< Første Krønikebog 7 >
1 Issakars Sønner var: Tola, Pua, Jasjub og Sjimron, fire.
Àwọn ọmọ Isakari: Tola, Pua, Jaṣubu àti Ṣimroni, mẹ́rin ni gbogbo rẹ̀.
2 Tolas Sønner: Uzzi, Refaja, Jeriel, Jamaj, Jibsam og Sjemuel, Overhoveder for Tolas Fædrenehuse, dygtige Krigere. Efter deres Slægtebøger udgjorde deres Tal paa Davids Tid 22 600.
Àwọn ọmọ Tola: Ussi, Refaiah, Jehieli, Jamai, Ibsamu àti Samuẹli olórí àwọn ìdílé wọn. Ní àkókò ìjọba, Dafidi, àwọn ìran ọmọ Tola tò lẹ́sẹẹsẹ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọkùnrin alágbára ní ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìlélógún ó lé ẹgbẹ̀ta.
3 Uzzis Sønner: Jizraja, Jizrajas Sønner Mikael, Obadja, Joel og Jissjija, fem, alle sammen Overhoveder.
Àwọn ọmọ, Ussi: Israhiah. Àwọn ọmọ Israhiah: Mikaeli, Obadiah, Joẹli àti Iṣiah. Gbogbo àwọn márààrún sì jẹ́ olóyè.
4 Til dem hørte efter deres Slægtebøger, efter deres Fædrenehuse, krigsrustede Skarer, 36 000; de havde nemlig mange Kvinder og Børn.
Gẹ́gẹ́ bí ìtàn ìdílé wọn láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, wọ́n ní ọkùnrin ẹgbàá mẹ́rìndínlógójì tí ó ti ṣe tan fún ogun, nítorí wọ́n ní ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ àti ìyàwó.
5 Deres Brødre, alle Issakars Slægter, var dygtige Krigere; de, som var indført i deres Slægtebog, udgjorde i alt 87 000.
Àwọn ìbátan tí ó jẹ́ alágbára akọni àwọn ọkùnrin tí ó jẹ́ ti àwọn ìdílé Isakari, bí a ti tò ó lẹ́sẹẹsẹ nínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàdínláàádọ́rin ni gbogbo rẹ̀.
6 Benjamins Sønner: Bela, Beker og Jediael, tre.
Àwọn ọmọ mẹ́ta Benjamini: Bela, Bekeri àti Jediaeli.
7 Belas Sønner: Ezbon, Uzzi, Uzziel Jerimot og Iri, fem, Overhoveder for Fædrenehuse, dygtige Krigere; de, som var indført i deres Slægtebog, udgjorde 22 034.
Àwọn ọmọ Bela: Esboni, Ussi, Usieli, Jerimoti àti Iri, àwọn márààrún. Àwọn ni olórí ilé baba ńlá wọn, akọni alágbára ènìyàn. A sì ka iye wọn nípa ìran wọn sí ẹgbẹ̀rún méjìlélógún ó lé mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n ènìyàn.
8 Bekers Sønner: Zemira, Joasj, Eliezer, Eljoenaj, Omri, Jeremot, Abija, Anatot og Alemet; alle disse var Bekers Sønner;
Àwọn ọmọ Bekeri: Semirahi, Joaṣi, Elieseri, Elioenai, Omri, Jeremoti, Abijah, Anatoti àti Alemeti. Gbogbo wọ̀nyí jẹ́ ọmọ Bekeri.
9 de, som var indført i deres Slægtebog efter deres Slægter, Overhovederne for Fædrenehusene, dygtige Krigere, udgjorde 20 200.
Ìtàn ìdílé wọn láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn tí a kọ lẹ́sẹẹsẹ jẹ́ ti àwọn olórí ìdílé àti ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà ogún ó lé nígba ọkùnrin alágbára.
10 Jediaels Sønner: Bilhan; Bilhans Sønner: Je'usj, Binjamin, Ehud, Kena'ana, Zetan, Tarsjisj og Ahisjahar;
Ọmọ Jediaeli: Bilhani. Àwọn ọmọ Bilhani: Jeuṣi Benjamini, Ehudu, Kenaana, Setamu, Tarṣiṣi àti Ahiṣahari.
11 alle disse var Jediaels Sønner, Overhoveder for deres Fædrenehuse, dygtige Krigere, 17 200 øvede Krigere.
Gbogbo àwọn ọmọ Jediaeli jẹ́ olórí. Àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlógún ó lé nígba akọni ọkùnrin ni ó ti ṣetán láti jáde lọ sí ogun.
