< Proverbs 17 >

1 Better a dry morsel in quietness than a house full of feasting with strife.
Òkèlè gbígbẹ tòun tàlàáfíà àti ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ sàn ju ilé tí ó kún fọ́fọ́ fún ẹran àti ìjà.
2 A wise servant will rule over a disgraceful son and share his inheritance as one of the brothers.
Ọlọ́gbọ́n ìránṣẹ́ yóò ṣàkóso adójútini ọmọ, yóò sì pín ogún gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ.
3 A crucible for silver and a furnace for gold, but the LORD is the tester of hearts.
Iná ni a fi fọ́ fàdákà àti wúrà, ṣùgbọ́n Olúwa ló ń dán ọkàn wò.
4 A wicked man listens to evil lips; a liar gives ear to a destructive tongue.
Ènìyàn búburú ń tẹ́tí sí ètè tí ń sọ ibi; òpùrọ́ a máa fetí sí ahọ́n búburú.
5 He who mocks the poor insults their Maker; whoever gloats over calamity will not go unpunished.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá sín olùpọ́njú jẹ, ó gan Ẹlẹ́dàá rẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ń yọ̀ sí ìyọnu kò ní lọ láìjìyà.
6 Grandchildren are the crown of the aged, and the glory of a son is his father.
Ọmọ ọmọ ni adé orí arúgbó, ògo àwọn ọmọ sì ni òbí jẹ.
7 Eloquent words are unfit for a fool; how much worse are lying lips to a ruler!
Ọ̀rọ̀ dídùn kò yẹ aṣiwèrè, bẹ́ẹ̀ ni ètè èké kò yẹ ọmọ-aládé!
8 A bribe is a charm to its giver; wherever he turns, he succeeds.
Òkúta iyebíye jẹ́ ẹ̀bùn ní ojú ẹni tí ó ni í, ibikíbi tí ó yí sí, á ṣe rere.
9 Whoever conceals an offense promotes love, but he who brings it up separates friends.
Ẹni tí ó fojú fo ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ ẹ́ mú kí ìfẹ́ gbòòrò sí i. Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ń tẹnumọ́ ọ̀rọ̀ yóò pín ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ méjì ní yà.
10 A rebuke cuts into a man of discernment deeper than a hundred lashes cut into a fool.
Ọ̀rọ̀ ìbáwí dun olóye ènìyàn ju ọgọ́rùn-ún pàṣán lọ lẹ́yìn òmùgọ̀.
11 An evil man seeks only rebellion; a cruel messenger will be sent against him.
Orí kunkun ni ènìyàn ìkà máa ń ṣe, ìjòyè aláìláàánú ni a ó rán sí i.
12 It is better to meet a bear robbed of her cubs than a fool in his folly.
Ó sàn kí ènìyàn pàdé beari tí a ti kó lọ́mọ jù aláìgbọ́n nínú ìwà òmùgọ̀ rẹ̀.
13 If anyone returns evil for good, evil will never leave his house.
Bí ènìyàn kan bá fi ibi san ìre, ibi kì yóò kúrò nílé rẹ̀ láéláé.
14 To start a quarrel is to release a flood; so abandon the dispute before it breaks out.
Bíbẹ̀rẹ̀ ìjà dàbí ẹni tí ó dá ojú fún adágún omi; nítorí náà mẹ́nu kúrò nínú ọ̀rọ̀ kí ó tó di ìjà.
15 Acquitting the guilty and condemning the righteous— both are detestable to the LORD.
Gbígbé ẹ̀bi fún aláre àti dídá ẹni jàre lẹ́bi, Olúwa kórìíra méjèèjì.
16 Why should the fool have money in his hand with no intention of buying wisdom?
Kí ni ìwúlò owó lọ́wọ́ aṣiwèrè, níwọ̀n bí kò ti ní èròǹgbà láti rí ọgbọ́n?
17 A friend loves at all times, and a brother is born for adversity.
Ọ̀rẹ́ a máa fẹ́ni nígbà gbogbo, arákùnrin sì wà fún ìgbà ìpọ́njú.
18 A man lacking judgment strikes hands in pledge and puts up security for his neighbor.
Ènìyàn aláìgbọ́n ṣe ìbúra, ó sì ṣe onídùúró fún aládùúgbò rẹ̀.
19 He who loves transgression loves strife; he who builds his gate high invites destruction.
Ẹni tí ó fẹ́ràn ìjà fẹ́ràn ẹ̀ṣẹ̀; ẹni tí ó kọ́ ibodè gígàn ń wá ìparun.
20 The one with a perverse heart finds no good, and he whose tongue is deceitful falls into trouble.
Ènìyàn aláyídáyidà ọkàn kì í gbèrú, ẹni tí ó ní ahọ́n ẹ̀tàn bọ́ sínú ìyọnu.
21 A man fathers a fool to his own grief; the father of a fool has no joy.
Láti bí aláìgbọ́n lọ́mọ a máa fa ìbànújẹ́ ọkàn, kò sí ayọ̀ fún baba ọmọ tí kò gbọ́n.
22 A joyful heart is good medicine, but a broken spirit dries up the bones.
Ọkàn tí ó túká jẹ́ oògùn gidi, ṣùgbọ́n ọkàn tí ó bàjẹ́ a máa mú kí egungun gbẹ.
23 A wicked man takes a covert bribe to subvert the course of justice.
Ènìyàn búburú a gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀ láti yí ìdájọ́ po.
24 Wisdom is the focus of the discerning, but the eyes of a fool wander to the ends of the earth.
Olóye ènìyàn gbójú wo ọgbọ́n níwájú, ṣùgbọ́n ojú aláìgbọ́n ń wò káàkiri ilẹ̀ ayé.
25 A foolish son brings grief to his father and bitterness to her who bore him.
Aṣiwèrè ọmọ mú ìbànújẹ́ bá baba rẹ̀ àti ìkorò fún ẹni tí ó bí i lọ́mọ.
26 It is surely not good to punish the innocent or to flog a noble for his honesty.
Kò dára láti fìyà jẹ ènìyàn tí kò ṣẹ̀, tàbí láti na ìjòyè lórí òtítọ́ inú wọn.
27 A man of knowledge restrains his words, and a man of understanding maintains a calm spirit.
Ènìyàn tó ní ìmọ̀ máa ń ṣọ́ra fún àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ, ènìyàn olóye sì máa ń ní sùúrù.
28 Even a fool is considered wise if he keeps silent, and discerning when he holds his tongue.
Kódà aláìgbọ́n máa ń dàbí ọlọ́gbọ́n bí ó bá dákẹ́, àti bí olóye bí ó bá fètèmétè.

< Proverbs 17 >