< Exodus 11 >
1 Then the LORD said to Moses, “I will bring upon Pharaoh and Egypt one more plague. After that, he will allow you to leave this place. And when he lets you go, he will drive you out completely.
Nísinsin yìí, Olúwa sọ fún Mose pé èmi yóò mú ààrùn kan sí i wá sí orí Farao àti ilẹ̀ Ejibiti. Lẹ́yìn náà yóò jẹ́ kí ẹ̀yin kí ó lọ kúrò níhìn-ín yìí, nígbà tí ó bá sì ṣe bẹ́ẹ̀ yóò lé yín jáde pátápátá.
2 Now announce to the people that men and women alike should ask their neighbors for articles of silver and gold.”
Sọ fún àwọn ènìyàn náà pé kí tọkùnrin tobìnrin wọn béèrè fún ohun èlò fàdákà àti wúrà lọ́wọ́ aládùúgbò rẹ̀.
3 And the LORD gave the people favor in the sight of the Egyptians. Moreover, Moses himself was highly regarded in Egypt by Pharaoh’s officials and by the people.
(Olúwa jẹ́ kí wọn rí ojúrere àwọn ará Ejibiti, pàápàá, Mose fúnra rẹ̀ di ènìyàn pàtàkì ní ilẹ̀ Ejibiti ní iwájú àwọn ìjòyè Farao àti ní iwájú àwọn ènìyàn pẹ̀lú).
4 So Moses declared, “This is what the LORD says: ‘About midnight I will go throughout Egypt,
Nígbà náà ni Mose wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ, ‘Ní ọ̀gànjọ́ òru èmi yóò la ilẹ̀ Ejibiti kọjá.
5 and every firstborn son in the land of Egypt will die, from the firstborn of Pharaoh who sits on his throne, to the firstborn of the servant girl behind the hand mill, as well as the firstborn of all the cattle.
Gbogbo àkọ́bí ọmọkùnrin tí ó wà ní ilẹ̀ Ejibiti ni yóò kùú, bẹ̀rẹ̀ lórí àkọ́bí ọkùnrin Farao tí ó jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀, tí ó fi dé orí àkọ́bí ọmọkùnrin ti ẹrúbìnrin tí ń lọ ọlọ àti gbogbo àkọ́bí ẹran ọ̀sìn pẹ̀lú.
6 Then a great cry will go out over all the land of Egypt. Such an outcry has never been heard before and will never be heard again.
Igbe ẹkún ńlá yóò sọ jákèjádò gbogbo ilẹ̀ Ejibiti. Irú ohun búburú tí kò ṣẹlẹ̀ rí tí kò sí tún ni ṣẹlẹ̀ mọ́.
7 But among all the Israelites, not even a dog will snarl at man or beast.’ Then you will know that the LORD makes a distinction between Egypt and Israel.
Ṣùgbọ́n láàrín àwọn ará Israẹli ajá lásán kò ní gbó àwọn ènìyàn tàbí àwọn ẹran wọn.’ Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé Olúwa ti fi ìyàtọ̀ sáàrín àwọn ará Ejibiti àti Israẹli.
8 And all these officials of yours will come and bow before me, saying, ‘Go, you and all the people who follow you!’ After that, I will depart.” And hot with anger, Moses left Pharaoh’s presence.
Gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀ wọ̀nyí yóò tọ̀ mí wá, wọn yóò wólẹ̀ ni iwájú, mi wọn yóò sì máa wí pé, ‘Lọ àti àwọn ènìyàn tí ó tẹ̀lé ọ!’ Lẹ́yìn náà èmi yóò jáde.” Nígbà náà ni Mose fi ìbínú jáde kúrò ní iwájú Farao.
9 The LORD said to Moses, “Pharaoh will not listen to you, so that My wonders may be multiplied in the land of Egypt.”
Olúwa ti sọ fún Mose pé, “Farao yóò kọ̀ láti fetísílẹ̀ sí ọ kí iṣẹ́ ìyanu mí le pọ̀ sí ní Ejibiti.”
10 Moses and Aaron did all these wonders before Pharaoh, but the LORD hardened Pharaoh’s heart so that he would not let the Israelites go out of his land.
Mose àti Aaroni ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí níwájú Farao, ṣùgbọ́n Olúwa sé ọkàn Farao le, òun kò sí jẹ́ kí àwọn Israẹli jáde kúrò ni orílẹ̀-èdè rẹ̀.