< 2 Samuel 3 >

1 Krigen imellem Sauls og Davids Huse trak i Langdrag; men David blev stærkere og stærkere, Sauls Hus svagere og svagere.
Ogun náà sì pẹ́ títí láàrín ìdílé Saulu àti ìdílé Dafidi: agbára Dafidi sì ń pọ̀ sí i, ṣùgbọ́n ìdílé Saulu ń rẹ̀yìn sí i.
2 I Hebron fødtes der David Sønner; hans førstefødte var Amnon, Søn af Ahinoam fra Jizre'el,
Dafidi sì bí ọmọkùnrin ní Hebroni: Amnoni ni àkọ́bí rẹ̀ tí Ahinoamu ará Jesreeli bí fún un.
3 den næstældste Kil'ab, Søn af Abigajil, Harmeliten Nabals Hustru, den tredje Absalon, en Søn af Kong Talmaj af Gesjurs Datter Ma'aka,
Èkejì rẹ̀ sì ni Kileabu, tí Abigaili aya Nabali ará Karmeli bí fún un; ẹ̀kẹta sì ni Absalomu ọmọ tí Maaka ọmọbìnrin Talmai ọba Geṣuri bí fún un.
4 den fjerde Adonija, en Søn af Haggit, den femte Sjefatja, en Søn af Abital,
Ẹ̀kẹrin sì ni Adonijah ọmọ Haggiti; àti ẹ̀karùnún ni Ṣefatia ọmọ Abitali;
5 og den sjette Jitream, Søn af Davids Hustru Egla. Disse fødtes David i Hebron.
Ẹ̀kẹfà sì ni Itreamu, tí Egla aya Dafidi bí fún un. Wọ̀nyí ni a bí fún Dafidi ni Hebroni.
6 Under Krigen mellem Sauls og Davids Huse ydede Abner Sauls Hus kraftig Støtte.
Ó sì ṣe, nígbà tí ogun wà láàrín ìdílé Saulu àti ìdílé Dafidi, Abneri sì dì alágbára ní ìdílé Saulu.
7 Nu havde Saul haft en Medhustru ved Navn Rizpa, Ajjas Datter. Og Isjbosjet sagde til Abner: "Hvorfor gik du ind til min Faders Medhustru?"
Saulu ti ní àlè kan, orúkọ rẹ̀ sì ń jẹ́ Rispa, ọmọbìnrin Aiah: Iṣboṣeti sì bi Abneri léèrè pé, “Èéṣe tí ìwọ fi wọlé tọ àlè baba mi lọ.”
8 Abner blev opbragt over Isjbosjets Ord og sagde: "Er jeg nu blevet et Hundehoved fra Juda? Nu har jeg Gang på Gang vist Godhed mod din Fader Sauls Hus, hans Brødre og Venner og ikke ladet dig falde i Davids Hånd, og så går du nu i Rette med mig for en Kvindes Skyld!
Abneri sì bínú gidigidi nítorí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ti Iṣboṣeti sọ fún un, ó sì wí pé, “Èmi jẹ́ bí orí ajá ti Juda bí? Di òní yìí ni mo ṣàánú fún ìdílé Saulu baba rẹ, àti fún àwọn arákùnrin rẹ̀, àti fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, tí èmi kò sì fi ọ́ lé Dafidi lọ́wọ́, ìwọ sì kà ẹ̀ṣẹ̀ sí mí lọ́rùn nítorí obìnrin yìí lónìí?
9 Gud ramme Abner både med det ene og det andet: Hvad HERREN tilsvor David, skal jeg nu sørge for bliver opfyldt på ham;
Bẹ́ẹ̀ ni kí Ọlọ́run ó ṣe Abneri, àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú, bí Olúwa ti búra fún Dafidi, bí èmi kò ní ṣe bẹ́ẹ̀ fún un.
10 jeg skal sørge for, at Sauls Hus mister Kongedømmet og Davids Trone bliver rejst over Israel og Juda fra Dan til Be'ersjeba!"
Láti mú ìjọba náà kúrò ní ìdílé Saulu, àti láti gbé ìtẹ́ Dafidi kalẹ̀ lórí Israẹli, àti lórí Juda, láti Dani títí ó fi dé Beerṣeba.”
11 Og af Frygt for Abner kunde Isjbosjet ikke svare et Ord.
Òun kò sì lè dá Abneri lóhùn kan nítorí tí ó bẹ̀rù rẹ̀.
