< 2 Samuel 9 >
1 Then David asked, “Is there anyone left from the house of Saul to whom I can show kindness for the sake of Jonathan?”
Dafidi sì béèrè pé, ọ̀kan nínú àwọn ẹni tí ń ṣe ìdílé Saulu kù síbẹ̀ bí? Kí èmi lè ṣe oore fún un nítorí Jonatani.
2 And there was a servant of Saul’s family named Ziba. They summoned him to David, and the king inquired, “Are you Ziba?” “I am your servant,” he replied.
Ìránṣẹ́ kan sì ti wà ní ìdílé Saulu, orúkọ rẹ̀ sí ń jẹ́ Ṣiba, wọ́n sì pè é wá sọ́dọ̀ Dafidi, ọba sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ìwọ ni Ṣiba bí?” Ó sì dáhùn wí pé, “Ìránṣẹ́ rẹ ni.”
3 So the king asked, “Is there anyone left of Saul’s family to whom I can show the kindness of God?” Ziba answered, “There is still Jonathan’s son, who is lame in both feet.”
Ọba sì wí pé, “Kò ha sí ọ̀kan nínú ìdílé Saulu síbẹ̀, kí èmi ṣe oore Ọlọ́run fún un?” Ṣiba sì wí fún ọba pé, “Jonatani ní ọmọ kan síbẹ̀ tó ya arọ.”
4 “Where is he?” replied the king. And Ziba said, “Indeed, he is in Lo-debar at the house of Machir son of Ammiel.”
Ọba sì wí fún un pé, “Níbo ni ó gbé wà?” Ṣiba sì wí fún ọba pé, “Wò ó, òun wà ní ilé Makiri, ọmọ Ammieli, ní Lo-Debari.”
5 So King David had him brought from the house of Machir son of Ammiel in Lo-debar.
Dafidi ọba sì ránṣẹ́, ó sì mú un láti ilé Makiri ọmọ Ammieli láti Lo-Debari wá.
6 And when Mephibosheth son of Jonathan, the son of Saul, came to David, he fell facedown in reverence. Then David said, “Mephibosheth!” “I am your servant,” he replied.
Mefiboṣeti ọmọ Jonatani ọmọ Saulu sì tọ Dafidi wá, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì bú ọlá fún un. Dafidi sì wí pé, “Mefiboṣeti!” Òun sì dáhùn wí pé, “Wò ó, ìránṣẹ́ rẹ!”
7 “Do not be afraid,” said David, “for surely I will show you kindness for the sake of your father Jonathan. I will restore to you all the land of your grandfather Saul, and you will always eat at my table.”
Dafidi sì wí fún un pé, “Má ṣe bẹ̀rù, nítorí pé nítòótọ́ èmi ó ṣe oore fún ọ nítorí Jonatani baba rẹ, èmi ó sì tún fi gbogbo ilé Saulu baba rẹ fún ọ, ìwọ ó sì máa bá mi jẹun nígbà gbogbo ní ibi oúnjẹ mi.”
8 Mephibosheth bowed down and said, “What is your servant, that you should show regard for a dead dog like me?”
Mefiboṣeti sì tẹríba, ó sì wí pé, “Kí ni ìránṣẹ́ rẹ jásí, tí ìwọ ó fi máa wo òkú ajá bí èmi.”
9 Then the king summoned Saul’s servant Ziba and said to him, “I have given to your master’s grandson all that belonged to Saul and to all his house.
Ọba sì pe Ṣiba ìránṣẹ́ Saulu, ó sì wí fún un pé, “Gbogbo nǹkan tí í ṣe ti Saulu, àti gbogbo èyí tí í ṣe ti ìdílé rẹ̀ ni èmi fi fún ọmọ olúwa rẹ.
10 You and your sons and servants are to work the ground for him and bring in the harvest, so that your master’s grandson may have food to eat. But Mephibosheth, your master’s grandson, is always to eat at my table.” Now Ziba had fifteen sons and twenty servants.
Ìwọ, àti àwọn ọmọ rẹ, àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ ni yóò sì máa ro ilẹ̀ náà fún un, ìwọ ni yóò sì máa mú ìkórè wá, ọmọ olúwa rẹ yóò sì máa rí oúnjẹ jẹ, ṣùgbọ́n Mefiboṣeti ọmọ olúwa rẹ yóò sì máa bá mi jẹun nígbà gbogbo ní ibi oúnjẹ mi.” (Ṣiba sì ní ọmọ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún àti ogún ìránṣẹ́kùnrin.)
11 And Ziba said to the king, “Your servant will do all that my lord the king has commanded.” So Mephibosheth ate at David’s table like one of the king’s own sons.
Ṣiba sì wí fún ọba pé, “Gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí olúwa mi ọba ti pàṣẹ fún ìránṣẹ́ rẹ, bẹ́ẹ̀ náà ni ìránṣẹ́ rẹ ó ṣe.” Ọba sì wí pé, “Ní ti Mefiboṣeti, yóò máa jẹun ní ibi oúnjẹ mi, gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọba.”
12 And Mephibosheth had a young son named Mica, and all who dwelt in the house of Ziba were servants of Mephibosheth.
Mefiboṣeti sì ní ọmọ kékeré kan, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mika. Gbogbo àwọn tí ń gbé ní ilé Ṣiba ni ó sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún Mefiboṣeti.
13 So Mephibosheth lived in Jerusalem, because he always ate at the king’s table, and he was lame in both feet.
Mefiboṣeti sì ń gbé ní Jerusalẹmu, òun a sì máa jẹun nígbà gbogbo ní ibi oúnjẹ ọba; òun sì yarọ ní ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì.