< Joel 3 >

1 “Yes, in those days and at that time, when I restore Judah and Jerusalem from captivity,
“Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àti ní àkókò náà, nígbà tí èmi tún mú ìgbèkùn Juda àti Jerusalẹmu padà bọ̀.
2 I will gather all the nations and bring them down to the Valley of Jehoshaphat. There I will enter into judgment against them concerning My people, My inheritance, Israel, whom they have scattered among the nations as they divided up My land.
Èmi yóò kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ pẹ̀lú èmi yóò sì mú wọn wá sí àfonífojì Jehoṣafati. Èmi yóò sì bá wọn wíjọ́ níbẹ̀ nítorí àwọn ènìyàn mi, àti nítorí Israẹli ìní mi, tí wọ́n fọ́nká sí àárín àwọn orílẹ̀-èdè, wọ́n sì pín ilẹ̀ mi.
3 They cast lots for My people; they bartered a boy for a prostitute and sold a girl for wine to drink.
Wọ́n si ti di ìbò fún àwọn ènìyàn mi; wọ́n sì ti fi ọmọdékùnrin kan fún panṣágà obìnrin kan, wọ́n sì ta ọmọdébìnrin kan fún ọtí wáìnì, kí wọ́n kí ó lè mu.
4 Now what do you have against Me, O Tyre, Sidon, and all the regions of Philistia? Are you rendering against Me a recompense? If you retaliate against Me, I will swiftly and speedily return your recompense upon your heads.
“Nísinsin yìí, kí ni ẹ̀yin ní fi mí ṣe Tire àti Sidoni, àti gbogbo ẹ̀yin ẹkún Filistia? Ẹ̀yin yóò ha sàn ẹ̀san fún mi? Bí ẹ̀yin bá sì san ẹ̀san fún mi, ní kánkán àti ní kíákíá ní èmi yóò san ẹ̀san ohun ti ẹ̀yin ṣe padà sórí ara yín.
5 For you took My silver and gold and carried off My finest treasures to your temples.
Nítorí tí ẹ̀yin tí mú fàdákà mi àti wúrà mi, ẹ̀yin si tí mú ohun rere dáradára mi lọ sínú tẹmpili yín.
6 You sold the people of Judah and Jerusalem to the Greeks, to send them far from their homeland.
Àti àwọn ọmọ Juda, àti àwọn ọmọ Jerusalẹmu ní ẹ̀yin ti tà fún àwọn ará Giriki, kí ẹ̀yin bá à lè sí wọn jìnnà kúrò ní agbègbè ilẹ̀ ìní wọn.
7 Behold, I will rouse them from the places to which you sold them; I will return your recompense upon your heads.
“Kíyèsi í, èmi yóò gbé wọ́n dìde kúrò níbi tì ẹ̀yin ti tà wọ́n sí, èmi yóò sì san ẹ̀san ohun ti ẹ ṣe padà sórí ara yín.
8 I will sell your sons and daughters into the hands of the people of Judah, and they will sell them to the Sabeans—to a distant nation.” Indeed, the LORD has spoken.
Èmi yóò si tà àwọn ọmọkùnrin yín àti àwọn ọmọbìnrin yín sí ọwọ́ àwọn ọmọ Juda, wọ́n yóò sì tà wọ́n fún àwọn ara Sabeani, fún orílẹ̀-èdè kan tí ó jìnnà réré.” Nítorí Olúwa ní o ti sọ ọ.
9 Proclaim this among the nations: “Prepare for war; rouse the mighty men; let all the men of war advance and attack!
Ẹ kéde èyí ní àárín àwọn kèfèrí; ẹ dira ogun, ẹ jí àwọn alágbára. Jẹ kí àwọn ajagun kí wọn bẹ̀rẹ̀ ogun.
10 Beat your plowshares into swords and your pruning hooks into spears. Let the weak say, ‘I am strong!’
Ẹ fi irin ìtulẹ̀ yín rọ idà, àti dòjé yín rọ ọ̀kọ̀. Jẹ́ kí aláìlera wí pé, “Ara mi le koko.”
