< 1 Mosebog 43 >
1 Men Hungersnøden var haard i Landet;
Báyìí, ìyàn náà sì mú gidigidi ní ilẹ̀ náà.
2 og da de havde fortæret det Korn, de havde hentet i Ægypten, sagde deres Fader til dem: »Køb os igen lidt Føde!«
Nígbà tí wọ́n sì ti jẹ gbogbo ọkà tí wọ́n rà ní Ejibiti tan, baba wọn wí fún wọn pé, “Ẹ padà lọ ra oúnjẹ díẹ̀ si wá fún wa.”
3 Men Juda svarede ham: »Manden sagde os ganske afgjort: I bliver ikke stedt for mit Aasyn, medmindre eders Broder er med!
Ṣùgbọ́n Juda wí fún un pé, “Ọkùnrin náà tẹnumọ́ ọn nínú ìkìlọ̀ rẹ̀ fún wa pé, ‘Ẹ̀yin kì yóò rí ojúrere mi mọ́, àyàfi bí arákùnrin yín bá bá a yín wá’.
4 Hvis du derfor vil sende vor Broder med os, vil vi rejse ned og købe dig Føde;
Tí ìwọ yóò bá rán Benjamini arákùnrin wa lọ pẹ̀lú wa, a ó lọ ra oúnjẹ wá fún ọ.
5 men sender du ham ikke med, saa rejser vi ikke derned, thi Manden sagde til os: I bliver ikke stedt for mit Aasyn, medmindre eders Broder er med!«
Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá ni jẹ́ kí ó bá wa lọ, àwa kì yóò lọ, nítorí ọkùnrin náà sọ fún wa pé, ‘Ẹ̀yin kì yóò rí ojúrere mi mọ́ àyàfi bí arákùnrin yín bá bá a yín wá.’”
6 Saa sagde Israel: »Hvorfor handlede I ilde imod mig og fortalte Manden, at I havde en Broder til?«
Israẹli béèrè pé, “Èéṣe tí ẹ fi kó ìdààmú yìí bá mi nípa sísọ fún ọkùnrin náà wí pé ẹ ní arákùnrin mìíràn?”
7 De svarede: »Manden spurgte os nøje ud om os og vor Slægt og sagde: Lever eders Fader endnu? Har I en Broder til? Og vi svarede ham paa hans Spørgsmaal; kunde vi vide, at han vilde sige: Bring eders Broder herned!«
Wọ́n dáhùn pé, “Ọkùnrin náà fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wádìí lọ́wọ́ wa nípa ìdílé wa àti àwa fúnra wa. Ó béèrè pé, ‘Ṣe baba yín ṣì wà láààyè? Ǹjẹ́ ẹ tún ní arákùnrin mìíràn?’ A kàn dáhùn ìbéèrè rẹ̀ ni. Báwo ni a ṣe le mọ̀ pé yóò wí pé, ‘Ẹ mú arákùnrin yín wá’?”
8 Men Juda sagde til sin Fader Israel: »Send dog Drengen med mig, saa vi kan komme af Sted og blive i Live og undgaa Døden, baade vi og du og vore Børn!
Juda sì wí fún Israẹli baba rẹ̀, “Jẹ́ kí ọmọkùnrin náà lọ pẹ̀lú mi, a ó sì lọ ní kíákíá, kí àwa àti ìwọ àti àwọn ọmọ wa le yè, kí a má sì kú.
9 Jeg svarer for ham, af min Haand maa du kræve ham: bringer jeg ham ikke til dig og stiller ham for dit Aasyn, vil jeg være din Skyldner for bestandig;
Èmi fúnra mi yóò ṣe onídùúró fún un, èmi ni kí o gbà pé o fi lé lọ́wọ́. Bí n kò bá sì mú un padà tọ̀ ọ́ wá, jẹ́ kí ẹ̀bi rẹ̀ kí ó jẹ́ tèmi ní gbogbo ọjọ́ ayé mi níwájú rẹ.
10 havde vi nu ikke spildt Tiden, kunde vi have været tilbage to Gange!«
Bí ó bá ṣe pé a kò fi falẹ̀ ni, àwa ìbá ti lọ, à bá sì ti padà ní ìgbà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.”
11 Saa sagde deres Fader Israel til dem: »Kan det ikke være anderledes, gør da i alt Fald saaledes: Tag noget af det bedste, Landet frembringer, med i eders Sække og bring Manden en Gave, lidt Mastiksbalsam, lidt Honning, Tragakantgummi, Cistusharpiks, Pistacienødder og Mandler;
Nígbà náà ni Israẹli baba wọn wí fún wọn, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, èyí ni kí ẹ ṣe, ẹ mú àwọn ohun dáradára ilẹ̀ yìí lọ́wọ́ lọ bí ẹ̀bùn fún ọkùnrin náà—ìkunra díẹ̀, oyin díẹ̀, tùràrí àti òjìá, èso pisitakio àti èso almondi
12 og tag dobbelt saa mange Penge med, saa I bringer de Penge tilbage, som var lagt oven i eders Sække; maaske var det en Fejltagelse;
ìlọ́po owó méjì ni kí ẹ mú lọ́wọ́, nítorí ẹ gbọdọ̀ dá owó tí ẹ bá lẹ́nu àpò yín padà. Bóyá ẹnìkan ló ṣèèṣì fi síbẹ̀.
