< Ordsprogene 30 >

1 Agurs, Jakes Søns Ord, det varslende Ord, Udsagnet af Manden, til Ithiel, til Ithiel og Ukal.
Àwọn ọ̀rọ̀ Aguri ọmọ Jake, ọ̀rọ̀ ìsọtẹ́lẹ̀ tí ọkùnrin yìí sọ fún Itieli. Sí Itieli àti sí Ukali.
2 Jeg var ufornuftigere end en Mand, og jeg havde ikke Forstand som et Menneske.
“Èmi ni aláìmòye ju nínú àwọn ènìyàn; n kò ní òye ènìyàn.
3 Og jeg havde ikke lært Visdom eller kendt Kundskab om den Hellige.
Èmi kò tilẹ̀ kọ́ ọgbọ́n tàbí ní ìmọ̀ ẹni mímọ́ nì.
4 Hvo for op til Himmelen og for ned? hvo samlede Vejret i sine Næver? hvo bandt Vandet i et Klædebon? hvo har fastsat alle Jordens Grænser? hvad er hans Navn? og hvad er hans Søns Navn? du ved det jo.
Ta ni ó ti gòkè lọ sí ọ̀run tí ó sì padà sọ̀kalẹ̀? Ta ni ó ti kó afẹ́fẹ́ jọ sí ihò àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀? Ta ni ó ti ta kókó omi sétí aṣọ? Ta ni ó fi gbogbo ìpìlẹ̀ ayé lélẹ̀? Kí ni orúkọ rẹ̀, àti orúkọ ọmọ rẹ̀? Sọ fún mi bí o bá mọ̀.
5 Alt Guds Ord er lutret; han er et Skjold for dem, som forlade sig paa ham.
“Gbogbo ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ aláìlábùkù; òun ni ààbò fún gbogbo ẹni fi í ṣe ibi ìpamọ́ wọn.
6 Læg intet til hans Ord, at han ikke skal straffe dig, og du skal staa som en Løgner.
Má ṣe fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀, àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò bá ọ wí yóò sì sọ ọ́ di òpùrọ́.
7 Om tvende Ting har jeg bedet dig; nægt mig dem ej, før jeg dør:
“Ohun méjì ni mo ń béèrè lọ́wọ́ rẹ, Olúwa; má ṣe fi wọ́n dù mí kí ń tó kú.
8 Lad Forfængelighed og Løgnens Ord være langt fra mig; giv mig ikke Armod eller Rigdom, men tildel mig mit beskikkede Brød;
Mú èké ṣíṣe àti irọ́ jìnnà sí mi; má ṣe fún mi ní òsì tàbí ọrọ̀, ṣùgbọ́n fún mi ní oúnjẹ òòjọ́ mi nìkan.
9 at jeg ikke, naar jeg mættedes, skulde fornægte dig og sige: Hvo er Herren? eller naar jeg blev fattig, skulde stjæle og forgribe mig paa min Guds Navn.
Àìṣe bẹ́ẹ̀, mo lè ní àníjù kí n sì gbàgbé rẹ kí ń sì wí pé, ‘Ta ni Olúwa?’ Tàbí kí ń di òtòṣì kí ń sì jalè kí ń sì ṣe àìbọ̀wọ̀ fún orúkọ Ọlọ́run mi.
10 Bagtal ikke en Træl for hans Herre, at han ikke skal forbande dig, og du skal bære Skyld.
“Má ṣe ba ìránṣẹ́ lórúkọ jẹ́ lọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀, kí ó má ba fi ọ́ bú, kí ìwọ má ba jẹ̀bi.
11 Der er en Slægt, som bander sin Fader og ikke velsigner sin Moder;
“Àwọn kan wá ṣépè fún àwọn baba wọn tí wọn kò sì súre fún àwọn ìyá wọn.
12 der er en Slægt, som er ren i sine egne Øjne, og hvis Skarn dog ikke er aftoet;
Àwọn tí ó mọ́ ní ojú ara wọn síbẹ̀ tí wọn kò sì mọ́ kúrò nínú èérí wọn;
13 der er en Slægt, hvis Øjne ere høje, og hvis Øjenlaage hæve sig i Vejret;
àwọn ẹni tí ojú wọn gbéga nígbà gbogbo, tí ìwolẹ̀ wọn sì kún fún ìgbéraga.
14 der er en Slægt, hvis Tænder ere Sværd, og hvis Kindtænder ere Knive, som vil fortære de elendige i Landet og de fattige iblandt Menneskene.
Àwọn ẹni tí eyín wọn jẹ́ idà àwọn tí èrìgì wọn kún fún ọ̀bẹ láti jẹ àwọn tálákà run kúrò ní ilẹ̀ ayé àwọn aláìní kúrò láàrín àwọn ọmọ ènìyàn.