12 Og Sjuppim og Huppim var Irs Sønner, og Husjim var Ahers Sønner.
Àti Ṣuppimu, àti Huppimu, àwọn ọmọ Iri, àti Huṣimu, àwọn ọmọ Aheri.
13 Naftalis Sønner var: Jahaziel, Guni, Jezer og Sjallum. Bilhas Sønner: ..... .
Àwọn ọmọ Naftali: Jasieli, Guni, Jeseri àti Ṣallumu—ọmọ rẹ̀ nípa Biliha.
14 Manasses Sønner, som hans aramaiske Medhustru fødte: Hun fødte Makir, Gileads Fader.
Àwọn ìran ọmọ Manase: Asrieli jẹ́ ìran ọmọ rẹ̀ ní ipasẹ̀ àlè rẹ̀ ará Aramu ó bí Makiri baba Gileadi.
15 Gilead ægtede en Kvinde ved Navn Ma'aka; hans Søster hed Hammoleket, og hans Broder hed Zelofhad; Zelofhad havde kun Døtre.
Makiri sì mú ìyàwó láti àárín àwọn ará Huppimu àti Ṣuppimu. Orúkọ arábìnrin rẹ̀ a máa jẹ́ Maaka. Orúkọ ìran ọmọ mìíràn a máa jẹ́ Selofehadi, tí ó ní àwọn ọmọbìnrin nìkan ṣoṣo.
16 Gileads Hustru Ma'aka fødte en Søn, som hun kaldte Peresj, medens hans Broder hed Sjeresj; hans Sønner var Ulam og Rekem.
Maaka, ìyàwó Makiri bí ọmọkùnrin kan. Ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Peresi. Ó sì pe arákùnrin rẹ̀ ní Ṣereṣi, àwọn ọmọ rẹ̀ sì ní Ulamu àti Rakemu.
17 Ulams Sønner: Bedan. Det var Sønner af Gilead, en Søn af Makir, en Søn af Manasse.
Ọmọ Ulamu: Bedani. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Gileadi ọmọ Makiri, ọmọ Manase.
18 Hans Søster Hammoleket fødte Isjhod, Abiezer og Mala.
Arábìnrin rẹ̀. Hamoleketi bí Iṣhodi, Abieseri àti Mahila.
19 Sjemidas Sønner: Ajan, Sjekem, Likhi og Ani'am.
Àwọn ọmọ Ṣemida sì jẹ́: Ahiani, Ṣekemu, Likki àti Aniamu.
20 Efraims Sønner: Sjutela hans Søn Bered, hans Søn Tahat, hans Søn El'ada, hans Søn Tahat,
Àwọn ìran ọmọ Efraimu: Ṣutelahi, Beredi ọmọkùnrin rẹ̀, Tahati ọmọ rẹ̀, Eleadah ọmọ rẹ̀. Tahati ọmọ rẹ̀
21 hans Søn Zabad, hans Søn Sjutela — og Ezer og El'ad. Dem dræbte Mændene fra Gat, de indfødte i Landet, fordi de var draget ned for at tage deres Hjorde.
Sabadi ọmọ, rẹ̀, àti Ṣutelahi ọmọ rẹ̀. Eseri àti Eleadi ni a pa nípasẹ̀ àwọn ọkùnrin bíbí ìbílẹ̀ Gati nígbà tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ láti lọ fi agbára mú ohun ọ̀sìn wọn
22 Deres Fader Efraim sørgede i lang Tid over dem, og hans Brødre kom for at trøste ham.
Efraimu baba wọn ṣọ̀fọ̀ fún wọn ní ọjọ́ púpọ̀, àwọn ìbátan rẹ̀ wá láti tù ú nínú.
23 Saa gik han ind til sin Hustru, og hun blev frugtsommelig og fødte en Søn, som han kaldte Beri'a, fordi hans Hus var i Ulykke, da det skete.
Nígbà náà, ó sùn pẹ̀lú, ìyàwó rẹ̀, ó sì lóyún ó sì bí ọmọkùnrin kan. Ó sì sọ ọ́ ní Beriah nítorí òfò ti wà nínú ìdílé náà.
24 Hans Datter var Sje'era, som byggede Nedre— og Øvre-Bet-Horon og Uzzen-Sje'era.
Ọmọbìnrin rẹ̀ sì jẹ́ Ṣerah, ẹni tí ó kọ́ ìsàlẹ̀ àti òkè Beti-Horoni àti Useni-Ṣerah pẹ̀lú.