12 Så sendte Abner Sendebud til David i Hebron og lod sige: "Slut Pagt med mig! Se, jeg vil hjælpe dig og bringe hele Israel over på din Side!"
Abneri sì rán àwọn oníṣẹ́ sí Dafidi nítorí rẹ̀ wí pé, “Ti ta ni ilẹ̀ náà ń ṣe? Bá mi ṣe àdéhùn, èmi yóò si kó gbogbo Israẹli tọ̀ ọ́ wá.”
13 Han svarede: "Vel, jeg vil slutte Pagt med dig; men een Ting kræver jeg af dig: Du bliver ikke stedet for mit Åsyn, med mindre du har Sauls Datter Mikal med, når du kommer!"
Òun sì wí pé, “Ó dára, èmi ó bá ọ ṣe àdéhùn, ṣùgbọ́n ohun kan ni èmi ó béèrè lọ́wọ́ rẹ, èyí ni pé, ìwọ kì yóò rí ojú mi, àfi bí ìwọ bá kọ́ mú Mikali ọmọbìnrin Saulu wá, nígbà tí ìwọ bá wá, láti rí ojú mi.”
14 David sendte derpå Bud til Isjbosjet, Sauls Søn, og lod sige:"Giv mig min Hustru Mikal, som jeg blev trolovet med for 100 Filisterforhuder!"
Dafidi sì rán àwọn ìránṣẹ́ sí Iṣboṣeti ọmọ Saulu pé, “Fi Mikali obìnrin mi lé mi lọ́wọ́, ẹni tí èmi ti fi ọgọ́rùn-ún awọ iwájú orí àwọn Filistini fẹ́.”
15 Da sendte Isjbosjet Bud og lod hende hente hos hendes Mand Paltiel, Lajisj's Søn.
Iṣboṣeti sì ránṣẹ́, ó sì gbà á lọ́wọ́ ọkùnrin tí a ń pè ní Paltieli ọmọ Laiṣi.
16 Hendes Mand fulgte hende grædende lige til Bahurim; her sagde Abner til ham: "Gå nu hjem!" Så vendte han hjem.
Ọkọ rẹ̀ sì ń bà a lọ, ó ń rìn, ó sì ń sọkún lẹ́yìn rẹ̀ títí ó fi dé Bahurimu Abneri sì wí fún un pé, “Padà sẹ́yìn!” Òun sì padà.
17 Men Abner havde forhandlet med Israels Ældste og sagt: "Allerede tidligere ønskede I David til Konge;
Abneri sì bá àwọn àgbàgbà Israẹli sọ̀rọ̀ pé, “Ẹ̀yin ti ń ṣe àfẹ́rí Dafidi ní ìgbà àtijọ́, láti jẹ ọba lórí yín.
18 så gør nu Alvor af det! Thi HERREN har sagt om David: Ved min Tjener Davids Hånd vil jeg frelse mit Folk Israel fra Filisternes og alle dets fjenders Hånd!"
Ǹjẹ́ ẹ ṣe, nítorí tí Olúwa ti sọ fún Dafidi pé, ‘Láti ọwọ́ Dafidi ìránṣẹ́ mi lé mi ó gba Israẹli ènìyàn mi là kúrò lọ́wọ́ àwọn Filistini àti lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá a wọn.’”
19 Abner talte også til Benjamin derom. Endelig gik Abner også til Hebron for at meddele David alt, hvad Israel og hele Benjamins Hus havde vedtaget.
Abneri sì sọ̀rọ̀ létí Benjamini: Abneri sì lọ sọ létí Dafidi ní Hebroni, gbogbo èyí tí ó dára lójú Israẹli, àti lójú gbogbo ilé Benjamini.
20 Da Abner, fulgt af tyve Mænd, kom til David i Hebron, gjorde David Gæstebud for Abner og Mændene, som var med ham.
Abneri sì tọ Dafidi wá ní Hebroni, ogún ọmọkùnrin sì lọ pẹ̀lú rẹ̀ Dafidi sì ṣe àsè fún Abneri àti fún àwọn ọmọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀.
21 Derpå sagde Abner til David: "Lad mig bryde op og drage hen og samle hele Israel om min Herre Kongen, for at de kan slutte Pagt med dig, at du kan blive Konge over alt, hvad din Hu står til!" Da lod David Abner rejse, og han drog bort i Fred.
