< Ordsprogene 3 >
1 Min Søn, glem ikke, hvad jeg har lært dig, dit hjerte tage vare på mine bud!
Ọmọ mi, má ṣe gbàgbé ẹ̀kọ́ mi. Ṣùgbọ́n pa òfin mi mọ́ sí ọkàn rẹ.
2 Thi en Række af Dage og Leveår og Lykke bringer de dig.
Nítorí ọjọ́ gígùn, ẹ̀mí gígùn, àti àlàáfíà, ni wọn yóò fi kùn un fún ọ.
3 Godhed og Troskab vige ej fra dig, bind dem som Bånd om din Hals, skriv dem på dit Hjertes Tavle!
Má ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ àti òtítọ́ ṣíṣe fi ọ́ sílẹ̀ láéláé so wọ́n mọ́ ọrùn rẹ, kọ wọ́n sí wàláà àyà rẹ.
4 Så finder du Nåde og Yndest i Guds og Menneskers Øjne.
Nígbà náà ni ìwọ yóò rí ojúrere àti orúkọ rere ní ojú Ọlọ́run àti lójú ènìyàn.
5 Stol på HERREN af hele dit Hjerfe, men forlad dig ikke på din Forstand;
Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ má ṣe sinmi lé òye ara à rẹ.
6 hav ham i Tanke på alle dine Veje, så jævner han dine Stier.
Mọ̀ ọ́n ní gbogbo ọ̀nà rẹ òun yóò sì máa tọ́ ipa ọ̀nà rẹ.
7 Hold ikke dig selv for viis, frygt HERREN og vig fra det onde;
Má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara à rẹ bẹ̀rù Olúwa kí o sì kórìíra ibi.
8 så får du Helse for Legemet, Lindring for dine Ledemod.
Èyí yóò mú ìlera fún ara rẹ àti okun fún àwọn egungun rẹ.
9 Ær med din Velstand HERREN med Førstegrøden af al din Avl;
Fi ọrọ̀ rẹ bọ̀wọ̀ fún Olúwa, pẹ̀lú àkọ́so oko rẹ,
10 da fyldes dine Lader med Korn, dine Perser svømmer over af Most.
nígbà náà ni àká rẹ yóò kún àkúnya àgbá rẹ yóò kún àkúnwọ́sílẹ̀ fún wáìnì tuntun.
11 Min Søn, lad ej hånt om HERRENs Tugt, vær ikke ked af hans Revselse;
Ọmọ mi, má ṣe kẹ́gàn ìbáwí Olúwa má sì ṣe bínú nígbà tí ó bá ń bá ọ wí,
12 HERREN revser den, han elsker, han straffer den Søn, han har kær.
nítorí Olúwa a máa bá àwọn tí ó fẹ́ràn wí bí baba ti í bá ọmọ tí ó bá nínú dídùn sí wí.
13 Lykkelig den, der har opnået Visdom, den, der vinder sig Indsigt;
Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ní ìmọ̀, ẹni tí ó tún ní òye sí i,
14 thi den er bedre at købe end Sølv, bedre at vinde end Guld;
nítorí ó ṣe èrè ju fàdákà lọ ó sì ní èrè lórí ju wúrà lọ.
15 den er mere værd end Perler, ingen Klenodier opvejer den;
Ó ṣe iyebíye ju iyùn lọ; kò sí ohunkóhun tí a lè fiwé e nínú ohun gbogbo tí ìwọ fẹ́.
16 en Række af Dage er i dens højre, i dens venstre Rigdom og Ære;
Ẹ̀mí gígùn ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀; ní ọwọ́ òsì rẹ sì ni ọrọ̀ àti ọlá.
17 dens Veje er liflige Veje, og alle dens Stier er Lykke;
Àwọn ọ̀nà rẹ jẹ́ ọ̀nà ìtura, òpópónà rẹ sì jẹ́ ti àlàáfíà.
18 den er et Livets Træ for dem, der griber den, lykkelig den, som holder den fast!
Igi ìyè ni ó jẹ́ fún gbogbo ẹni tí ó bá gbà á; àwọn tí ó bá sì dìímú yóò rí ìbùkún gbà.
19 HERREN grundlagde Jorden med Visdom, grundfæsted Himlen med Indsigt;
Nípa ọgbọ́n, Olúwa fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé sọlẹ̀; nípa òye, ó fi àwọn ọ̀run sí ipò wọn;
20 ved hans Kundskab brød Strømmene frem, lader Skyerne Dug dryppe ned.
nípa ìmọ̀ rẹ̀ ó pín ibú omi ní yà, àwọsánmọ̀ sì ń sẹ ìrì.
21 Min Søn, tag Vare på Snilde og Kløgt, de slippe dig ikke af Syne;
Ọmọ mi, pa ọgbọ́n tí ó yè kooro àti ìmòye mọ́, má jẹ́ kí wọn lọ kúrò ní ibi tí ojú rẹ ti le tó wọn.
22 så bliver de Liv for din Sjæl og et yndigt Smykke til din Hals.
Wọn yóò jẹ́ ìyè fún ọ, àti ẹ̀ṣọ́ fún ọrùn rẹ.
23 Da vandrer du trygt din Vej, støder ikke imod med din Fod; -
Nígbà náà ni ìwọ yóò bá ọ̀nà rẹ lọ ní àìléwu, ìwọ kì yóò sì kọsẹ̀.
24 sætter du dig, skal du ikke skræmmes, lægger du dig, skal din Søvn vorde sød;
Nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀, ìwọ kì yóò bẹ̀rù, nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀, oorun rẹ yóò jẹ́ oorun ayọ̀.
25 du skal ikke frygte uventet Rædsel, Uvejret, når det kommer over gudløse;
Má ṣe bẹ̀rù ìdààmú òjijì, tàbí ti ìparun tí ó ń dé bá àwọn ènìyàn búburú.
26 thi HERREN skal være din Tillid, han vogter din Fod, så den ikke hildes.
Nítorí Olúwa yóò jẹ́ ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ, kì yóò sì jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ bọ́ sínú pàkúté.
27 Nægt ikke den trængende Hjælp, når det står i din Magt at hjælpe;
Má ṣe fa ọwọ́ ìre sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ àwọn tí ṣe tìrẹ, nígbà tí ó bá wà ní ìkápá rẹ láti ṣe ohun kan.
28 sig ej til din Næste: "Gå og kom igen, jeg vil give i Morgen!" - såfremt du har det.
Má ṣe wí fún aládùúgbò rẹ pé, “Padà wá nígbà tó ṣe díẹ̀; èmi yóò fi fún ọ ní ọ̀la,” nígbà tí o ní i pẹ̀lú rẹ nísinsin yìí.
29 Tænk ikke på ondt mod din Næste, når han tillidsfuldt bor i din Nærhed.
Má ṣe pète ohun búburú fún aládùúgbò rẹ, ti o gbé nítòsí rẹ, tí ó sì fọkàn tán ọ.
30 Yp ikke Trætte med sagesløs Mand, når han ikke har voldet dig Men.
Má ṣe fẹ̀sùn kan ènìyàn láìnídìí, nígbà tí kò ṣe ọ́ ní ibi kankan rárá.
31 Misund ikke en Voldsmand, græm dig aldrig over hans Veje;
Má ṣe ṣe ìlara ènìyàn jàgídíjàgan tàbí kí o yàn láti rìn ní ọ̀nà rẹ̀.
32 thi den falske er HERREN en Gru; mod retsindig er han fortrolig;
Nítorí Olúwa kórìíra ènìyàn aláyídáyidà ṣùgbọ́n a máa fọkàn tán ẹni dídúró ṣinṣin.
33 i den gudløses Hus er HERRENs Forbandelse, men retfærdiges Bolig velsigner han.
Ègún Olúwa ń bẹ lórí ilé ènìyàn búburú, ṣùgbọ́n ó bùkún fún ilé olódodo.
34 Over for Spottere bruger han Spot, men ydmyge giver han Nåde.
Ó fi àwọn ẹlẹ́yà ṣe yẹ̀yẹ́, ṣùgbọ́n ó fi oore-ọ̀fẹ́ fún onírẹ̀lẹ̀.
35 De vise får Ære til Arv, men Tåber høster kun Skam.
Ọlọ́gbọ́n jogún iyì, ṣùgbọ́n àwọn aṣiwèrè ni yóò ru ìtìjú wọn.