< 2 Samuel 4 >

1 Now when Ish-bosheth son of Saul heard that Abner had died in Hebron, he lost courage, and all Israel was dismayed.
Nígbà tí ọmọ Saulu sì gbọ́ pé, Abneri kú ní Hebroni, ọwọ́ rẹ̀ sì rọ, gbogbo Israẹli sì rẹ̀wẹ̀sì.
2 Saul’s son had two men who were leaders of raiding parties. One was named Baanah and the other Rechab; they were sons of Rimmon the Beerothite of the tribe of Benjamin—Beeroth is considered part of Benjamin,
Ọmọ Saulu sì ní ọkùnrin méjì tí í ṣe olórí ẹgbẹ́ ogun: a ń pe orúkọ ọ̀kan ní Baanah, àti orúkọ èkejì ní Rekabu, àwọn ọmọ Rimoni ará Beeroti ti àwọn ọmọ Benjamini (nítorí pé a sì ka Beeroti pẹ̀lú Benjamini).
3 because the Beerothites fled to Gittaim and have lived there as foreigners to this day.
Àwọn ará Beeroti sì ti sálọ sí Gittaimu, wọ́n sì ṣe àtìpó níbẹ̀ títí ó fi di ọjọ́ òní yìí.
4 And Jonathan son of Saul had a son who was lame in his feet. He was five years old when the report about Saul and Jonathan came from Jezreel. His nurse picked him up and fled, but as she was hurrying to escape, he fell and became lame. His name was Mephibosheth.
(Jonatani ọmọ Saulu sì ti bí ọmọkùnrin kan tí ẹsẹ̀ rẹ̀ rọ, òun sì jẹ́ ọdún márùn-ún, nígbà tí ìròyìn dé ní ti Saulu àti Jonatani láti Jesreeli wá, olùtọ́ rẹ̀ sì gbé e, o sì sálọ, ó sì ṣe, bí ó sì ti ń yára láti sálọ, òun sì ṣubú, ó sì ya arọ. Orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Mefiboṣeti.)
5 Now Rechab and Baanah, the sons of Rimmon the Beerothite, set out and arrived at the house of Ish-bosheth in the heat of the day, while the king was taking his midday nap.
Àwọn ọmọ Rimoni, ará Beeroti, Rekabu àti Baanah sì lọ wọ́n sì wá síh ilé Iṣboṣeti ní ọ̀sán gangan, òun sì sinmi lórí ibùsùn kan ní ọjọ́-kanrí.
6 They entered the interior of the house as if to get some wheat, and they stabbed him in the stomach. Then Rechab and his brother Baanah slipped away.
Sì wò ó, bí olùṣọ́ ẹnu-ọ̀nà ilé náà ti ń gbọn àwọn pàǹtí, ó tòògbé ó sì sùn lọ, wọ́n sì wá sí àárín ilé náà, wọ́n sì ṣe bí ẹni pé wọ́n ń fẹ́ mú alikama; wọ́n sì gún un lábẹ́ inú. Rekabu àti Baanah arákùnrin rẹ̀ sì sálọ.
7 They had entered the house while Ish-bosheth was lying on his bed, and having stabbed and killed him, they beheaded him, took his head, and traveled all night by way of the Arabah.
Nígbà tí wọ́n wọ ilé náà lọ, òun sì dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀ nínú iyàrá rẹ̀, wọ́n sì pa á, wọ́n sì bẹ́ ẹ lórí, wọ́n gbé orí sálọ, wọ́n sì fi gbogbo òru rìn ni pẹ̀tẹ́lẹ̀ náà.
8 They brought the head of Ish-bosheth to David at Hebron and said to the king, “Here is the head of Ish-bosheth son of Saul, your enemy who sought your life. Today the LORD has granted vengeance to my lord the king against Saul and his offspring.”
Wọ́n sì gbé orí Iṣboṣeti tọ Dafidi wá ní Hebroni, wọ́n sì wí fún ọba pé, “Wò ó, orí Iṣboṣeti ọmọ Saulu ọ̀tá rẹ, tí ó ti ń wá ẹ̀mí rẹ kiri, Olúwa ti gbẹ̀san fún ọba olúwa mi lónìí lára Saulu àti lára irú-ọmọ rẹ̀.”
9 But David answered Rechab and his brother Baanah, the sons of Rimmon the Beerothite, “As surely as the LORD lives, who has redeemed my life from all distress,
Dafidi sì dá Rekabu àti Baanah arákùnrin rẹ̀, àwọn ọmọ Rimoni ará Beeroti lóhùn, ó sì wí fún wọn pé, “Bí Olúwa ti ń bẹ, ẹni tí ó gba ẹ̀mí mi lọ́wọ́ gbogbo ìpọ́njú.
10 when someone told me, ‘Look, Saul is dead,’ and thought he was a bearer of good news, I seized him and put him to death at Ziklag. That was his reward for his news!
Nígbà tí ẹnìkan rò fún mi pé, ‘Wò ó, Saulu ti kú,’ lójú ara rẹ̀ òun sì jásí ẹni tí ó mú ìyìnrere wá, èmi sì mú un, mo sì pa á ní Siklagi, ẹni tí ó ṣe bí òun ó rí nǹkan gbà nítorí ìròyìn rere rẹ̀.
11 How much more, when wicked men kill a righteous man in his own house and on his own bed, shall I not now require his blood from your hands and remove you from the earth!”
Mélòó mélòó ni, nígbà tí àwọn ìkà ènìyàn pa olódodo ènìyàn kan ni ilé rẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀—ǹjẹ́ èmi ha sì lè ṣe aláìbéèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ yín bí? Kí èmi sì mú yín kúrò láààyè.”
12 So David commanded his young men, and they killed Rechab and Baanah. They cut off their hands and feet and hung their bodies by the pool in Hebron, but they took the head of Ish-bosheth and buried it in Abner’s tomb in Hebron.
Dafidi sì fi àṣẹ fún àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ̀, wọ́n sì pa wọ́n, wọ́n sì gé ọwọ́ àti ẹsẹ̀ wọn, a sì fi wọ́n há lórí igi ní Hebroni. Ṣùgbọ́n wọ́n mú orí Iṣboṣeti, wọ́n sì sin ín ní ibojì Abneri ní Hebroni.

< 2 Samuel 4 >