Abneri sì wí fún Dafidi pé, “Èmi ó dìde, èmi ó sì lọ, èmi ó sì kó gbogbo Israẹli jọ sọ́dọ̀ ọba olúwa mi, wọn ó sì bá a ṣe àdéhùn, ìwọ ó sì jẹ ọba gbogbo wọn bí ọkàn rẹ ti ń fẹ́.” Dafidi sì rán Abneri lọ; òun sì lọ ní àlàáfíà.
22 Just da kom Davids Folk og Joab hjem fra et Strejftog og medførte et rigt Bytte; Abner var da ikke mere hos David i Hebron, thi David havde ladet ham rejse, og han var draget bort i Fred.
Sì wò ó, àwọn ìránṣẹ́ Dafidi àti Joabu sì ti ibi ìlépa ẹgbẹ́ ogun kan bọ̀, wọ́n sì mú ìkógun púpọ̀ bọ̀; ṣùgbọ́n Abneri kò sí lọ́dọ̀ Dafidi ní Hebroni; nítorí tí òun ti rán an lọ, òun sì ti lọ ní àlàáfíà.
23 Da nu Joab var vendt hjem med hele sin Hær, fik han at vide at Abner, Ners Søn, havde været hos Kongen, og at denne havde ladet ham rejse, så han var draget bort i Fred.
Nígbà tí Joabu àti gbogbo ogun tí ó pẹ̀lú rẹ̀ sì dé, wọ́n sì sọ fún Joabu pé Abneri, ọmọ Neri ti tọ ọba wá, òun sì ti rán an lọ, ó sì ti lọ ní àlàáfíà.
24 Da gik Joab til Kongen og sagde: "Hvad har du gjort? Abner har jo været hos dig! Hvorfor lod du ham rejse, så han frit kunde drage bort?
Joabu sì tọ ọba wá, ó sì sọ pé, “Kí ni ìwọ ṣe yìí? Wò ó, Abneri tọ̀ ọ́ wá; èéha ti ṣe tí ìwọ sì fi rán an lọ? Òun sì ti lọ.
25 Indser du ikke, at Abner, Ners Søn, kun kom for at bedrage dig. udspejde din Færd og få at vide, hvad du har for!"
Ìwọ mọ Abneri ọmọ Neri, pé ó wá láti tàn ọ́ jẹ ni, àti láti mọ ìjáde lọ rẹ, àti wíwọlé rẹ́ àti láti mọ gbogbo èyí tí ìwọ ń ṣe.”
26 Så gik Joab bort fra David og sendte uden Davids Vidende Sendebud efter Abner og de hentede ham tilbage fra Bor-Sira.
Nígbà tí Joabu sì jáde kúrò lọ́dọ̀ Dafidi, ó sì rán àwọn ìránṣẹ́ láti lépa Abneri, wọ́n sì pè é padà láti ibi kànga Sira, Dafidi kò sì mọ̀.
27 Og da Abner kom tilbage til Hebron, tog Joab ham til Side midt i Porten for at tale uhindret med ham; og der dræbte han ham ved et Stik i Underlivet for at hævne sin Broder Asa'els Blod.
Abneri sì padà sí Hebroni, Joabu sì bá a tẹ̀ láàrín ojú ọ̀nà láti bá a sọ̀rọ̀ ní àlàáfíà, ó sì gún un níbẹ̀ lábẹ́ inú, ó sì kú, nítorí ẹ̀jẹ̀ Asaheli arákùnrin rẹ̀.
28 Da det siden kom David for Øre, sagde han: "Jeg og mit Rige er til evig Tid uden Skyld for HERREN i Abners, Ners Søns, Blod!
Lẹ́yìn ìgbà tí Dafidi sì gbọ́ ọ, ó sì wí pé, “Èmi àti ìjọba mi sì jẹ́ aláìlẹ́bi níwájú Olúwa títí láé, ní ti ẹ̀jẹ̀ Abneri ọmọ Neri,
29 Det komme over Joabs Hoved og over hele hans Fædrenehus; og Joabs Hus være aldrig frit for Folk, som lider af Flåd eller Spedalsk hed, går med Krykke eller falder for Sværdet eller mangler Brød!"
jẹ́ kí ó wà ní orí Joabu, àti ní orí gbogbo ìdílé baba rẹ̀; kí a má sì fẹ́ ẹni ó tí ní ààrùn ìsun, tàbí adẹ́tẹ̀, tàbí ẹni tí ń tẹ ọ̀pá, tàbí ẹni tí a ó fi idà pa, tàbí ẹni tí ó ṣe aláìní oúnjẹ kù ní ilé Joabu.”
