< Ezekiel 30 >

1 Again the word of the LORD came to me, saying,
Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá: wí pé:
2 “Son of man, prophesy and declare that this is what the Lord GOD says: Wail, ‘Alas for that day!’
“Ọmọ ènìyàn, sọtẹ́lẹ̀ kí o sì wí pé: ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: “‘Hu, kí o sì wí pé, “Ó ṣe fún ọjọ́ náà!”
3 For the day is near, the Day of the LORD is near. It will be a day of clouds, a time of doom for the nations.
Nítorí ọjọ́ náà súnmọ́ tòsí àní ọjọ́ Olúwa súnmọ́ tòsí, ọjọ́ tí ọjọ́ ìkùùkuu ṣú dúdú, àsìkò ìparun fún àwọn kèfèrí.
4 A sword will come against Egypt, and there will be anguish in Cush when the slain fall in Egypt, its wealth is taken away, and its foundations are torn down.
Idà yóò wá sórí Ejibiti ìrora ńlá yóò sì wá sórí Kuṣi. Nígbà tí àwọn tí a pa yóò ṣubú ní Ejibiti wọn yóò kò ọrọ̀ rẹ̀ lọ ìpìlẹ̀ rẹ̀ yóò sì wó lulẹ̀.
5 Cush, Put, and Lud, and all the various peoples, as well as Libya and the men of the covenant land, will fall with Egypt by the sword.
Kuṣi àti Puti, Libia, Ludi àti gbogbo Arabia, Kubu àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà tí ó mulẹ̀ yóò ṣubú nípa idà pẹ̀lú Ejibiti.
6 For this is what the LORD says: The allies of Egypt will fall, and her proud strength will collapse. From Migdol to Syene they will fall by the sword within her,
“‘Èyí yìí ní Olúwa wí: “‘Àwọn àlejò Ejibiti yóò ṣubú agbára ìgbéraga rẹ yóò kùnà láti Migdoli títí dé Siene, wọn yóò ti ipa idà ṣubú nínú rẹ; ní Olúwa Olódùmarè wí.
7 They will be desolate among desolate lands, and their cities will lie among ruined cities.
Wọn yóò sì wà lára àwọn ilẹ̀ tí ó di ahoro, ìlú rẹ yóò sì wà ní ara àwọn ìlú tí ó di ahoro.
8 Then they will know that I am the LORD when I set fire to Egypt and all her helpers are shattered.
Lẹ́yìn náà wọn yóò mọ̀ pé èmi ní Olúwa, nígbà tí mo bá gbé iná kalẹ̀ ní Ejibiti tí gbogbo àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ bá parun.
9 On that day messengers will go out from Me in ships to frighten Cush out of complacency. Anguish will come upon them on the day of Egypt’s doom. For it is indeed coming.
“‘Ní ọjọ́ náà oníṣẹ́ yóò ti ọ̀dọ̀ mi jáde nínú ọkọ̀ ojú omi láti dẹ́rùbà Kuṣi tí ó wà nínú àlàáfíà. Ìrora yóò wá sórí wọn gẹ́gẹ́ bí ti ọjọ́ ìparun Ejibiti. Kíyèsi i, ó dé.
10 This is what the Lord GOD says: I will put an end to the hordes of Egypt by the hand of Nebuchadnezzar king of Babylon.
“‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: “‘Èmi yóò mú òpin bá ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn Ejibiti láti ọwọ́ Nebukadnessari ọba Babeli.
11 He and his people with him, the most ruthless of the nations, will be brought in to destroy the land. They will draw their swords against Egypt and fill the land with the slain.
Òun àti àwọn ológun rẹ̀ ẹ̀rù àwọn orílẹ̀-èdè ní a o mú wá láti pa ilẹ̀ náà run. Wọn yóò fa idà wọn yọ sí Ejibiti ilẹ̀ náà yóò sì kún fún àwọn tí a pa.
12 I will make the streams dry up and sell the land to the wicked. By the hands of foreigners I will bring desolation upon the land and everything in it.
Èmi yóò mú kí àwọn odò Naili gbẹ, Èmi yóò sì ta ilẹ̀ náà fún àwọn ènìyàn búburú: láti ọwọ́ àwọn àjèjì ènìyàn, Èmi yóò jẹ́ kí ilẹ̀ náà àti gbogbo ohun tí ó wá nínú rẹ ṣòfò. Èmi Olúwa ni ó ti sọ ọ́.
13 This is what the Lord GOD says: I will destroy the idols and put an end to the images in Memphis. There will no longer be a prince in Egypt, and I will instill fear in that land.
“‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: “‘Èmi yóò pa àwọn òrìṣà run, Èmi yóò sì mú kí òpin dé bá ère gbígbẹ́ ni Memfisi. Kò ní sí ọmọ-aládé mọ́ ní Ejibiti, Èmi yóò mú kí ìbẹ̀rù gba gbogbo ilẹ̀ náà.
14 I will lay waste Pathros, set fire to Zoan, and execute judgment on Thebes.
Èmi yóò sì mú kí Paturosi di ahoro, èmi yóò fi iná sí Ṣoani, èmi yóò sì fi ìyà jẹ Tebesi.
15 I will pour out My wrath on Pelusium, the stronghold of Egypt, and cut off the crowds of Thebes.
Èmi yóò tú ìbínú mi jáde sórí Pelusiumu ìlú odi Ejibiti èmi yóò sì ké àkójọpọ̀ Tebesi kúrò.
16 I will set fire to Egypt, Pelusium will writhe in anguish, Thebes will be split open, and Memphis will face daily distress.
Èmi yóò ti iná bọ Ejibiti Pelusiumu yóò japoró ní ìrora. Ìjì líle yóò jà ní Tebesi Memfisi yóò wà ìpọ́njú ní ìgbà gbogbo.
17 The young men of On and Pi-beseth will fall by the sword, and those cities will go into captivity.
Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin ní Heliopolisi àti Bubasiti yóò ti ipa idà ṣubú wọn yóò sì kó àwọn ìlú wọn ní ìgbèkùn.
18 The day will be darkened in Tahpanhes when I break the yoke of Egypt and her proud strength comes to an end. A cloud will cover her, and her daughters will go into captivity.
Ojú ọjọ́ yóò ṣókùnkùn ní Tafanesi nígbà tí mo bá já àjàgà Ejibiti kúrò; níbẹ̀ agbára iyì rẹ̀ yóò dópin wọn yóò fi ìkùùkuu bò ó àwọn abúlé rẹ ní wọn yóò lọ sí ìgbèkùn.
19 So I will execute judgment on Egypt, and they will know that I am the LORD.”
Nítorí náà, Èmi yóò mú ki ìjìyà wá sórí Ejibiti, wọn yóò sì mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa.’”
20 In the eleventh year, on the seventh day of the first month, the word of the LORD came to me, saying,
Ní ọjọ́ keje oṣù kìn-ín-ní ọdún kọkànlá ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá,
21 “Son of man, I have broken the arm of Pharaoh king of Egypt. See, it has not been bound up for healing, or splinted for strength to hold the sword.
“Ọmọ ènìyàn, Èmi ti ṣẹ́ apá Farao ọba Ejibiti. A kò ì tí ì di apá náà papọ̀ láti mu kí ó san, a kò sì ti di i si àárín igi pẹlẹbẹ kí o lè ni agbára tó láti di idà mú.
22 Therefore this is what the Lord GOD says: Behold, I am against Pharaoh king of Egypt. I will break his arms, both the strong one and the one already broken, and will make the sword fall from his hand.
Nítorí náà, báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Èmi lòdì sí Farao ọba Ejibiti. Èmi yóò sẹ́ apá rẹ̀ méjèèjì, èyí tí ó dára àti èyí tí a ti ṣẹ́ pẹ̀lú, yóò sì mú kí idà bọ́ sọnù ní ọwọ́ rẹ̀.
23 I will disperse the Egyptians among the nations and scatter them throughout the lands.
Èmi yóò sì fọ́n àwọn ènìyàn Ejibiti ká sí àárín àwọn orílẹ̀-èdè, èmi yóò sì tú wọn ká gbogbo ilẹ̀.
24 I will strengthen the arms of Babylon’s king and place My sword in his hand, but I will break the arms of Pharaoh, who will groan before him like a mortally wounded man.
Èmi yóò mú kí apá ọba Babeli ní agbára, èmi yóò sì fi idà mi sí ọwọ́ rẹ, ṣùgbọ́n èmi yóò ṣẹ́ apá Farao, yóò sì kérora níwájú rẹ̀ bí ọkùnrin tí a sá ní àṣápa.
25 I will strengthen the arms of Babylon’s king, but Pharaoh’s arms will fall limp. Then they will know that I am the LORD, when I place My sword in the hand of Babylon’s king, and he wields it against the land of Egypt.
Èmi yóò mú kí apá ọba Babeli lé, ṣùgbọ́n apá Farao yóò sì rọ. Nígbà náà wọn yóò mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa, nígbà tí mo bá mú idà mi sí ọwọ́ ọba Babeli yóò sì fi idà náà kọlu Ejibiti.
26 I will disperse the Egyptians among the nations and scatter them throughout the lands. Then they will know that I am the LORD.”
Èmi yóò fọ́n àwọn ara Ejibiti ká sí àárín orílẹ̀-èdè, èmi yóò sì tú wọn ká sí àárín orílẹ̀-èdè, èmi yóò sì tú wọn ká sí gbogbo ilẹ̀. Nígbà náà wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.”

< Ezekiel 30 >