11 Come quickly, all you surrounding nations, and gather yourselves. Bring down Your mighty ones, O LORD.
Ẹ wá kánkán, gbogbo ẹ̀yin kèfèrí láti gbogbo àyíká, kí ẹ sì gbá ara yín jọ yí káàkiri. Níbẹ̀ ní kí o mú àwọn alágbára rẹ sọ̀kalẹ̀, Olúwa.
12 Let the nations be roused and advance to the Valley of Jehoshaphat, for there I will sit down to judge all the nations on every side.
“Ẹ jí, ẹ sì gòkè wá sí àfonífojì Jehoṣafati ẹ̀yin kèfèrí: nítorí níbẹ̀ ní èmi yóò jókòó láti ṣe ìdájọ́ àwọn kèfèrí yí káàkiri.
13 Swing the sickle, for the harvest is ripe. Come, trample the grapes, for the winepress is full; the wine vats overflow because their wickedness is great.
Ẹ tẹ dòjé bọ̀ ọ́, nítorí ìkórè pọ́n. Ẹ wá, ẹ sọ̀kalẹ̀, nítorí ìfúntí kún, nítorí àwọn ọpọ́n kún àkúnwọ́sílẹ̀, nítorí ìwà búburú wọn pọ̀!”
14 Multitudes, multitudes in the valley of decision! For the Day of the LORD is near in the valley of decision.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní àfonífojì ìpinnu! Nítorí ọjọ́ Olúwa kù si dẹ̀dẹ̀ ní àfonífojì ìdájọ́.
15 The sun and moon will grow dark, and the stars will no longer shine.
Oòrùn àti òṣùpá yóò ṣú òkùnkùn, àti àwọn ìràwọ̀ kí yóò tan ìmọ́lẹ̀ wọn mọ́.
16 The LORD will roar from Zion and raise His voice from Jerusalem; heaven and earth will tremble. But the LORD will be a refuge for His people, a stronghold for the people of Israel.
Olúwa yóò sí ké ramúramù láti Sioni wá, yóò sì fọ ohùn rẹ̀ jáde láti Jerusalẹmu wá; àwọn ọ̀run àti ayé yóò sì mì tìtì. Ṣùgbọ́n Olúwa yóò ṣe ààbò àwọn ènìyàn rẹ̀, àti agbára àwọn ọmọ Israẹli.
17 Then you will know that I am the LORD your God, who dwells in Zion, My holy mountain. Jerusalem will be holy, never again to be overrun by foreigners.
“Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, tí ń gbé Sioni òkè mímọ́ mi. Ìgbà náà ni Jerusalẹmu yóò jẹ́ mímọ́; àwọn àjèjì kì yóò sì kó o mọ́.
18 And in that day the mountains will drip with sweet wine, and the hills will flow with milk. All the streams of Judah will run with water, and a spring will flow from the house of the LORD to water the Valley of Acacias.
“Ní ọjọ́ náà, àwọn òkè ńlá yóò máa kán ọtí wáìnì tuntun sílẹ̀, àwọn òkè kéékèèké yóò máa sàn fún wàrà; gbogbo odò Juda tí ó gbẹ́ yóò máa sàn fún omi. Orísun kan yóò sì ṣàn jáde láti inú ilé Olúwa wá, yóò sì rin omi sí àfonífojì Ṣittimu.
19 Egypt will become desolate, and Edom a desert wasteland, because of the violence done to the people of Judah, in whose land they shed innocent blood.
Ṣùgbọ́n Ejibiti yóò di ahoro, Edomu yóò sì di aṣálẹ̀ ahoro, nítorí ìwà ipá tí a hù sì àwọn ọmọ Juda, ní ilẹ̀ ẹni tí wọ́n ti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀.
20 But Judah will be inhabited forever, and Jerusalem from generation to generation.
Ṣùgbọ́n Juda yóò jẹ́ ibùgbé títí láé, àti Jerusalẹmu láti ìran dé ìran.
21 For I will avenge their blood, which I have not yet avenged.”
Nítorí èmi yóò wẹ ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ wọn nù, tí èmi kò tí ì wẹ̀nù.

< Joel 3 >