13 og tag saa eders Broder og drag atter til Manden!
Ẹ mú arákùnrin yín lọ́wọ́ pẹ̀lú ki ẹ sì tọ arákùnrin náà lọ.
14 Gud den Almægtige lade eder finde Barmhjertighed hos Manden, saa han lader eders anden Broder og Benjamin fare — men skal jeg være barnløs, saa lad mig da blive det!«
Kí Ọlọ́run alágbára jẹ́ kí ẹ rí àánú gbà lọ́dọ̀ ọkùnrin náà kí ó ba à le jẹ́ kí arákùnrin yín tí ó wà lọ́hùn ún àti Benjamini padà wá pẹ̀lú yín. Ní tèmi, bí mo bá pàdánù àwọn ọmọ mi, n ó ṣọ̀fọ̀ wọn náà ni.”
15 Saa tog Mændene deres Gave og dobbelt saa mange Penge med; ogsaa Benjamin tog de med, brød op og drog ned til Ægypten, hvor de fremstillede sig for Josef.
Nítorí náà wọ́n mú àwọn ẹ̀bùn náà àti owó ìlọ́po méjì àti Benjamini, wọ́n sì yára lọ sí ilẹ̀ Ejibiti, wọ́n sì fi ara wọn hàn níwájú Josẹfu.
16 Da Josef saa Benjamin iblandt dem, sagde han til sin Hushovmester: »Bring de Mænd ind i mit Hus, lad slagte og lave til, thi de skal spise til Middag hos mig.«
Nígbà tí Josẹfu rí Benjamini pẹ̀lú wọn, ó sọ fún ìránṣẹ́ ilé rẹ̀, “Mú àwọn ọkùnrin wọ̀nyí lọ sí ilé mi, pa ẹran kí o sì ṣe àsè; wọn ó jẹun ọ̀sán pẹ̀lú mi.”
17 Manden gjorde, som Josef bød, og førte Mændene ind i Josefs Hus.
Ọkùnrin náà sì ṣe bí Josẹfu ti wí fún un, ó sì mú àwọn ọkùnrin náà lọ sí ilé Josẹfu.
18 Men Mændene blev bange, da de førtes ind i Josefs Hus, og sagde: »Det er for de Penges Skyld, der forrige Gang kom tilbage i vore Sække, at vi føres herind, for at de kan vælte sig ind paa os og kaste sig over os, gøre os til Trælle og tage vore Æsler.«
Ẹ̀rù sì ba àwọn ọkùnrin náà nígbà tí wọ́n mú wọn lọ sí ilé Josẹfu. Wọ́n rò ó pé, “A mú wa wá sí ìhín nítorí owó tí a fi sí inú àpò wa ní ìgbà àkọ́kọ́. Ó fẹ́ bá wa jà, kí ó mú wa lẹ́rú kí ó sì gba àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wa.”
19 Derfor traadte de hen til Josefs Hushovmester ved Døren til Huset
Nítorí náà wọ́n lọ bá ìránṣẹ́ Josẹfu, wọ́n sì ba sọ̀rọ̀ ní ẹnu-ọ̀nà àbáwọlé ilé náà.
20 og sagde: »Hør os, Herre! Vi drog en Gang før herned for at købe Føde,
Wọ́n wí pé, “Jọ̀wọ́ ọ̀gá, ní òtítọ́ ni àwa ti sọ̀kalẹ̀ síyìn-ín láti wá ra oúnjẹ ní ìṣáájú.
21 og da vi kom til vort Natteherberge og aabnede vore Sække, se, da laa vore Penge oven i hver enkelts Sæk, vore Penge til sidste Hvid. Men nu har vi bragt dem med tilbage
Ṣùgbọ́n níbi tí a ti dúró ní ọ̀nà láti sùn ní alẹ́, nígbà tí a tú àpò oúnjẹ wa, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa bá owó oúnjẹ tirẹ̀ tí ó rà lẹ́nu àpò láì lé, láì dín. Nítorí náà òun nìyí, a ti mu un padà wá pẹ̀lú wa.
22 og desuden andre Penge for at købe Føde. Vi ved ikke, hvem der har lagt Pengene i vore Sække!«
A sì tún mú owó mìíràn lọ́wọ́ láti fi ra oúnjẹ. A ò mọ ẹni tí ó fi owó wa sí ẹnu àpò.”
23 Men han svarede: »Vær ved godt Mod, frygt ikke! Eders Gud og eders Faders Gud har lagt en Skat i eders Sække — eders Penge har jeg modtaget!« Og han førte Simeon ud til dem.
