< Ordsprogene 13 >
1 Viis Søn elsker tugt, spotter hører ikke på skænd.
Ọlọ́gbọ́n ọmọ gba ẹ̀kọ́ baba rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹlẹ́gàn kò gbọ́ ìbáwí.
2 Af sin Munds Frugt nyder en Mand kun godt, til Vold står troløses Hu.
Láti inú èso ẹnu rẹ̀ ènìyàn ń gbádùn ohun rere, ṣùgbọ́n, ìfẹ́ ọkàn aláìṣòótọ́ ní ìwà ipá.
3 Vogter man Munden, bevarer man Sjælen, den åbenmundede falder i Våde.
Ẹnikẹ́ni tí ó ṣọ́ ẹnu rẹ̀ pa ẹnu ara rẹ̀ mọ́, ṣùgbọ́n ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ gbàù gbàù yóò parun.
4 Den lade attrår uden at få, men flittiges Sjæl bliver mæt.
Ọkàn ọ̀lẹ ń fẹ́, ṣùgbọ́n kò rí nǹkan kan, ṣùgbọ́n ọkàn àwọn ti kì í ṣe ọ̀lẹ rí ìtẹ́lọ́rùn.
5 Den retfærdige hader Løgnetale, den gudløse spreder Skam og Skændsel.
Olódodo kórìíra ohun tí í ṣe irọ́, ṣùgbọ́n ènìyàn búburú hu ìwà ìríra àti ìtìjú.
6 Retfærd skærmer, hvo lydefrit vandrer, Synden fælder de gudløse.
Òdodo ń ṣamọ̀nà ènìyàn olóòtítọ́ inú, ṣùgbọ́n ìwà búburú ṣí ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ipò.
7 Mangen lader rig og ejer dog intet, mangen lader fattig og ejer dog meget.
Ènìyàn kan díbọ́n bí ẹni tí ó ní ọrọ̀ síbẹ̀ kò ní nǹkan kan ẹlòmíràn díbọ́n bí i tálákà, síbẹ̀ ó ní ọrọ̀ púpọ̀.
8 Mands Rigdom er Løsepenge for hans Liv, Fattigmand får ingen Trusel at høre.
Ọrọ̀ ènìyàn le è ra ẹ̀mí rẹ̀ ṣùgbọ́n tálákà kì í gbọ́ ìdẹ́rùbà.
9 Retfærdiges Lys bryder frem, gudløses Lampe går ud.
Ìmọ́lẹ̀ olódodo tàn roro, ṣùgbọ́n fìtílà ènìyàn búburú ni a pa kú.
10 Ved Hovmod vækkes kun Splid, hos dem, der lader sig råde, er Visdom.
Ìgbéraga máa ń dá ìjà sílẹ̀ ni ṣùgbọ́n ọgbọ́n wà nínú àwọn tí ń gba ìmọ̀ràn.
11 Rigdom, vundet i Hast, smuldrer hen, hvad der samles Håndfuld for Håndfuld, øges.
Owó tí a fi ọ̀nà èrú kójọ yóò ṣí lọ, ṣùgbọ́n ẹni tí ń kó owó jọ díẹ̀díẹ̀ yóò pọ̀ sí i.
12 At bie længe gør Hjertet sygt, opfyldt Ønske er et Livets Træ.
Ìrètí tí ń falẹ̀ máa ń mú kí ọkàn ṣàárẹ̀ ṣùgbọ́n ìrètí tí a rí gbà jẹ́ igi ìyè.
13 Den, der lader hånt om Ordet, slås ned, den, der frygter Budet, får Løn.
Ẹni tí ó kẹ́gàn ẹ̀kọ́ yóò jìyà rẹ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ó pa àṣẹ mọ́ gba èrè rẹ̀.
14 Vismands Lære er en Livsens Kilde, derved undgås Dødens Snarer.
Ìkọ́ni ọlọ́gbọ́n jẹ́ orísun ìyè, tí ń yí ènìyàn padà kúrò nínú ìdẹ̀kùn ikú.
15 God Forstand vinder Yndest, troløses Vej er deres Undergang.
Òye pípé ń mú ni rí ojúrere, ṣùgbọ́n ọ̀nà aláìṣòótọ́ kì í tọ́jọ́.
16 Hver, som er klog, går til Værks med Kundskab, Tåben udfolder Dårskab.
Gbogbo olóye ènìyàn máa ń hùwà pẹ̀lú ìmọ̀, ṣùgbọ́n aláìgbọ́n a fi ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ hàn.
17 Gudløs Budbringer går det galt, troværdigt Bud bringer Lægedom.
Ìránṣẹ́ búburú bọ́ sínú ìdààmú ṣùgbọ́n aṣojú olóòtítọ́ mú ìwòsàn wá.
18 Afvises Tugt, får man Armod og Skam; agtes på Revselse, bliver man æret.
Ẹni tí ó kọ ìbáwí yóò di tálákà yóò sì rí ìtìjú, ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí ni yóò rí ọlá.
19 Opfyldt Ønske er sødt for Sjælen, at vige fra ondt er Tåber en Gru.
Ìfẹ́ tí a mú ṣẹ dùn mọ́ ọkàn ṣùgbọ́n ìríra ni fún aṣiwèrè láti kúrò nínú ibi.
20 Omgås Vismænd, så bliver du viis, ilde faren er Tåbers Ven.
Ẹni tí ó ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n ṣùgbọ́n ẹni tí ń bá aláìgbọ́n kẹ́gbẹ́ ń pa ara rẹ̀ lára.
21 Vanheld følger Syndere, Lykken når de retfærdige.
Òsì a máa ta ẹlẹ́ṣẹ̀, ṣùgbọ́n ọrọ̀ ni èrè fún olódodo.
22 Den gode efterlader Børnebrn Arv, til retfærdige gemmes Synderens Gods.
Ènìyàn rere a máa fi ogún sílẹ̀ fún àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀, ṣùgbọ́n, a kó ọrọ̀ àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ pamọ́ fún àwọn olódodo.
23 På Fattigfolks Nyjord er rigelig Føde, mens mangen rives bort ved Uret.
Ilẹ̀ ẹ tálákà le è mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìre oko wá ṣùgbọ́n àìṣòdodo gbá gbogbo rẹ̀ lọ.
24 Hvo Riset sparer, hader sin Søn, den, der elsker ham, tugter i Tide.
Ẹni tí ó fa ọwọ́ ìbáwí sẹ́yìn kórìíra ọmọ rẹ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ó fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ yóò máa bá a wí.
25 Den retfærdige spiser, til Sulten er stillet, gudløses Bug er tom.
Olódodo jẹ́wọ́ títí ó fi tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn ṣùgbọ́n ebi yóò máa pa ikùn ènìyàn búburú.