< 1 Samuel 27 >

1 David, however, said to himself, “One of these days now I will be swept away by the hand of Saul. There is nothing better for me than to escape to the land of the Philistines. Then Saul will stop searching for me all over Israel, and I will slip out of his hand.”
Dafidi sì wí ní ọkàn ara rẹ̀ pé, “Ǹjẹ́ ni ìjọ kan ni èmi yóò ti ọwọ́ Saulu ṣègbé, kò sì sí ohun tí ó yẹ mí jù kí èmi yára sá àsálà lọ sórí ilẹ̀ àwọn Filistini, yóò sú Saulu láti máa tún wa mi kiri ní gbogbo agbègbè Israẹli, èmi a sì bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀.”
2 So David set out with his six hundred men and went to Achish son of Maoch, the king of Gath.
Dafidi sì dìde, ó sì rékọjá, òun pẹ̀lú ẹgbẹ̀ta ọmọkùnrin tí o ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ sí Akiṣi, ọmọ Maoki, ọba Gati.
3 David and his men settled in Gath with Achish. Each man had his family with him, and David had his two wives: Ahinoam of Jezreel and Abigail of Carmel, the widow of Nabal.
Dafidi sì bá Akiṣi jókòó ní Gati, òun, àti àwọn ọmọkùnrin rẹ, olúkúlùkù wọn pẹ̀lú ará ilé rẹ̀; Dafidi pẹ̀lú àwọn aya rẹ̀ méjèèjì, Ahinoamu ará Jesreeli, àti Abigaili ará Karmeli aya Nabali.
4 And when Saul learned that David had fled to Gath, he no longer searched for him.
A sì sọ fún Saulu pé, Dafidi sálọ si Gati, òun kò sì tún wá á kiri mọ́.
5 Then David said to Achish, “If I have found favor in your eyes, let me be assigned a place in one of the outlying towns, so I can live there. For why should your servant live in the royal city with you?”
Dafidi sì wí fún Akiṣi pé, “Bí ó bá jẹ́ pé èmi rí oore-ọ̀fẹ́ lójú rẹ̀, jẹ́ kí wọn ó fún mi ní ibìkan nínú àwọn ìletò wọ̀nyí; èmi yóò máa gbé ibẹ̀, èéṣe tí ìránṣẹ́ rẹ yóò sì máa bá ọ gbé ní ìlú ọba.”
6 That day Achish gave him Ziklag, and to this day it still belongs to the kings of Judah.
Akiṣi sí fi Siklagi fún un ní ọjọ́ náà nítorí náà ni Siklagi fi dí ọba Juda títí ó fi dì òní yìí.
7 And the time that David lived in Philistine territory amounted to a year and four months.
Iye ọjọ́ tí Dafidi fi jókòó ní ìlú àwọn Filistini sì jẹ́ ọdún kan àti oṣù mẹ́rin.
8 Now David and his men went up and raided the Geshurites, the Girzites, and the Amalekites. (From ancient times these people had inhabited the land extending to Shur and Egypt.)
Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì gòkè lọ, wọ́n sì gbé ogun ti àwọn ará Geṣuri, àti àwọn ará Gesri, àti àwọn ará Amaleki àwọn wọ̀nyí ni ó sì tí ń gbé ní ilẹ̀ náà, láti ìgbà àtijọ́, bí ó ti fẹ̀ lọ sí Ṣuri títí ó fi dé ilẹ̀ Ejibiti.
9 Whenever David attacked a territory, he did not leave a man or woman alive, but he took the flocks and herds, the donkeys, camels, and clothing. Then he would return to Achish,
Dafidi sì kọlu ilẹ̀ náà kò sì fi ọkùnrin tàbí obìnrin sílẹ̀ láààyè, ó sì kó àgùntàn, àti màlúù, àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àti ìbákasẹ, àti aṣọ, ó sì yípadà ó tọ Akiṣi wá.
10 who would ask him, “What have you raided today?” And David would reply, “The Negev of Judah,” or “The Negev of Jerahmeel,” or “The Negev of the Kenites.”
Akiṣi sì bi í pé, “Níbo ni ẹ̀yin gbé rìn sí lónìí?” Dafidi sì dáhùn pé, “Sí ìhà gúúsù ti Juda ni, tàbí sí ìhà gúúsù ti Jerahmeeli,” tàbí “Sí ìhà gúúsù ti àwọn ará Keni.”
11 David did not leave a man or woman alive to be brought to Gath, for he said, “Otherwise they will report us, saying, ‘This is what David did.’” And this was David’s custom the whole time he lived in Philistine territory.
Dafidi kò sì dá ọkùnrin tàbí obìnrin sí láààyè, láti mú ìròyìn wá sí Gati, wí pé, “Ki wọn máa bá à sọ ọ̀rọ̀ wa níbẹ̀, pé, ‘Báyìí ni Dafidi ṣe,’” àti bẹ́ẹ̀ ni ìṣe rẹ̀, yóò sì rí ni gbogbo ọjọ́ ti yóò fi jókòó ni ìlú àwọn Filistini.
12 So Achish trusted David, thinking, “Since he has made himself an utter stench to his people Israel, he will be my servant forever.”
Akiṣi sì gba ti Dafidi gbọ́, wí pé, “Òun ti mú kí Israẹli àti àwọn ènìyàn rẹ̀ kórìíra rẹ̀ pátápátá, yóò si jẹ́ ìránṣẹ́ mi títí láé.”

< 1 Samuel 27 >