< Proverbs 5 >
1 My son, pay attention to my wisdom; incline your ear to my insight,
Ọmọ mi, fiyèsí ọgbọ́n mi, kí o sì dẹtí rẹ sí òye mi,
2 that you may maintain discretion and your lips may preserve knowledge.
kí ìwọ sì lè ní ìṣọ́ra kí ètè rẹ sì le pa ìmọ̀ mọ́.
3 Though the lips of the forbidden woman drip honey and her speech is smoother than oil,
Nítorí ètè àwọn àjèjì obìnrin a máa sun bi oyin, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì kúnná ju òróró lọ.
4 in the end she is bitter as wormwood, sharp as a double-edged sword.
Ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín, ó korò ju òróǹró lọ, ó mú bí idà olójú méjì.
5 Her feet go down to death; her steps lead straight to Sheol. (Sheol )
Ẹsẹ̀ rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí ọ̀nà ikú ìgbésẹ̀ rẹ̀ lọ tààrà sí ibojì òkú. (Sheol )
6 She does not consider the path of life; she does not know that her ways are unstable.
Kí ìwọ má ba à já ipa ọ̀nà ìyè; ọ̀nà rẹ̀ rí pálapàla, ṣùgbọ́n kò tilẹ̀ mọ́.
7 So now, my sons, listen to me, and do not turn aside from the words of my mouth.
Nítorí náà, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ dẹtí sí mi, kí ẹ̀yin kí ó má ṣe yàgò kúrò nínú ọ̀rọ̀ tí mo sọ.
8 Keep your path far from her; do not go near the door of her house,
Rìn ní ọ̀nà tí ó jìnnà sí ti rẹ̀, má ṣe súnmọ́ ẹnu-ọ̀nà ilé rẹ̀,
9 lest you concede your vigor to others, and your years to one who is cruel;
àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ yóò gbé gbogbo ọlá rẹ lé ẹlòmíràn lọ́wọ́ àti ọjọ́ ayé rẹ fún ìkà ènìyàn.
10 lest strangers feast on your wealth, and your labors enrich the house of a foreigner.
Kí a má ba à fi ọrọ̀ rẹ fún àjèjì ènìyàn, kí làálàá rẹ sì sọ ilé ẹlòmíràn di ọlọ́rọ̀.
11 At the end of your life you will groan when your flesh and your body are spent,
Ní ìgbẹ̀yìn ayé rẹ ìwọ yóò kérora, nígbà tí agbára rẹ àti ara rẹ bá ti joro tán.
12 and you will say, “How I hated discipline, and my heart despised reproof!
Ìwọ yóò wí pé, “Mo ti kórìíra ẹ̀kọ́ tó! Ọkàn mi ṣe wá kórìíra ìbáwí!
13 I did not listen to the voice of my teachers or incline my ear to my mentors.
N kò gbọ́rọ̀ sí àwọn olùkọ́ mi lẹ́nu, tàbí kí n fetí sí àwọn tí ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́.
14 I am on the brink of utter ruin in the midst of the whole assembly.”
Mo ti bẹ̀rẹ̀ ìparun pátápátá ní àárín gbogbo àwùjọ ènìyàn.”
15 Drink water from your own cistern, and running water from your own well.
Mu omi láti inú kànga tìrẹ, omi tí ń sàn láti inú kànga rẹ.
16 Why should your springs flow in the streets, your streams of water in the public squares?
Ó ha yẹ kí omi ìsun rẹ kún àkúnya sí ojú ọ̀nà àti odò tí ń sàn lọ sí àárín ọjà?
17 Let them be yours alone, never to be shared with strangers.
Jẹ́ kí wọn jẹ́ tìrẹ nìkan, má ṣe ṣe àjọpín wọn pẹ̀lú àjèjì láéláé.
18 May your fountain be blessed, and may you rejoice in the wife of your youth:
Jẹ́ kí orísun rẹ kí ó ní ìbùkún; kí ìwọ ó sì máa yọ nínú aya ìgbà èwe rẹ.
19 A loving doe, a graceful fawn— may her breasts satisfy you always; may you be captivated by her love forever.
Abo àgbọ̀nrín tó dára, ìgalà tí ó wu ni jọjọ, jẹ́ kí ọmú rẹ̀ kí ó máa fi ayọ̀ fún ọ nígbà gbogbo, kí o sì máa yọ̀ nínú ìfẹ́ rẹ̀ nígbàkígbà.
20 Why be captivated, my son, by an adulteress, or embrace the bosom of a stranger?
Ọmọ mi, èéṣe tí ìwọ ó fi máa yọ̀ nínú ìfẹ́ obìnrin panṣágà, tí ìwọ ó sì fi dì mọ́ ìyàwó ẹlòmíràn?
21 For a man’s ways are before the eyes of the LORD, and the LORD examines all his paths.
Nítorí ọ̀nà ènìyàn kò fi ara sin rárá fún Olúwa Ó sì ń gbé gbogbo ọ̀nà rẹ̀ yẹ̀ wò.
22 The iniquities of a wicked man entrap him; the cords of his sin entangle him.
Ìwà búburú ènìyàn búburú ni yóò mú kó bọ́ sínú okùn; okùn ẹ̀ṣẹ̀ ara rẹ̀ yóò sì dìímú.
23 He dies for lack of discipline, led astray by his own great folly.
Yóò kú ní àìgba ẹ̀kọ́ ìwà òmùgọ̀ ara rẹ̀ yóò sì mú kí ó máa ṣìnà kiri.