< Johannes 2 >

1 En op den derden dag was er een bruiloft te Kana in Galilea; en de moeder van Jezus was aldaar.
Ní ọjọ́ kẹta, wọn ń ṣe ìgbéyàwó kan ní Kana ti Galili. Ìyá Jesu sì wà níbẹ̀.
2 En Jezus was ook genood, en Zijn discipelen, tot de bruiloft.
A sì pe Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sí ibi ìgbéyàwó náà.
3 En als er wijn ontbrak, zeide de moeder van Jezus tot Hem: Zij hebben geen wijn.
Nígbà tí wáìnì sì tán, ìyá Jesu wí fún un pé, “Wọn kò ní wáìnì mọ́.”
4 Jezus zeide tot haar: Vrouw, wat heb Ik met u te doen? Mijn ure is nog niet gekomen.
Jesu fèsì pé, “Arábìnrin ọ̀wọ́n, èéṣe tí ọ̀rọ̀ yìí fi kàn mí? Àkókò mi kò tí ì dé.”
5 Zijn moeder zeide tot de dienaars: Zo wat Hij ulieden zal zeggen, doet dat.
Ìyá rẹ̀ wí fún àwọn ìránṣẹ́ náà pé, “Ẹ ṣe ohunkóhun tí ó bá wí fún yín.”
6 En aldaar waren zes stenen watervaten gesteld, naar de reiniging der Joden, elk houdende twee of drie metreten.
Ìkòkò òkúta omi mẹ́fà ni a sì gbé kalẹ̀ níbẹ̀, irú èyí tí àwọn Júù máa ń fi ṣe ìwẹ̀nù, èyí tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn gbà tó ìwọ̀n ogún sí ọgbọ̀n jálá.
7 Jezus zeide tot hen: Vult de watervaten met water. En zij vulden ze tot boven toe.
Jesu wí fún àwọn ìránṣẹ́ náà pé, “Ẹ pọn omi kún ìkòkò wọ̀nyí.” Wọ́n sì pọn omi kún wọn títí dé etí.
8 En Hij zeide tot hen: Schept nu, en draagt het tot den hofmeester; en zij droegen het.
Lẹ́yìn náà ni ó wí fún wọn pé, “Ẹ bù jáde lára rẹ̀ kí ẹ sì gbé e tọ alábojútó àsè lọ.” Wọ́n sì gbé e lọ;
9 Als nu de hofmeester het water, dat wijn geworden was, geproefd had (en hij wist niet, van waar de wijn was; maar de dienaren, die het water geschept hadden, wisten het), zo riep de hofmeester den bruidegom.
alábojútó àsè náà tọ́ omi tí a sọ di wáìnì wò. Òun kò sì mọ ibi tí ó ti wá, ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ tí ó bu omi náà wá mọ̀. Alábojútó àsè sì pe ọkọ ìyàwó sí apá kan,
10 En zeide tot hem: Alle man zet eerst den goeden wijn op, en wanneer men wel gedronken heeft, alsdan den minderen; maar gij hebt den goeden wijn tot nu toe bewaard.
Ó sì wí fún un pé, “Olúkúlùkù a máa kọ́kọ́ gbé wáìnì tí ó dára jùlọ kalẹ̀; nígbà tí àwọn ènìyàn bá sì mu ún yó tan, nígbà náà ní wọn a mú èyí tí kò dára tó bẹ́ẹ̀ wá; ṣùgbọ́n ìwọ ti pa wáìnì dáradára yìí mọ́ títí ó fi di ìsinsin yìí.”
11 Dit beginsel der tekenen heeft Jezus gedaan te Kana in Galilea, en heeft Zijn heerlijkheid geopenbaard; en Zijn discipelen geloofden in Hem.
Èyí jẹ́ àkọ́ṣe iṣẹ́ àmì, tí Jesu ṣe ní Kana ti Galili. Ó sì fi ògo rẹ̀ hàn; àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì gbà á gbọ́.
12 Daarna ging Hij af naar Kapernaum, Hij, en Zijn moeder, en Zijn broeders, en Zijn discipelen; en zij bleven aldaar niet vele dagen.
Lẹ́yìn èyí, ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí Kapernaumu, Òun àti ìyá rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀, àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, wọ́n sì gbé ibẹ̀ ní ọjọ́ pípẹ́.
