< 2 Chronicles 3 >
1 Then Solomon began to build the house of the LORD in Jerusalem on Mount Moriah, where the LORD had appeared to his father David. This was the place that David had prepared on the threshing floor of Ornan the Jebusite.
Nígbà náà, Solomoni bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ́ ilé Olúwa ní Jerusalẹmu lórí òkè Moria, níbi tí Olúwa ti farahan baba a rẹ̀ Dafidi. Ní orí ilẹ̀ ìpakà Arauna ará Jebusi, ibi tí Dafidi pèsè.
2 Solomon began construction on the second day of the second month in the fourth year of his reign.
Ó bẹ̀rẹ̀ sí kíkọ́ rẹ̀ ní ọjọ́ kejì oṣù kejì ní ọdún kẹrin ìjọba rẹ̀.
3 The foundation that Solomon laid for the house of God was sixty cubits long and twenty cubits wide, according to the old standard.
Ìpìlẹ̀ tí Solomoni gbé kalẹ̀ fún kíkọ́ ilé Ọlọ́run jẹ́ ọgọ́ta gígùn ìgbọ̀nwọ́ àti ogún fífẹ̀ ìgbọ̀nwọ́.
4 The portico at the front, extending across the width of the temple, was twenty cubits long and twenty cubits high. He overlaid the inside with pure gold.
Ìloro tí ó wà níwájú ilé Olúwa náà jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn rékọjá fífẹ̀ ilé náà àti gíga rẹ̀ jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn rékọjá fífẹ̀ ilé náà àti gíga rẹ̀ jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́. Ó tẹ́ inú rẹ̀ pẹ̀lú kìkì wúrà.
5 He paneled the main room with cypress, which he overlaid with fine gold and decorated with palm trees and chains.
Ó fi igi firi bo ilé yàrá ńlá náà ó sì bò ó pẹ̀lú kìkì wúrà, ó sì ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú igi ọ̀pẹ àti àwòrán ẹ̀wọ̀n.
6 He adorned the temple with precious stones for beauty, and its gold was from Parvaim.
Ó ṣe ilé Olúwa náà lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú òkúta iyebíye. Wúrà tí ó lò jẹ́ wúrà parifaimu.
7 He overlaid its beams, thresholds, walls, and doors with gold, and he carved cherubim on the walls.
Ó tẹ́ àjà ilé náà pẹ̀lú ìtí igi àti ìlẹ̀kùn ògiri àti àwọn ìlẹ̀kùn ilé Olúwa pẹ̀lú wúrà, ó sì gbẹ́ àwòrán kérúbù sára ògiri.
8 Then he made the Most Holy Place; its length corresponded to the width of the temple—twenty cubits long and twenty cubits wide. And he overlaid the inside with six hundred talents of fine gold.
Ó kọ́ Ibi Mímọ́ Jùlọ, gígùn rẹ̀ bá fífẹ̀ ilé Olúwa mu, ogún ìgbọ̀nwọ́ fún gígùn, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́, ó tẹ́ inú rẹ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ̀ta tálẹ́ǹtì ti wúrà dáradára.
9 The weight of the nails was fifty shekels of gold. He also overlaid the upper area with gold.
Ìwọ̀n àwọn ìṣó náà jẹ́ àádọ́ta ṣékélì. Ó tẹ́ àwọn apẹ òkè pẹ̀lú wúrà.
10 In the Most Holy Place he made two cherubim of sculptured work, and he overlaid them with gold.
Ní Ibi Mímọ́ Jùlọ, ó gbẹ́ àwòrán igi kérúbù kan, ó sì tẹ́ wọn pẹ̀lú wúrà.
11 The total wingspan of the cherubim was twenty cubits. One wing of the first cherub was five cubits long and touched the wall of the temple, and its other wing was five cubits long and touched the wing of the other cherub.
Iye ìyẹ́ apá ìbú àtẹ́lẹwọ́ lápapọ̀ ní ti kérúbù, jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ ọ̀kan nínú ìyẹ́ apá ti kérúbù àkọ́kọ́ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gígùn, ó sì farakan ògiri ilé Olúwa. Nígbà tí ìyẹ́ apá kejì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gígùn ó sì, farakan ìyẹ́ apá kérúbù mìíràn.
12 The wing of the second cherub also measured five cubits and touched the wall of the temple, while its other wing measured five cubits and touched the wing of the first cherub.
Ní ìjọra, ìyẹ́ apá kan ti kérúbù kejì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gígùn, ó sì farakan ògiri ilé Olúwa mìíràn; ìyẹ́ apá rẹ̀ mìíràn sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn ní gígùn pẹ̀lú tí ó farakan ìyẹ́ apá kérúbù àkọ́kọ́.
13 So the total wingspan of these cherubim was twenty cubits. They stood on their feet, facing the main room.
Ìyẹ́ apá àwọn kérúbù wọ̀nyí gbà tó ogún ìgbọ̀nwọ́. Wọ́n dúró ní ẹsẹ̀ wọn, wọ́n kọjú sí yàrá pàtàkì ńlá náà.
14 He made the veil of blue, purple, and crimson yarn and fine linen, with cherubim woven into it.
Ó ṣe aṣọ títa ní àwọ̀ ojú ọ̀run, àwọ̀ àlùkò àti àwọ̀ pupa fòò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ pẹ̀lú kérúbù tí a ṣe sórí i rẹ̀.
15 In front of the temple he made two pillars, which together were thirty-five cubits high, each with a capital on top measuring five cubits.
Níwájú ilé Olúwa náà ó ṣe òpó méjì tí lápapọ̀ jẹ́ márùn-ún dín lógójì ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, olúkúlùkù pẹ̀lú olórí lórí rẹ̀ tí o ń wọn ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún.
16 He made interwoven chains and put them on top of the pillars. He made a hundred pomegranates and fastened them into the chainwork.
Ó ṣe ẹ̀wọ̀n tí a hun wọ inú ara wọn, ó gbé wọn ká orí òpó náà. Ó ṣe ọgọ́rùn-ún pomegiranate (orúkọ èso igi) ó sì so wọ́n mọ́ àwọn ẹ̀wọ̀n náà
17 Then he set up the pillars in front of the temple, one on the south and one on the north. The pillar on the south he named Jachin, and the pillar on the north he named Boaz.
Ó gbe òpó náà dúró níwájú ilé Olúwa, ọ̀kan sí gúúsù, pẹ̀lú ọ̀kan sí àríwá. Èyí ti gúúsù, ó sọ ní Jakini àti èyí ti àríwá, ó sọ ní Boasi.