< Numbers 15 >
1 Then the LORD said to Moses,
Olúwa sọ fún Mose pé,
2 “Speak to the Israelites and tell them: After you enter the land that I am giving you as a home
“Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí èmi ó fún yin gẹ́gẹ́ bí ibùgbé
3 and you present an offering made by fire to the LORD from the herd or flock to produce a pleasing aroma to the LORD—either a burnt offering or a sacrifice, for a special vow or freewill offering or appointed feast—
tí ẹ̀yin ó bá sì ṣe ẹbọ iná sí Olúwa ẹbọ sísun, tàbí ẹbọ, láti san ẹ̀jẹ́ pàtàkì tàbí ọrẹ àtinúwá, tàbí nínú àjọ yín, láti ṣe òórùn dídùn sí Olúwa nínú agbo ẹran tàbí ọ̀wọ́ ẹran,
4 then the one presenting his offering to the LORD shall also present a grain offering of a tenth of an ephah of fine flour mixed with a quarter hin of olive oil.
nígbà náà ni kí ẹni tí ó bá mú ọrẹ rẹ̀ wá, yóò tún mú ẹbọ ohun jíjẹ ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná pẹ̀lú ìdámẹ́rin òsùwọ̀n òróró wá síwájú Olúwa.
5 With the burnt offering or sacrifice of each lamb, you are to prepare a quarter hin of wine as a drink offering.
Pẹ̀lú ọ̀dọ́-àgùntàn kọ̀ọ̀kan yálà fún ọrẹ tàbí ẹbọ sísun ni, kí ẹ pèsè ìdámẹ́rin òsùwọ̀n wáìnì gẹ́gẹ́ bí ohun mímu.
6 With a ram you are to prepare a grain offering of two-tenths of an ephah of fine flour mixed with a third of a hin of olive oil,
“‘Fún àgbò kan ni kí ẹ pèsè ọrẹ ohun jíjẹ ìdá méjì nínú mẹ́wàá òsùwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi ìdákan nínú mẹ́ta òsùwọ̀n òróró pò.
7 and a third of a hin of wine as a drink offering, a pleasing aroma to the LORD.
Àti ìdákan nínú mẹ́ta òsùwọ̀n wáìnì fún ọrẹ ohun mímu gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn sí Olúwa.
8 When you prepare a young bull as a burnt offering or sacrifice to fulfill a vow or as a peace offering to the LORD,
“‘Nígbà tí ẹ bá sì pèsè ọ̀dọ́ akọ màlúù fún ọrẹ tàbí ẹbọ sísun, láti fi san ẹ̀jẹ́ tàbí fún ọrẹ àlàáfíà sí Olúwa,
9 present with the bull a grain offering of three-tenths of an ephah of fine flour mixed with half a hin of olive oil.
ẹni náà yóò mú ọ̀dọ́ akọ màlúù náà wá pẹ̀lú ọrẹ ohun jíjẹ, ìdámẹ́ta nínú mẹ́wàá òsùwọ̀n ìyẹ̀fun ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi ìdajì òsùwọ̀n òróró pò.
10 Also present half a hin of wine as a drink offering. It is an offering made by fire, a pleasing aroma to the LORD.
Kí ó tún mú ìdajì òsùwọ̀n wáìnì wá fún ọrẹ ohun mímu. Yóò jẹ́ ọrẹ àfinásun, àní òórùn dídùn sí Olúwa.
11 This is to be done for each bull, ram, lamb, or goat.
Báyìí ni kí ẹ ṣe pèsè ọ̀dọ́ akọ màlúù tàbí àgbò, ọ̀dọ́-àgùntàn tàbí ọmọ ewúrẹ́.
12 This is how you must prepare each one, no matter how many.
Ẹ ṣe bẹ́ẹ̀ fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn, iyekíye tí ẹ̀yin ìbá à pèsè.
13 Everyone who is native-born shall prepare these things in this way when he presents an offering made by fire as a pleasing aroma to the LORD.
“‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ ọmọ bíbí ilẹ̀ yín ni kí ó máa ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí nígbà tí ó bá mú ọrẹ àfinásun gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn wá fún Olúwa.
14 And for the generations to come, if a foreigner residing with you or someone else among you wants to prepare an offering made by fire as a pleasing aroma to the LORD, he is to do exactly as you do.
Bí àlejò kan bá ń gbé láàrín yín ní gbogbo ìran yín, bí irú ẹni bẹ́ẹ̀ bá fẹ́ mú ọrẹ àfinásun bí òórùn dídùn wá fún Olúwa, gbogbo bí ẹ bá ṣe ń ṣe náà ni kí ó ṣe.
15 The assembly is to have the same statute both for you and for the foreign resident; it is a permanent statute for the generations to come. You and the foreigner shall be the same before the LORD.
Gbogbo ìjọ ènìyàn gbọdọ̀ ní òfin kan náà fún ọmọ bíbí ilẹ̀ yín àti fún àwọn àlejò tó ń gbé láàrín yín, èyí jẹ́ ìlànà títí láé fún àwọn ìran tó ń bọ̀. Ẹ̀yin àti àlejò tó ń gbé láàrín yín sì jẹ́ bákan náà níwájú Olúwa.
16 The same law and the same ordinance will apply both to you and to the foreigner residing with you.”
Òfin kan àti ìlànà kan ni yóò wà fún yín àti fún àwọn àlejò tí ń gbé láàrín yín.’”
17 Then the LORD said to Moses,
Olúwa sọ fún Mose pé,
18 “Speak to the Israelites and tell them: When you enter the land to which I am bringing you
“Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí mo ń mú yín lọ.
19 and you eat the food of the land, you shall lift up an offering to the LORD.
Tí ẹ sì jẹ oúnjẹ ilẹ̀ náà, ẹ mú nínú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ìgbésókè wá fún Olúwa.
20 From the first of your dough, you are to lift up a cake as a contribution; offer it just like an offering from the threshing floor.
Ẹ mú àkàrà wá nínú àkọ́so oúnjẹ yín wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ìgbésókè sí Olúwa, ọrẹ láti inú ilẹ̀ ìpakà yín.
21 Throughout your generations, you are to give the LORD an offering from the first of your dough.
Nínú àkọ́so oúnjẹ yín ni kí ẹ ti máa mú ọrẹ ìgbésókè yìí fún Olúwa.
22 Now if you stray unintentionally and do not obey all these commandments that the LORD has spoken to Moses—
“‘Bí ẹ bá kùnà láìròtẹ́lẹ̀ láti pa àwọn òfin tí Olúwa fún Mose mọ́,
23 all that the LORD has commanded you through Moses from the day the LORD gave them and continuing through the generations to come—
èyí ni gbogbo òfin tí Olúwa fún yín láti ẹnu Mose láti ọjọ́ tí Olúwa ti fún yín àti títí dé ìran tó ń bọ̀.
24 and if it was done unintentionally without the knowledge of the congregation, then the whole congregation is to prepare one young bull as a burnt offering, a pleasing aroma to the LORD, with its grain offering and drink offering according to the regulation, and one male goat as a sin offering.
Bí ẹ̀ṣẹ̀ bá wáyé láìròtẹ́lẹ̀ láìjẹ́ pé ìjọ ènìyàn mọ̀ sí i, nígbà náà ni kí gbogbo ìjọ ènìyàn mú ọ̀dọ́ akọ màlúù kan wá fún ẹbọ sísun bí òórùn dídùn sí Olúwa, pẹ̀lú ọrẹ ohun jíjẹ àti ọrẹ ohun mímu rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà, pẹ̀lú akọ ewúrẹ́ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.
25 The priest is to make atonement for the whole congregation of Israel, so that they may be forgiven; for the sin was unintentional and they have brought to the LORD an offering made by fire and a sin offering, presented before the LORD for their unintentional sin.
Àlùfáà yóò sì ṣe ètùtù, fun gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli, a ó sì dáríjì wọ́n, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àìròtẹ́lẹ̀, wọ́n sì ti mú ọrẹ àfinásun wá fún Olúwa nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀.
26 Then the whole congregation of Israel and the foreigners residing among them will be forgiven, since it happened to all the people unintentionally.
A ó dárí jí gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli àti àwọn àjèjì tí ń gbé ní àárín wọn nítorí pé ní àìròtẹ́lẹ̀ ni wọ́n sẹ ẹ̀ṣẹ̀ náà.
27 Also, if one person sins unintentionally, he is to present a year-old female goat as a sin offering.
“‘Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ pé ẹnìkan ló sẹ̀ ní àìròtẹ́lẹ̀, kí ó mú abo ewúrẹ́ ọlọ́dún kan wá fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.
28 And the priest shall make atonement before the LORD on behalf of the person who erred by sinning unintentionally; and when atonement has been made for him, he will be forgiven.
