< Micah 3 >

1 Then I said: “Hear now, O leaders of Jacob, you rulers of the house of Israel. Should you not know justice?
Nígbà náà, ni mo wí pé, “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin olórí Jakọbu, ẹ̀yin alákòóso ilé Israẹli. Ǹjẹ́ ẹ̀yin kò ha ni í gba òdodo bí.
2 You hate good and love evil. You tear the skin from my people and strip the flesh from their bones.
Ẹ̀yin tí ó kórìíra ìre, tí ẹ sì fẹ́ràn ibi; ẹ̀yin tí ẹ fa awọ ẹran-ara àwọn ènìyàn mi ya kúrò lára wọn àti ẹran-ara wọn kúrò ní egungun wọn;
3 You eat the flesh of my people after stripping off their skin and breaking their bones. You chop them up like flesh for the cooking pot, like meat in a cauldron.”
àwọn tí ó jẹ ẹran-ara àwọn ènìyàn mi, wọn sì bọ́ awọ ara wọn kúrò lára wọn. Wọ́n sì fọ́ egungun wọn sí wẹ́wẹ́; wọn sì gé e sí wẹ́wẹ́ bí ẹran inú ìkòkò, bí ẹran inú agbada?”
4 Then they will cry out to the LORD, but He will not answer them. At that time He will hide His face from them because of the evil they have done.
Nígbà náà ni wọn yóò kígbe sí Olúwa, ṣùgbọ́n òun kì yóò dá wọn lóhùn. Ní àkókò náà ni òun yóò fi ojú rẹ̀ pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn, nítorí ibi tí wọ́n ti ṣe.
5 This is what the LORD says: “As for the prophets who lead My people astray, who proclaim peace while they chew with their teeth, but declare war against one who puts nothing in their mouths:
Báyìí ni Olúwa wí, “Ní ti àwọn Wòlíì tí ń ṣi àwọn ènìyàn mi lọ́nà, tí ẹnìkan bá fún wọn ní oúnjẹ, wọn yóò kéde àlàáfíà; ṣùgbọ́n tí kò bá fi nǹkan sí wọn ní ẹnu, wọn yóò múra ogun sí i.
6 Therefore night will come over you without visions, and darkness without divination. The sun will set on these prophets, and the daylight will turn black over them.
Nítorí náà òru yóò wá sórí yín, tí ẹ̀yin kì yóò sì rí ìran kankan, òkùnkùn yóò sì kùn fún yín, tí ẹ̀yin kì yóò sì lè sọtẹ́lẹ̀. Oòrùn yóò sì wọ lórí àwọn wòlíì ọjọ́ yóò sì ṣókùnkùn lórí wọn.
7 Then the seers will be ashamed and the diviners will be disgraced. They will all cover their mouths because there is no answer from God.”
Ojú yóò sì ti àwọn wòlíì àwọn alásọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú yóò sì gba ìtìjú. Gbogbo wọn ni yóò bo ojú wọn, nítorí kò sí ìdáhùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.”
8 As for me, however, I am filled with power by the Spirit of the LORD, with justice and courage, to declare to Jacob his transgression and to Israel his sin.
Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi kún fún agbára pẹ̀lú ẹ̀mí Olúwa, láti sọ ìré-òfin-kọjá Jakọbu fún un, àti láti sọ ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli fún un.
9 Now hear this, O leaders of the house of Jacob and rulers of the house of Israel, who despise justice and pervert all that is right,
Gbọ́ ẹ̀yin olórí ilé Jakọbu, àti ẹ̀yin alákòóso ilé Israẹli, tí ó kórìíra òdodo tí ó sì yí òtítọ́ padà;
10 who build Zion with bloodshed and Jerusalem with iniquity.
tí ó kọ́ Sioni pẹ̀lú ìtàjẹ̀ sílẹ̀, àti Jerusalẹmu pẹ̀lú ìwà búburú.
11 Her leaders judge for a bribe, her priests teach for a price, and her prophets practice divination for money. Yet they lean upon the LORD, saying, “Is not the LORD among us? No disaster can come upon us.”
Àwọn olórí rẹ̀ ń ṣe ìdájọ́ nítorí àbẹ̀tẹ́lẹ̀, àwọn àlùfáà rẹ̀ sì ń kọ́ni nítorí owó ọ̀yà àwọn wòlíì rẹ̀ pẹ̀lú sì ń sọtẹ́lẹ̀ nítorí owó. Síbẹ̀, wọn gbẹ́kẹ̀lé Olúwa, wọ́n sì wí pé, “Nítòótọ́, Olúwa wà pẹ̀lú wa! Ibi kan kì yóò bá wa.”
12 Therefore, because of you, Zion will be plowed like a field, Jerusalem will become a heap of rubble, and the temple mount a wooded ridge.
Nítorí náà, nítorí tiyín, ni a ó ṣe ro Sioni bí oko, Jerusalẹmu yóò sì di ebè àti òkè tẹmpili bí i ibi gíga igbó.

< Micah 3 >