30 Men Joab og hans Broder Abisjaj havde slået Abner ihjel, fordi han havde fældet deres Broder Asa'el i Kampen ved Gibeon.
(Joabu àti Abiṣai arákùnrin rẹ̀ sì pa Abneri, nítorí pé òun ti pa Asaheli arákùnrin wọn ní Gibeoni ní ogun.)
31 Derpå sagde David til Joab og alle Folkene, som fulgte ham: "Sønderriv eders Klæder, tag Sæk om eder og hold Klage over Abner!" Og Kong David gik selv bag efter Båren.
Dafidi sì wí fún Joabu àti fún gbogbo ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ fa aṣọ yín ya, kí ẹ̀yin sì mú aṣọ ọ̀fọ̀, kí ẹ̀yin sì sọkún níwájú Abneri.” Dafidi ọba tìkára rẹ̀ sì tẹ̀lé pósí rẹ̀.
32 Og da man jordede Abner i Hebron, græd Kongen højt ved Abners Grav, og alt Folket græd med,
Wọ́n sì sin Abneri ní Hebroni, ọba sì gbé ohùn rẹ̀ sókè, ó sì sọkún ní ibojì Abneri; gbogbo àwọn ènìyàn náà sì sọkún.
33 Da sang Kongen denne Klagesang over Abner: Skulde Abner dø en Dåres Død?
Ọba sì sọkún lórí Abneri, ó sì wí pé, “Ǹjẹ́ Abneri ó yẹ kí ó kú bí aṣiwèrè?
34 Dine Hænder var ikke bundne, dine Fødder ikke lagt i Lænker, du faldt, som man falder for Misdædere! Da græd hele Folket end mere over ham,
A kò sá à dè ọ́ lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni a kò kan ẹsẹ̀ rẹ ní àbà. Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí ń ṣubú níwájú àwọn ìkà ènìyàn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ ṣubú.” Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì tún sọkún lórí rẹ̀.
35 og da hele Folket kom for at få David til af spise, medens det endnu var Dag, svor David: "Gud ramme mig både med det ene og det andet, om jeg smager Brød eller noget andet, før Sol går ned!"
Nígbà tí gbogbo ènìyàn sì wá láti gba Dafidi ní ìyànjú kí ó jẹun, nígbà tí ọjọ́ sì ń bẹ, Dafidi sì búra wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni kí Ọlọ́run ó ṣe sí mi àti jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí èmi yóò bá tọ́ oúnjẹ wò, tàbí nǹkan mìíràn títí oòrùn yóò fi wọ̀!”
36 Hele Folket lagde Mærke dertil, og det gjorde et godt Indtryk på dem; alt, hvad Kongen foretog sig, gjorde et godt Indtryk på alt Folket;
Gbogbo àwọn ènìyàn sì kíyèsi i, ó sì dára lójú wọn, gbogbo èyí tí ọba ṣe sì dára lójú gbogbo àwọn ènìyàn náà.
37 og hele Folket og hele Israel skønnede den Dag, at Kongen ikke var Ophavsmand til Drabet på Abner, Ners Søn.
Gbogbo àwọn ènìyàn náà àti gbogbo Israẹli sì mọ̀ lọ́jọ́ náà pé, kì í ṣe ìfẹ́ ọba láti pa Abneri ọmọ Neri.
38 Og Kongen sagde til sine Folk: "Ved I ikke, af der i Dag er faldet en Øverste og Stormand i Israel?
Ọba sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin kò mọ̀ pé olórí àti ẹni ńlá kan ni ó ṣubú lónìí ní Israẹli.
39 Men jeg er endnu for svag, skønt jeg er salvet til Konge, og disse Mænd, Zerujasønnerne, er mig for stærke. HERREN gengælde Udådsmanden hans Skændsels- dåd!"
Èmi sì ṣe aláìlágbára lónìí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a fi èmi jẹ ọba; àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ọmọ Seruiah sì le jù mí lọ: Olúwa ni yóò san án fún ẹni tí ó ṣe ibi gẹ́gẹ́ bí ìwà búburú rẹ̀!”

< 2 Samuel 3 >