15 Blodsugersken har to Døtre, „giv hid! giv hid!‟ Der er tre, som ikke kunne mættes, fire, som ikke sige: „Nok!‟
“Eṣúṣú ni ọmọbìnrin méjì. ‘Mú wá! Mú wá!’ ní wọn ń ké. “Àwọn nǹkan mẹ́ta kan wà tí kò ní ìtẹ́lọ́rùn láéláé, mẹ́rin tí kò jẹ́ wí láéláé pé, ‘Ó tó!’:
16 Dødsriget og det ufrugtbare Moderliv; Jorden bliver ikke mæt af Vand, og Ilden siger ikke: „Nok!‟ (Sheol h7585)
Ibojì, inú tí ó yàgàn, ilẹ̀ tí omi kì í tẹ́lọ́rùn láéláé, àti iná, tí kì í wí láéláé pé, ‘Ó tó!’ (Sheol h7585)
17 Et Øje, som spotter Faderen og lader haant om at lyde Moderen, det skulle Ravnene ved Bækken udhugge, og Ørneunger skulle æde det.
“Ojú tí ń fi baba ṣẹ̀fẹ̀, tí ó kẹ́gàn ìgbọ́ràn sí ìyá, ẹyẹ ìwò ẹ̀bá odò ni yóò yọ ọ́, igún yóò mú un jẹ.
18 Tre Ting ere mig forunderlige; og fire Ting kender jeg ikke:
“Àwọn nǹkan mẹ́ta wà tí ó jẹ́ ìyàlẹ́nu fún mi, mẹ́rin tí kò yé mi,
19 Ørnens Vej imod Himmelen, Slangens Vej over Klippen, Skibets Vej midt paa Havet, og en Mands Vej til en Jomfru.
ipa ẹyẹ idì ní òfúrufú ipa ejò lórí àpáta ipa ọkọ̀ ojú omi lójú agbami Òkun àti ipa ọ̀nà ọkùnrin tí ó mú wúńdíá lọ́wọ́.
20 Saa er en Horekvindes Vej; hun spiser og afvisker sin Mund og siger: Jeg har ikke gjort Uret.
“Èyí ni ọ̀nà alágbèrè obìnrin ó jẹun ó sì nu ẹnu rẹ̀ ó sì wí pé, ‘N kò ṣe ohunkóhun tí kò tọ́.’
21 Under tre ryster et Land, og under fire kan det ikke holde ud:
“Lábẹ́ nǹkan mẹ́ta ni ilé ayé ti ń wárìrì lábẹ́ ohun mẹ́rin ni kò ti lè mí fín ín.
22 Under en Træl, naar han kommer til at herske; og en Daare, naar han bliver mæt af Brød;
Ìránṣẹ́ tí ó di ọba aláìgbọ́n tí ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ,
23 under en forhadt Kvinde, naar hun bliver gift; og en Trælkvinde, naar hun bliver sin Frues Arving.
obìnrin tí gbogbo ènìyàn kórìíra tí ó sì wá lọ́kọ ìránṣẹ́bìnrin tí ó gbọkọ mọ́ ọ̀gá rẹ̀ lọ́wọ́.
24 Der er fire smaa paa Jorden, dog ere de vise, saare vise:
“Àwọn ohun mẹ́rin ló kéré láyé síbẹ̀ wọ́n gbọ́n gidigidi.
25 Myrerne ere ikke et stærkt Folk, alligevel berede de deres Spise om Sommeren;
Àwọn èèrà jẹ́ aláìlágbára ẹ̀dá, síbẹ̀ wọ́n kó oúnjẹ wọn pamọ́ ní àsìkò òjò.
26 Kaninerne ere et afmægtigt Folk, dog indrette de deres Hus i Klippen;
Ehoro jẹ́ aláìlágbára ẹ̀dá; síbẹ̀ wọ́n ń ṣe ihò wọn sí ibi pálapàla àpáta;
27 Græshopperne have ingen Konge, alligevel drage de ud, alle i sluttet Skare;
àwọn eṣú kò ní ọba, síbẹ̀ gbogbo wọ́n ń jáde lọ ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́
28 Firbenet griber fat med Hænder, og dog er det i Kongepaladser.
Ọmọnílé fi ọwọ́ rẹ̀ dì mú, síbẹ̀ a ń rí i ní ààfin ọba.
29 Der er tre, som have et smukt Skridt, og fire, som have en smuk Gang:
“Àwọn ohun mẹ́ta ní ń bẹ tí ń rìn rere, ohun mẹ́rin ni ó dára púpọ̀ ní ìrìn rírìn:
30 Løven, som er vældig iblandt Dyrene og ikke viger tilbage for nogens Ansigt;
Kìnnìún, alágbára láàrín ẹranko tí kì í sá fún ohunkóhun
31 Hesten, som er omgjordet om Lænderne; Bukken; og en Konge, som ingen tør rejse sig imod.
Ẹsin tí a dì lẹ́gbẹ̀ẹ́; àti òbúkọ, àti ọba láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀.
32 Har du handlet daarligt, der du ophøjede dig, og har du tænkt ondt, da læg Haand paa Mund!
“Bí ìwọ bá ti hùwà aṣiwèrè nípa gbígbé ara rẹ ga, tàbí tí o bá ti gbèrò ibi, da ọwọ́ rẹ bo ẹnu rẹ!
33 Thi den, som trykker Mælk, faar Ost derudaf; og den, som trykker Næsen, faar Blod derudaf; og den, som trykker Vrede, faar Trætte derudaf.
Nítorí bí fífún omi ọmú tí í mú wàrà wá, tí fífún imú sì ń mú ẹ̀jẹ̀ jáde, bẹ́ẹ̀ ni rírú ìbínú sókè í mú ìjà wá.”

< Ordsprogene 30 >