< 1 Samuel 1 >

1 Now there was a man named Elkanah who was from Ramathaim-zophim in the hill country of Ephraim. He was the son of Jeroham, the son of Elihu, the son of Tohu, the son of Zuph, an Ephraimite.
Ọkùnrin kan wà, láti Ramataimu-Sofimu, láti ìlú olókè Efraimu, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Elkana, ọmọ Jerohamu, ọmọ Elihu, ọmọ Tohu, ọmọ Sufu, ará Efrata.
2 He had two wives, one named Hannah and the other Peninnah. And Peninnah had children, but Hannah had none.
Ó sì ní ìyàwó méjì, orúkọ wọn ni Hana àti Penina: Penina ní ọmọ, ṣùgbọ́n Hana kò ní.
3 Year after year Elkanah would go up from his city to worship and sacrifice to the LORD of Hosts at Shiloh, where Eli’s two sons, Hophni and Phinehas, were priests to the LORD.
Ní ọdọọdún, ọkùnrin yìí máa ń gòkè láti ìlú rẹ̀ láti lọ sìn àti láti ṣe ìrúbọ sí Olúwa àwọn ọmọ-ogun jùlọ ní Ṣilo, níbi tí àwọn ọmọkùnrin Eli méjèèjì, Hofini àti Finehasi ti jẹ́ àlùfáà Olúwa.
4 And whenever the day came for Elkanah to present his sacrifice, he would give portions to his wife Peninnah and to all her sons and daughters.
Nígbàkígbà tí ó bá kan Elkana láti ṣe ìrúbọ, òun yóò bù lára ẹran fún aya rẹ̀ Penina àti fún gbogbo àwọn ọmọ ọkùnrin àti obìnrin.
5 But to Hannah he would give a double portion, for he loved her even though the LORD had closed her womb.
Ṣùgbọ́n ó máa ń pín ìlọ́po fun Hana nítorí pé ó fẹ́ràn rẹ̀ àti pé Olúwa ti sé e nínú.
6 Because the LORD had closed Hannah’s womb, her rival would provoke her and taunt her viciously.
Nítorí pé Olúwa ti sé e nínú, orogún rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní fín níràn láti lè mú kí ó bínú.
7 And this went on year after year. Whenever Hannah went up to the house of the LORD, her rival taunted her until she wept and would not eat.
Eléyìí sì máa ń ṣẹlẹ̀ ní ọdọọdún. Nígbàkígbà tí Hana bá gòkè lọ sí ilé Olúwa, orogún rẹ̀ a máa fín níràn títí tí yóò fi máa sọkún tí kò sì ní lè jẹun.
8 “Hannah, why are you crying?” her husband Elkanah asked. “Why won’t you eat? Why is your heart so grieved? Am I not better to you than ten sons?”
Elkana ọkọ rẹ̀ yóò sọ fún un pé, “Hana èéṣe tí ìwọ fi ń sọkún? Èéṣe tí ìwọ kò fi jẹun? Èéṣe tí ìwọ fi ń ba ọkàn jẹ́? Èmi kò ha ju ọmọ mẹ́wàá lọ fún ọ bí?”
9 So after they had finished eating and drinking in Shiloh, Hannah stood up. Now Eli the priest was sitting on a chair by the doorpost of the temple of the LORD.
Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti jẹ, tí wọ́n tún mu tán ní Ṣilo, Hana dìde wá síwájú Olúwa. Nígbà náà, Eli àlùfáà wà lórí àga ní ẹ̀gbẹ́ ẹnu-ọ̀nà ilé Olúwa ní ibi tí ó máa ń jókòó.
10 In her bitter distress, Hannah prayed to the LORD and wept with many tears.
Pẹ̀lú ẹ̀dùn ọkàn Hana sọkún gidigidi, ó sì gbàdúrà sí Olúwa.
11 And she made a vow, pleading, “O LORD of Hosts, if only You will look upon the affliction of Your maidservant and remember me, not forgetting Your maidservant but giving her a son, then I will dedicate him to the LORD all the days of his life, and no razor shall ever come over his head.”
Ó sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ wí pé, “Olúwa àwọn ọmọ-ogun, jùlọ tí ìwọ bá le bojú wo ìránṣẹ́bìnrin rẹ kí ìwọ sì rántí rẹ̀, tí ìwọ kò sì gbàgbé ìránṣẹ́ rẹ ṣùgbọ́n tí ìwọ yóò fún un ní ọmọkùnrin, nígbà náà èmi yóò sì fi fún Olúwa ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ a kì yóò sì fi abẹ kàn án ní orí.”
12 As Hannah kept on praying before the LORD, Eli watched her mouth.
Bí ó sì ṣe ń gbàdúrà sí Olúwa, Eli sì kíyèsi ẹnu rẹ̀.
13 Hannah was praying in her heart, and though her lips were moving, her voice could not be heard. So Eli thought she was drunk
Hana ń gbàdúrà láti inú ọkàn rẹ̀, ṣùgbọ́n ètè rẹ̀ ni ó ń mì, a kò gbọ́ ohùn rẹ̀. Eli rò wí pé ó ti mu ọtí yó.
14 and said to her, “How long will you be drunk? Put away your wine!”
Eli sì wí fún un pé, “Yóò ti pẹ́ fún ọ tó tí ìwọ yóò máa yó? Mú ọtí wáìnì rẹ̀ kúrò.”
15 “No, my lord,” Hannah replied. “I am a woman oppressed in spirit. I have not had any wine or strong drink, but I have poured out my soul before the LORD.