13 En het pascha der Joden was nabij, en Jezus ging op naar Jeruzalem.
Àjọ ìrékọjá àwọn Júù sì súnmọ́ etílé, Jesu sì gòkè lọ sí Jerusalẹmu,
14 En Hij vond in den tempel, die ossen, en schapen, en duiven verkochten, en de wisselaars daar zittende.
Ó sì rí àwọn tí n ta màlúù, àti àgùntàn, àti àdàbà, àti àwọn onípàṣípàrọ̀ owó nínú tẹmpili wọ́n jókòó:
15 En een gesel van touwtjes gemaakt hebbende, dreef Hij ze allen uit den tempel, ook de schapen en de ossen; en het geld der wisselaren stortte Hij uit, en keerde de tafelen om.
Ó sì fi okùn tẹ́ẹ́rẹ́ ṣe pàṣán, ó sì lé gbogbo wọn jáde kúrò nínú tẹmpili, àti àgùntàn àti màlúù; ó sì da owó àwọn onípàṣípàrọ̀ owó nù, ó si ti tábìlì wọn ṣubú.
16 En Hij zeide tot degenen, die de duiven verkochten: Neemt deze dingen van hier weg; maakt niet het huis Mijns Vaders tot een huis van koophandel.
Ó sì wí fún àwọn tí ń ta àdàbà pé, “Ẹ gbé nǹkan wọ̀nyí kúrò níhìn-ín; ẹ má ṣe sọ ilé Baba mi di ilé ọjà títà.”
17 En Zijn discipelen werden indachtig, dat er geschreven is: De ijver van Uw huis heeft mij verslonden.
Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì rántí pé, a ti kọ ọ́ pé, “Ìtara ilé rẹ jẹ mí run.”
18 De Joden antwoordden dan, en zeiden tot Hem: Wat teken toont Gij ons, dat Gij deze dingen doet?
Nígbà náà ní àwọn Júù dáhùn, wọ́n sì bi í pé, “Àmì wo ni ìwọ lè fihàn wá, tí ìwọ fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí?”
19 Jezus antwoordde en zeide tot hen: Breekt dezen tempel, en in drie dagen zal Ik denzelven oprichten.
Jesu dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ wó tẹmpili yìí palẹ̀, Èmi ó sì tún un kọ ní ọjọ́ mẹ́ta.”
20 De Joden zeiden dan: Zes en veertig jaren is over dezen tempel gebouwd, en Gij, zult Gij dien in drie dagen oprichten?
Nígbà náà ní àwọn Júù wí pé, “Ọdún mẹ́rìndínláàádọ́ta ni a fi kọ́ tẹmpili yìí, ìwọ ó ha sì tún un kọ ní ọjọ́ mẹ́ta?”
21 Maar Hij zeide dit van den tempel Zijns lichaams.
Ṣùgbọ́n òun ń sọ ti tẹmpili ara rẹ̀.
22 Daarom, als Hij opgestaan was van de doden, werden Zijn discipelen gedachtig, dat Hij dit tot hen gezegd had, en zij geloofden de Schrift, en het woord, dat Jezus gesproken had.
Nítorí náà nígbà tí ó jíǹde kúrò nínú òkú, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ rántí pé, ó ti sọ èyí fún wọn, wọ́n sì gba Ìwé Mímọ́, àti ọ̀rọ̀ tí Jesu ti sọ gbọ́.
23 En als Hij te Jeruzalem was, op het pascha, in het feest, geloofden velen in Zijn Naam, ziende Zijn tekenen, die Hij deed.
Nígbà tí ó sì wà ní Jerusalẹmu, ní àjọ ìrékọjá, lákokò àjọ náà, ọ̀pọ̀ ènìyàn gba orúkọ rẹ̀ gbọ́ nígbà tí wọ́n rí iṣẹ́ àmì tí ó ṣe.
24 Maar Jezus Zelf betrouwde hun Zichzelven niet, omdat Hij hen allen kende,
Ṣùgbọ́n Jesu kò gbé ara lé wọn, nítorí tí ó mọ gbogbo ènìyàn.
25 En omdat Hij niet van node had, dat iemand getuigen zou van den mens; want Hij Zelf wist, wat in den mens was.
Òun kò sì nílò ẹ̀rí nípa ènìyàn, nítorí tí o mọ̀ ohun tí ń bẹ nínú ènìyàn.

< Johannes 2 >