< 2 Chronicles 16 >

1 In the thirty-sixth year of Asa’s reign, Baasha king of Israel went up against Judah and fortified Ramah to prevent anyone from leaving or entering the territory of Asa king of Judah.
Ní ọdún kẹrìndínlógójì ìjọba Asa, Baaṣa ọba Israẹli gòkè wá sí Juda ó sì kọlu Rama, láti ma bá a jẹ́ kí ẹnikẹ́ni lè jáde tàbí wọlé tọ Asa ọba Juda lọ.
2 So Asa withdrew the silver and gold from the treasuries of the house of the LORD and the royal palace, and he sent it with this message to Ben-hadad king of Aram, who was ruling in Damascus:
Nígbà náà ni Asa mú wúrà àti fàdákà jáde nínú ilé ìṣúra ilé Olúwa àti ààfin ọba ó sì ránṣẹ́ sí Beni-Hadadi ọba Siria, ẹni tí ń gbé ní Damasku, ó wí pé,
3 “Let there be a treaty between me and you, between my father and your father. See, I have sent you silver and gold. Now go and break your treaty with Baasha king of Israel, so that he will withdraw from me.”
“Májẹ̀mú kan wà láàrín èmi àti ìrẹ, bí ó ti wà láàrín baba mi àti baba rẹ. Ẹ wò ó, mo fi wúrà àti fàdákà ránṣẹ́ sí ọ; lọ, ba májẹ̀mú tí o bá Baaṣa ọba Israẹli dá jẹ́, kí ó lè lọ kúrò ní ọ̀dọ̀ mi.”
4 And Ben-hadad listened to King Asa and sent the commanders of his armies against the cities of Israel, conquering Ijon, Dan, Abel-maim, and all the store cities of Naphtali.
Beni-Hadadi sì gbọ́ ti Asa ọba, ó sì rán àwọn olórí ogun rẹ̀ lọ sí àwọn ìlú Israẹli, wọ́n sì kọlu Ijoni, Dani, Abeli-Maimu, àti gbogbo ìlú ìṣúra Naftali.
5 When Baasha learned of this, he stopped fortifying Ramah and abandoned his work.
Nígbà tí Baaṣa gbọ́ èyí, ó sì dá kíkọ́ Rama dúró, ó sì dá iṣẹ́ rẹ̀ dúró.
6 Then King Asa brought all the men of Judah, and they carried away the stones of Ramah and the timbers Baasha had used for building. And with these materials he built up Geba and Mizpah.
Nígbà náà ní ọba Asa kó gbogbo àwọn ènìyàn Juda jọ, wọ́n sì kó òkúta àti igi Rama lọ èyí ti Baaṣa ń fi kọ́lé; ó sì fi kọ́ Geba àti Mispa.
7 At that time Hanani the seer came to King Asa of Judah and told him, “Because you have relied on the king of Aram and not on the LORD your God, the army of the king of Aram has escaped from your hand.
Ní àkókò náà wòlíì Hanani wá sí ọ̀dọ̀ Asa ọba Juda, ó sì wí fún un pé, “Nítorí tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé ọba Siria, ìwọ kò sì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run rẹ, nítorí náà ni ogún ọba Siria ṣe bọ́ kúrò lọ́wọ́ rẹ.
8 Were not the Cushites and Libyans a vast army with many chariots and horsemen? Yet because you relied on the LORD, He delivered them into your hand.
Àwa kì í ṣe ará Etiopia àti àwọn ará Libia àwọn alágbára ogun pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ kẹ̀kẹ́ àti àwọn ẹlẹ́ṣin? Síbẹ̀ nígbà tí ìwọ bá gbẹ́kẹ̀lé Olúwa yóò sì fi wọ́n lé ọwọ́ rẹ.
9 For the eyes of the LORD roam to and fro over all the earth, to show Himself strong on behalf of those whose hearts are fully devoted to Him. You have acted foolishly in this matter. From now on, therefore, you will be at war.”
Nítorí ojú Olúwa yí gbogbo ayé ká láti fi agbára fún àwọn ẹni tí ó ní ọkàn pípé sí i. Ìwọ ti ṣe ohun aṣiwèrè, láti ìsinsin yìí lọ, ìwọ yóò wà lójú ogun.”
10 Asa was angry with the seer and became so enraged over this matter that he put the man in prison. And at the same time Asa oppressed some of the people.
Asa sì bínú pẹ̀lú sí wòlíì nítorí èyí, ó sì mú un bínú gidigidi tí ó sì fi mú un sínú túbú. Ní àkókò náà Asa sì ni díẹ̀ nínú àwọn ènìyàn náà lára.
11 Now the rest of the acts of Asa, from beginning to end, are indeed written in the Book of the Kings of Judah and Israel.
Àwọn iṣẹ́ ìjọba Asa, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, ni akọ sínú ìwé ọba Juda àti Israẹli.
12 In the thirty-ninth year of his reign, Asa became diseased in his feet, and his malady became increasingly severe. Yet even in his illness he did not seek the LORD, but only the physicians.
Ní ọdún kọkàndínlógójì ìjọba rẹ̀, Asa sì ṣe àìsàn pẹ̀lú ààrùn nínú ẹsẹ̀ rẹ̀. Bi ó tilẹ̀ jẹ pé ààrùn rẹ̀ lágbára, síbẹ̀ kódà nínú àìsàn rẹ̀ kò wá ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ Olúwa, ṣùgbọ́n lọ́dọ̀ àwọn oníṣègùn nìkan.
13 So in the forty-first year of his reign, Asa died and rested with his fathers.
Nígbà náà tí ó pé ọdún kọ́kànlélógójì rẹ̀, Asa kú, ó sì sùn pẹ̀lú àwọn ìjọba baba rẹ̀,
14 And he was buried in the tomb that he had cut out for himself in the City of David. They laid him on a bier that was full of spices and various blended perfumes; then they made a great fire in his honor.
wọ́n sì sin ín sínú isà òkú tí ó ti gbẹ́ jáde fún ara rẹ̀ ní ìlú Dafidi. Wọ́n sì tẹ sí orí àkéte tí ó fi òórùn dídùn kún, àti onírúurú tùràrí tí a fi ọgbọ́n pèsè, wọ́n sì da iná ńlá nítorí rẹ̀.

< 2 Chronicles 16 >