Hana dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, Olúwa mi, èmi ni obìnrin oníròbìnújẹ́. Èmi kò mu ọtí wáìnì tàbí ọtí líle; èmi ń tú ọkàn mi jáde sí Olúwa ni.
16 Do not take your servant for a wicked woman; for all this time I have been praying out of the depth of my anguish and grief.”
Má ṣe mú ìránṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí obìnrin búburú. Èmi ti ń gbàdúrà níhìn-ín nínú ìrora ọkàn àti ìbànújẹ́ mi.”
17 “Go in peace,” Eli replied, “and may the God of Israel grant the petition you have asked of Him.”
Eli dáhùn pé, “Máa lọ ní àlàáfíà, kí Ọlọ́run Israẹli fi ohun tí ìwọ ti béèrè ní ọwọ́ rẹ̀ fún ọ.”
18 “May your maidservant find favor with you,” said Hannah. Then she went on her way, and she began eating again, and her face was no longer downcast.
Ó wí pé, “Kí ìránṣẹ́bìnrin rẹ rí oore-ọ̀fẹ́ lójú rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni obìnrin náà bá tirẹ̀ lọ, ó sì jẹun, kò sì fa ojú ro mọ́.
19 The next morning Elkanah and Hannah got up early to bow in worship before the LORD, and then returned home to Ramah. And Elkanah had relations with his wife Hannah, and the LORD remembered her.
Wọ́n sì dìde ni kùtùkùtù òwúrọ̀, wọn wólẹ̀ sìn níwájú Olúwa, wọn padà wa sí ilé wọn ni Rama: Elkana si mọ Hana aya rẹ̀: Olúwa sì rántí rẹ̀.
20 So in the course of time, Hannah conceived and gave birth to a son. She named him Samuel, saying, “Because I have asked for him from the LORD.”
Ó sì ṣe, nígbà tí ọjọ́ rẹ̀ pé, lẹ́yìn ìgbà tí Hana lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Samuẹli, pé, “Nítorí tí mo béèrè rẹ̀ lọ́wọ́ Olúwa.”
21 Then Elkanah and all his house went up to make the annual sacrifice to the LORD and to fulfill his vow,
Ọkùnrin náà Elkana, àti gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀, gòkè lọ láti rú ẹbọ ọdún sí Olúwa, àti láti sán ẹ̀jẹ́ rẹ̀.
22 but Hannah did not go. “After the boy is weaned,” she said to her husband, “I will take him to appear before the LORD and to stay there permanently.”
Ṣùgbọ́n Hana kò gòkè lọ; nítorí tí ó sọ fún ọkọ rẹ̀ pé, “Ó di ìgbà tí mo bá gba ọmú lẹ́nu ọmọ náà, nígbà náà ni èmi yóò mú un lọ, kí òun lè fi ara hàn níwájú Olúwa, kí ó sí máa gbé ibẹ̀ títí láé.”
23 “Do what you think is best,” her husband Elkanah replied, “and stay here until you have weaned him. Only may the LORD confirm His word.” So Hannah stayed and nursed her son until she had weaned him.
Elkana ọkọ rẹ̀ sì wí fún un pé, “Ṣe èyí tí ó tọ́ lójú rẹ. Dúró títí ìwọ yóò fi gba ọmú lẹ́nu rẹ̀; ṣùgbọ́n kí Olúwa sá à mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni obìnrin náà sì jókòó, ó sì fi ọmú fún ọmọ rẹ̀ títí ó fi gbà á lẹ́nu rẹ̀.
24 Once she had weaned him, Hannah took the boy with her, along with a three-year-old bull, an ephah of flour, and a skin of wine. Though the boy was still young, she brought him to the house of the LORD at Shiloh.
Nígbà tí ó sì gba ọmú lẹ́nu rẹ̀, ó sì mú un gòkè lọ pẹ̀lú ara rẹ̀. Pẹ̀lú ẹgbọrọ màlúù mẹ́ta, àti ìyẹ̀fun efa kan, àti ìgò ọtí wáìnì kan, ó sì mú un wá sí ilé Olúwa ní Ṣilo: ọmọ náà sì wà ní ọmọdé.
25 And when they had slaughtered the bull, they brought the boy to Eli.
Wọ́n pa ẹgbọrọ màlúù, wọ́n sì mú ọmọ náà tọ Eli wá.
26 “Please, my lord,” said Hannah, “as surely as you live, my lord, I am the woman who stood here beside you praying to the LORD.
Hana sì wí pé, “Olúwa mi, bí ọkàn rẹ ti wà láààyè, Olúwa mi, èmi ni obìnrin náà tí ó dúró lẹ́bàá ọ̀dọ̀ rẹ níhìn-ín tí ń tọrọ lọ́dọ̀ Olúwa.
27 I prayed for this boy, and since the LORD has granted me what I asked of Him,
Ọmọ yìí ni mo ń tọrọ; Olúwa sì fi ìdáhùn ìbéèrè tí mo béèrè lọ́dọ̀ rẹ̀ fún mi.
28 I now dedicate the boy to the LORD. For as long as he lives, he is dedicated to the LORD.” So they worshiped the LORD there.
Nítorí náà pẹ̀lú, èmi fi í fún Olúwa; ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀: nítorí tí mo ti béèrè rẹ̀ fún Olúwa.” Wọn si wólẹ̀ sin Olúwa níbẹ̀.

< 1 Samuel 1 >