< Job 3 >
1 After this, Job opened his mouth and cursed the day of his birth.
Ẹ̀yìn èyí ní Jobu yanu, ó sì fi ọjọ́ ìbí rẹ̀ ré
2 And this is what he said:
Jobu sọ, ó sì wí pé,
3 “May the day of my birth perish, and the night it was said, ‘A boy is conceived.’
“Kí ọjọ́ tí a bí mi kí ó di ìgbàgbé, àti òru ni, nínú èyí tí a wí pé, ‘A lóyún ọmọkùnrin kan!’
4 If only that day had turned to darkness! May God above disregard it; may no light shine upon it.
Kí ọjọ́ náà kí ó já si òkùnkùn, kí Ọlọ́run kí ó má ṣe kà á sí láti ọ̀run wá; bẹ́ẹ̀ ni kí ìmọ́lẹ̀ kí ó má ṣe mọ́ sí i.
5 May darkness and gloom reclaim it, and a cloud settle over it; may the blackness of the day overwhelm it.
Kí òkùnkùn àti òjìji ikú fi ṣe ti ara wọn; kí àwọsánmọ̀ kí ó bà lé e; kí ìṣúdudu ọjọ́ kí ó pa láyà.
6 If only darkness had taken that night away! May it not appear among the days of the year; may it never be entered in any of the months.
Kí òkùnkùn kí ó ṣú bo òru náà biribiri, kí ó má ṣe yọ pẹ̀lú ọjọ́ ọdún náà: kí a má ṣe kà a mọ́ iye ọjọ́ oṣù.
7 Behold, may that night be barren; may no joyful voice come into it.
Kí òru náà kí ó yàgàn; kí ohun ayọ̀ kan kí ó má ṣe wọ inú rẹ̀ lọ.
8 May it be cursed by those who curse the day — those prepared to rouse Leviathan.
Kí àwọn tí í fi ọjọ́ gégùn ún kí o fi gégùn ún, tí wọ́n mura tán láti ru Lefitani sókè.
9 May its morning stars grow dark; may it wait in vain for daylight; may it not see the breaking of dawn.
Kí ìràwọ̀ òwúrọ̀ ọjọ́ rẹ̀ kí ó ṣókùnkùn; kí ó má wá ìmọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n kí ó máa mọ́ sí i, bẹ́ẹ̀ ni kí ó má ṣe rí àfẹ̀mọ́júmọ́
10 For that night did not shut the doors of the womb to hide the sorrow from my eyes.
nítorí tí kò sé ìlẹ̀kùn inú ìyá mi, láti pa ìbànújẹ́ rẹ́ ní ojú mi.
11 Why did I not perish at birth; why did I not die as I came from the womb?
“Èéṣe tí èmi kò fi kú láti inú wá, tàbí tí èmi kò kú ní ìgbà tí mo ti inú jáde wá?
12 Why were there knees to receive me, and breasts that I should be nursed?
Èéṣe tí orúnkún wá pàdé mi, tàbí ọmú tí èmi yóò mu?
13 For now I would be lying down in peace; I would be asleep and at rest
Ǹjẹ́ nísinsin yìí èmi ìbá ti dùbúlẹ̀ jẹ́ẹ́; èmi ìbá ti sùn, èmi ìbá ti sinmi
14 with kings and counselors of the earth, who built for themselves cities now in ruins,
pẹ̀lú àwọn ọba àti ìgbìmọ̀ ayé tí wọ́n mọ ilé fún ara wọn wá dùbúlẹ̀ nínú ìsọdahoro.
15 or with princes who had gold, who filled their houses with silver.
Tàbí pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé tí ó ní wúrà, tí wọ́n sì fi fàdákà kun ilé wọn.
16 Or why was I not hidden like a stillborn child, like an infant who never sees daylight?
Tàbí bí ọlẹ̀ tí a sin, èmi kì bá ti sí: bí ọmọ ìṣunú tí kò rí ìmọ́lẹ̀?
17 There the wicked cease from raging, and there the weary find rest.
Níbẹ̀ ni ẹni búburú ṣíwọ́ ìyọnilẹ́nu, níbẹ̀ ni ẹni àárẹ̀ wà nínú ìsinmi.
18 The captives enjoy their ease; they do not hear the voice of the oppressor.
Níbẹ̀ ni àwọn ìgbèkùn sinmi pọ̀, wọn kò gbóhùn amúnisìn mọ́.
19 Both small and great are there, and the slave is freed from his master.
Àti èwe àti àgbà wà níbẹ̀, ẹrú sì di òmìnira kúrò lọ́wọ́ olówó rẹ̀.
20 Why is light given to the miserable, and life to the bitter of soul,
“Nítorí kí ni a ṣe fi ìmọ́lẹ̀ fún òtòṣì, àti ìyè fún ọlọ́kàn kíkorò,
21 who long for death that does not come, and search for it like hidden treasure,
tí wọ́n dúró de ikú, ṣùgbọ́n òun kò wá, tí wọ́n wá a jù ìṣúra tí a bò mọ́lẹ̀ pamọ́ lọ.
22 who rejoice and greatly exult when they can find the grave?
Ẹni tí ó yọ̀ gidigidi, tí inú wọ́n sì dùn nígbà tí wọ́n wá ibojì òkú rí?
23 Why is life given to a man whose way is hidden, whom God has hedged in?
Kí ni a fi ìmọ́lẹ̀ fún ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ fi ara pamọ́ fún, tí Ọlọ́run sì ṣọgbà dí mọ́ ká?
24 I sigh when food is put before me, and my groans pour out like water.
Nítorí pé èémí-ẹ̀dùn wà ṣáájú oúnjẹ mi; ìkérora mi sì tú jáde bí omi.
25 For the thing I feared has overtaken me, and what I dreaded has befallen me.
Nítorí pé ohun náà tí mo bẹ̀rù gidigidi ni ó dé bá mi yìí, àti ohun tí mo fòyà rẹ̀ bá mi ó sì ṣubú lù mí.
26 I am not at ease or quiet; I have no rest, for trouble has come.”
Èmi wà láìní àlàáfíà, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ní ìsinmi; bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ni ìfàyàbalẹ̀, bí kò ṣe ìdààmú.”