Àlùfáà yóò ṣe ètùtù níwájú Olúwa fún ẹni tó ṣẹ̀ láìròtẹ́lẹ̀, tí wọ́n bá ṣe ètùtù fún un, a ó sì dáríjì í.
29 You shall have the same law for the one who acts in error, whether he is a native-born Israelite or a foreigner residing among you.
Òfin kan kí ẹ̀yin kí ó ní fún ẹnikẹ́ni tó bá ṣẹ̀ ní àìmọ̀, àti fún àwọn ẹni tí a bí nínú àwọn ọmọ Israẹli, àti fún àlejò tí ń ṣe àtìpó.
30 But the person who sins defiantly, whether a native or foreigner, blasphemes the LORD. That person shall be cut off from among his people.
“‘Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni bá mọ̀ ọ́n mọ̀ dẹ́ṣẹ̀ yálà ó jẹ́ ọmọ bíbí ilẹ̀ yín tàbí àlejò, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ti kó ẹ̀gàn bá orúkọ Olúwa, a ó sì gé irú ẹni bẹ́ẹ̀ kúrò lára àwọn ènìyàn rẹ̀.
31 He shall certainly be cut off, because he has despised the word of the LORD and broken His commandment; his guilt remains on him.”
Nítorí pé ẹni náà ti kẹ́gàn ọ̀rọ̀ Olúwa ó sì ti rú òfin rẹ̀, a gbọdọ̀ gé irú ẹni bẹ́ẹ̀ kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀; ẹ̀bi rẹ̀ yóò sì wà lórí rẹ̀.’”
32 While the Israelites were in the wilderness, a man was found gathering wood on the Sabbath day.
Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli wà nínú aginjù, wọ́n rí ọkùnrin kan tí ń ṣá igi ní ọjọ́ Ìsinmi.
33 Those who found the man gathering wood brought him to Moses, Aaron, and the whole congregation,
Àwọn tó sì rí i níbi tó ti ń ṣá igi wọ́n sì mú un wá sí ọ̀dọ̀ Mose àti Aaroni àti síwájú gbogbo ìjọ ènìyàn,
34 and because it had not been declared what should be done to him, they placed him in custody.
wọ́n fi sí ìpamọ́ nítorí pé ohun tí wọn ó ṣe fún un kò tí ì yé wọn.
35 And the LORD said to Moses, “The man must surely be put to death. The whole congregation is to stone him outside the camp.”
Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Kíkú ni ọkùnrin náà yóò kú kí gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli sọ ọ́ lókùúta pa ní ẹ̀yìn ibùdó.”
36 So the whole congregation took the man outside the camp and stoned him to death, as the LORD had commanded Moses.
Wọ́n mú un jáde sí ẹ̀yìn ibùdó, gbogbo ìjọ ènìyàn sì sọ ọ́ lókùúta pa, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.
37 Later, the LORD said to Moses,
Olúwa sọ fún Mose pé,
38 “Speak to the Israelites and tell them that throughout the generations to come they are to make for themselves tassels for the corners of their garments, with a blue cord on each tassel.
“Bá àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀, kí o sọ fún wọn pé: ‘Títí dé àwọn ìran tó ń bọ̀ ni kí wọn máa ṣe wajawaja sí etí aṣọ wọn, kí wọn sì fi okùn tẹ́ẹ́rẹ́ aláwọ̀ búlúù sí wajawaja kọ̀ọ̀kan.
39 These will serve as tassels for you to look at, so that you may remember all the commandments of the LORD, that you may obey them and not prostitute yourselves by following your own heart and your own eyes.
Wajawaja yìí ni ẹ sì máa wọ̀ láti lè mú yín rántí gbogbo òfin Olúwa, kí ẹ bá à lè ṣe wọ́n, kí ẹ sì má bá à ṣe àgbèrè nípa títẹ̀lé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn àti ojú yín.
40 Then you will remember and obey all My commandments, and you will be holy to your God.
Nígbà náà ni ẹ ó gbọ́rọ̀ láti pa gbogbo òfin mi mọ́, ẹ ó sì jẹ́ mímọ́ sí Ọlọ́run yín.
41 I am the LORD your God who brought you out of the land of Egypt to be your God. I am the LORD your God.”
Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín tí ó mú yín jáde láti Ejibiti láti jẹ́ Ọlọ́run yín. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.’”