< Psalms 77 >
1 For the Chief Musician. To Jeduthun. A Psalm by Asaph. My cry goes to God! Indeed, I cry to God for help, and for him to listen to me.
Fún adarí orin. Fún Jedutuni. Ti Asafu. Saamu. Mó kígbe sí Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́; mo kígbe sí Ọlọ́run láti gbọ́ tèmi.
2 In the day of my trouble I sought the Lord. My hand was stretched out in the night, and did not get tired. My soul refused to be comforted.
Nígbà tí mo wà nínú ìpọ́njú, mo wá Olúwa; ní òru ni mo na ọwọ́ mi jáde ní àìkáárẹ̀ ọkàn mí sì kọ̀ láti tù ú nínú.
3 I remember God, and I groan. I complain, and my spirit is overwhelmed. (Selah)
Èmi rántí rẹ, Ọlọ́run, mo sì kẹ́dùn; mo ṣe àròyé, ẹ̀mí mi sì rẹ̀wẹ̀sì. (Sela)
4 You hold my eyelids open. I am so troubled that I cannot speak.
Ìwọ kò fẹ́ kí èmi fi ojú ba oorun, mo dààmú tó bẹ́ẹ̀ tí ń kò le sọ̀rọ̀.
5 I have considered the days of old, the years of ancient times.
Mo ronú nípa ọjọ́ ìgbàanì; ọdún pípẹ́ sẹ́yìn;
6 I remember my song in the night. I consider in my own heart; my spirit diligently inquires:
mo rántí orin mi ní òru. Èmi ń bá àyà mi sọ̀rọ̀, ọkàn mi sì ń ṣe àwárí jọjọ.
7 “Will the Lord reject us forever? Will he be favorable no more?
“Olúwa yóò ha kọ̀ títí láé? Ki yóò ha ṣe ojúrere rẹ̀ mọ́?
8 Has his loving kindness vanished forever? Does his promise fail for generations?
Ṣe ìfẹ́ rẹ̀ àti àánú rẹ̀ ti kú lọ láéláé? Ìlérí rẹ̀ ha kùnà títí ayé?
9 Has God forgotten to be gracious? Has he, in anger, withheld his compassion?” (Selah)
Ọlọ́run ha gbàgbé láti máa ṣàánú? Ní ìbínú rẹ̀, ó ha sé ojúrere rẹ̀ mọ́?” (Sela)
10 Then I thought, “I will appeal to this: the years of the right hand of the Most High.”
Èmi wí pé, “Èyí ní ẹ̀dùn ọkàn mi, pé ọwọ́ ọ̀tún Ọ̀gá-ògo jùlọ ti yípadà”.
11 I will remember the LORD’s deeds; for I will remember your wonders of old.
Èmi ó rántí iṣẹ́ Olúwa: bẹ́ẹ̀ ni, èmi ó rántí iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ọjọ́ pípẹ́.
12 I will also meditate on all your work, and consider your doings.
Èmi ṣàṣàrò lórí iṣẹ́ rẹ gbogbo, pẹ̀lú, ènìyàn sì máa sọ̀rọ̀ gbogbo iṣẹ́ agbára rẹ.
13 Your way, God, is in the sanctuary. What god is great like God?
Ọlọ́run, ọ̀nà rẹ jẹ́ mímọ́. Ọlọ́run wo ni ó sì tóbi bí Ọlọ́run wa?
14 You are the God who does wonders. You have made your strength known among the peoples.
Ìwọ ni Ọlọ́run tó ń ṣe ìyanu; ìwọ fi agbára rẹ hàn nínú àwọn ènìyàn.
15 You have redeemed your people with your arm, the sons of Jacob and Joseph. (Selah)
Pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ ni ìwọ ra àwọn ènìyàn padà, àwọn ọmọ Jakọbu àti Josẹfu. (Sela)
16 The waters saw you, God. The waters saw you, and they writhed. The depths also convulsed.
Nígbà tí àwọn omi rí Ọlọ́run, nígbà tí àwọn omi rí ọ, ẹ̀rù bà wọ́n, nítòótọ́ ara ibú kò balẹ̀.
17 The clouds poured out water. The skies resounded with thunder. Your arrows also flashed around.
Àwọn ojú ọ̀run tú omi sílẹ̀, àwọsánmọ̀ fi àrá dáhùn; ọfà rẹ̀ ń tàn sẹ́yìn àti síwájú.
18 The voice of your thunder was in the whirlwind. The lightnings lit up the world. The earth trembled and shook.
Àrá rẹ̀ ni a gbọ́ nínú ìjì, ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ sí gbogbo ayé; ayé bẹ̀rù, wọ́n sì wárìrì.
19 Your way was through the sea, your paths through the great waters. Your footsteps were not known.
Ipa rẹ̀ gba Òkun, ọ̀nà rẹ̀ ń bẹ nínú Òkun, ọ̀nà la omi alágbára kọjá ipa rẹ̀ ń bẹ nínú líla omi alágbára kọjá, nítòótọ́ a kò rí ojú ẹsẹ̀ rẹ̀.
20 You led your people like a flock, by the hand of Moses and Aaron.
Ó tọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ ẹran nípa ọwọ́ Mose àti Aaroni.