And may the God of my salvation be exalted—
Olúwa wà láààyè! Olùbùkún ni àpáta mi! Gbígbéga ní Ọlọ́run Olùgbàlà mi.
47 the God who avenges me and subdues nations beneath me,
Òun ni Ọlọ́run tí ó ń gbẹ̀san mi, tí ó sì ń ṣẹ́gun àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wà ní abẹ́ mi,
48 who delivers me from my enemies. You exalt me above my foes; You rescue me from violent men.
tí ó pa mí mọ́ kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mí. Ìwọ gbé mi ga ju àwọn ọ̀tá tí ó dìde sí mi lọ; lọ́wọ́ àwọn ènìyàn alágbára ni ìwọ ti gbà mí.
49 Therefore I will praise You, O LORD, among the nations; I will sing praises to Your name.
Títí láéláé, èmi yóò máa yìn ọ́ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ìwọ Olúwa; èmi yóò sì máa kọ orin ìyìn sí orúkọ rẹ.
50 Great salvation He brings to His king. He shows loving devotion to His anointed, to David and his descendants forever.
Ó fún ọba rẹ̀ ni ìṣẹ́gun ńlá; ó fi ìkáàánú àìṣẹ̀tàn fún ẹni àmì òróró rẹ̀, fún Dafidi àti ìran rẹ̀ títí láé.

< Psalms 18 >