25 Hans Søn var Refa, hans Søn Resjef, hans Søn Tela, hans Søn Tahan,
Refa jẹ́ ọmọ rẹ̀, Resefi ọmọ rẹ̀, Tela ọmọ rẹ̀, Tahani ọmọ rẹ̀,
26 hans Søn Ladan, hans Søn Ammihud, hans Søn Elisjama,
Laadani ọmọ rẹ̀ Ammihudu ọmọ rẹ̀, Eliṣama ọmọ rẹ̀,
27 hans Søn Nun, hans Søn Josua.
Nuni ọmọ rẹ̀ àti Joṣua ọmọ rẹ̀.
28 Deres Besiddelser og Boliger var Betel med Smaabyer, mod Øst Na'aran, mod Vest Gezer med Smaabyer, fremdeles Sikem med Smaabyer indtil Ajja med Smaabyer;
Ilẹ̀ wọn àti ìfìdíkalẹ̀ wọn ni Beteli àti àwọn ìletò tí ó yíká, Narani lọ sí ìhà ìlà-oòrùn, Geseri àti àwọn ìletò rẹ̀ lọ sí ìhà ìwọ̀-oòrùn àti Ṣekemu àti àwọn ìletò rẹ̀ ní ọ̀nà lọ sí Ayahi àti àwọn ìletò.
29 langs Manassiternes Grænse Bet-Sjean med Smaabyer, Ta'anak med Smaabyer, Megiddo med Smaabyer og Dor med Smaabyer. I dem boede Israels Søn Josefs Sønner.
Lẹ́gbẹ̀ ìpínlẹ̀ ti Manase ni Beti-Ṣeani, Taanaki, Megido àti Dori lápapọ̀ pẹ̀lú àwọn ìletò rẹ̀. Àwọn ìran ọmọ Josẹfu ọmọ Israẹli ń gbé nínú ìlú wọ̀nyí.
30 Asers Sønner: Jimna, Jisjva, Jisjvi og Beri'a og deres Søster Sera.
Àwọn ọmọ Aṣeri: Imina, Iṣifa, Iṣfi àti Beriah. Arábìnrin wọn sì jẹ́ Sera.
31 Beri'as Sønner: Heber og Malkiel, som var Birzajits Fader.
Àwọn ọmọ Beriah: Heberi àti Malkieli, tí ó jẹ́ baba Barsafiti.
32 Heber avlede Jaflet, Sjomer, Hotam og deres Søster Sjua.
Heberi jẹ́ baba Jafileti, Ṣomeri àti Hotami àti ti arábìnrin wọn Ṣua.
33 Jaflets Sønner: Pasak, Bimhal og Asjvat; det var Jaflets Sønner.
Àwọn ọmọ Jafileti: Pasaki, Bimhali àti Asifati. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Jafileti.
34 Sjemers Sønner: Ahi, Roga, Hubba og Aram.
Àwọn ọmọ Ṣomeri: Ahi, Roga, Jahuba àti Aramu.
35 Hans Broder Hotams Sønner: Zofa, Jimna, Sjelesj og Amal.
Àwọn ọmọ arákùnrin rẹ̀ Helemu Sofahi, Imina, Ṣeleṣi àti Amali.
36 Zofas Sønner: Sua, Harnefer, Sjual, Beri, Jimra,
Àwọn ọmọ Sofahi: Sua, Haniferi, Ṣuali, Beri, Imra.
37 Bezer, Hod, Sjamma, Sjilsja, Jitran og Be'era.
Beseri, Hodi, Ṣamma, Ṣilisa, Itrani àti Bera.
38 Jeters Sønner: Jefunne, Pispa og Ara.
Àwọn ọmọ Jeteri: Jefunne, Pisifa àti Ara.
39 Ullas Sønner: Ara, Hanniel og Rizja.
Àwọn ọmọ Ulla: Arah, Hannieli àti Resia.
40 Alle disse var Asers Sønner. Overhoveder for Fædrenehusene, udsøgte dygtige Krigere, Overhoveder for Øversterne. De, der var indført i Slægtebogen som brugelige til Krigstjeneste, talte 26 000.
Gbogbo wọ̀nyí jẹ́ ìran ọmọ Aṣeri—olórí ìdílé, àṣàyàn ọkùnrin, alágbára jagunjagun àti olórí nínú àwọn ìjòyè. Iye àwọn tí a kà yẹ fún ogun, gẹ́gẹ́ bí à ti ṣe kọ ọ́ lẹ́sẹẹsẹ nínú ìtàn ìdílé wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàlá ọkùnrin.