Ó sì wí fún wọn pé, “Àlàáfíà ni fún yín, ẹ má bẹ̀rù, Ọlọ́run yín, àní Ọlọ́run baba yín ni ó fi ìṣúra sí inú àpò yín; mo rí owó tí ẹ san gbà.” Nígbà náà ni ó mú Simeoni jáde tọ̀ wọ́n wá.
24 Saa førte Manden dem ind i Josefs Hus og gav dem Vand til at tvætte deres Fødder og Foder til Æslerne.
Ìránṣẹ́ náà mú àwọn ọkùnrin náà lọ sí ilé Josẹfu, ó fún wọn ní omi láti fi wẹ ẹsẹ̀ wọn nu, ó sì fún àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn lóúnjẹ pẹ̀lú.
25 Og de fremtog deres Gave, før Josef kom hjem ved Middagstid, thi de hørte, at de skulde spise der.
Wọ́n pèsè ẹ̀bùn wọn sílẹ̀ fún Josẹfu di ọ̀sán nígbà tí yóò dé, nítorí wọ́n ti gbọ́ pé ibẹ̀ ni àwọn yóò ti jẹun ọ̀sán.
26 Da Josef traadte ind i Huset, bragte de ham den Gave, de havde med, og kastede sig til Jorden for ham.
Nígbà tí Josẹfu dé sí ilé, wọ́n kó àwọn ẹ̀bùn tí wọ́n ti mú wá fún un, wọ́n sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀.
27 Han hilste paa dem og spurgte: »Gaar det eders gamle Fader vel, ham, I talte om? Lever han endnu?«
Ó béèrè àlàáfíà wọn, ó sì wí pé, “Ṣé àlàáfíà ni baba yín wà, baba arúgbó tí ẹ sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún mi, ṣé ó sì wà láààyè?”
28 De svarede: »Det gaar din Træl, vor Fader, vel; han lever endnu!« Og de bøjede sig og kastede sig til Jorden.
Wọ́n dáhùn pé, “Ìránṣẹ́ rẹ, baba wa sì wà láààyè, àlàáfíà sì ni ó wà pẹ̀lú.” Wọn sì tẹríba láti bọ̀wọ̀ fún un.
29 Da han saa fik Øje paa sin kødelige Broder Benjamin, sagde han: »Er det saa eders yngste Broder, som I talte til mig om?« Og han sagde: »Gud være dig naadig, min Søn!«
Bí ó ti wò yíká tí ó sì rí Benjamini àbúrò rẹ̀, tí í ṣe ọmọ ìyá rẹ̀ gan an. Ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ṣe àbúrò yín tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn tí ẹ sọ fún mi nípa rẹ̀ nìyìí?” Ó sì tún wí pe, “Kí Ọlọ́run kí ó ṣàánú fún ọ, ọmọ mi.”
30 Men Josef brød hurtigt af, thi Kærligheden til Broderen blussede op i ham, og han kæmpede med Graaden; derfor gik han ind i sit Kammer og græd der.
Ọkàn rẹ̀ sì fà sí i gidigidi nígbà tí ó rí arákùnrin rẹ̀, nítorí náà Josẹfu yára jáde láti wá ibi tí ó ti le sọkún. Ó lọ sí iyàrá rẹ̀, ó sì sọkún níbẹ̀.
31 Men da han havde badet sit Ansigt, kom han ud, og han beherskede sig og sagde: »Sæt Maden frem!«
Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti bọ́jú tan, ó jáde wá, ó ṣe ọkàn ọkùnrin, ó sì wí fún wọn pé, kí wọ́n gbé oúnjẹ wá kí wọ́n le è jẹun.
32 Saa blev Maden sat frem særskilt for ham og for dem og for de Ægyptere, der spiste hos ham; thi Ægypterne kan ikke spise sammen med Hebræere, det er dem en Vederstyggelighed.
Wọ́n gbé oúnjẹ tirẹ̀ fún un lọ́tọ̀, àti fún àwọn ará Ejibiti tí ó wá ba jẹun náà lọ́tọ̀, nítorí ará Ejibiti kò le bá ará Heberu jẹun nítorí ìríra pátápátá ló jẹ́ fún àwọn Ejibiti.
33 De blev bænket foran ham efter Alder, den førstefødte øverst og den yngste nederst, og Mændene undrede sig og saa paa hverandre;
A mú àwọn ọkùnrin náà jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, bí wọ́n ṣe dàgbà sí, láti orí ẹ̀gbọ́n pátápátá dé orí èyí tí ó kéré pátápátá, wọ́n sì ń wo ara wọn tìyanu tìyanu.
34 og han lod dem bringe Mad fra sit eget Bord, og Benjamin fik fem Gange saa meget som hver af de andre. Og de drak og blev lystige sammen med ham.
A sì bu oúnjẹ fún wọn láti orí tábìlì Josẹfu. Oúnjẹ Benjamini sì tó ìlọ́po márùn-ún ti àwọn tókù. Wọ́n ń jẹ, wọ́n sì ń mu lọ́dọ̀ rẹ̀ láìsí ìdíwọ́.