< 4 Mojžišova 29 >
1 Měsíce pak sedmého v první den jeho shromáždění svaté míti budete, žádného díla robotného nebudete dělati; to jest den troubení vašeho.
“‘Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù keje, kí ẹ ní àpéjọ mímọ́, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan. Ọjọ́ ìfùnpè ni ó jẹ́ fún yín.
2 A obětovati budete zápal u vůni příjemnou Hospodinu, volka mladého jednoho, skopce jednoho, beránků ročních bez poškvrny sedm;
Gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn sí Olúwa, ẹ pèsè ẹgbọrọ akọ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan aláìlábùkù, kí ẹ fi ẹbọ sísun.
3 A obět suchou při nich z mouky bělné olejem zadělané, tři desetiny na každého volka, a dvě desetiny na každého skopce;
Pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ wọn, ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò, ìdámẹ́ta nínú mẹ́wàá òsùwọ̀n fún akọ màlúù kan, àti ìdá méjì nínú mẹ́wàá, òsùwọ̀n fún àgbò kan,
4 A desetina jedna na každého beránka z sedmi beránků;
àti ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n fún ọ̀dọ́-àgùntàn kan, àti fún ọ̀dọ́-àgùntàn méje.
5 A kozla jednoho v obět za hřích k očištění vás.
Àti òbúkọ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣètùtù fún yín.
6 Mimo zápalnou obět novoměsíčnou s obětí její suchou, a mimo obět zápalnou ustavičnou s obětí její suchou, a s obětmi jejich mokrými vedlé pořádku jejich, u vůni příjemnou, v obět ohnivou Hospodinu.
Pẹ̀lú ẹbọ sísun oṣù àti ẹbọ ohun jíjẹ rẹ̀ àti ẹbọ sísun ìgbà gbogbo àti ẹbọ mímu wọn gẹ́gẹ́ bí ìlànà wọn. Fún òórùn dídùn, ẹbọ tí a fi iná ṣe sí Olúwa.
7 V desátý pak den téhož měsíce sedmého shromáždění svaté míti budete, a ponižovati budete životů svých; žádného díla nebudete dělati.
“‘Ní ọjọ́ kẹwàá nínú oṣù keje, kí ẹ ṣe àpéjọ mímọ́. Kí ẹ̀yin kí ó sẹ́ ara yín, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan.
8 A obětovati budete obět zápalnou Hospodinu u vůni příjemnou, volka mladého jednoho, skopce jednoho, beránků ročních sedm, a ti ať jsou bez poškvrny;
Kí ẹ̀yin kí ó rú ẹbọ sísun olóòórùn dídùn sí Olúwa, ẹgbọrọ akọ màlúù kan, àgbò kan, àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn méje ọlọ́dún kan, kí wọn kí ó sì jẹ́ aláìlábùkù fún yín.
9 A obět suchou jejich z mouky bělné olejem zadělané, tři desetiny na každého volka, a dvě desetiny na každého skopce;
Pẹ̀lú akọ màlúù, pèsè ọrẹ ìdámẹ́wàá mẹ́ta, òsùwọ̀n ìyẹ̀fun tí a fi òróró pò àti ìdámẹ́wàá méjì òsùwọ̀n fún àgbò kan,
10 A desetina jedna na každého beránka z těch sedmi beránků;
àti fún ọ̀dọ́-àgùntàn kọ̀ọ̀kan, ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n.
11 Kozla jednoho v obět za hřích, mimo obět za hřích k očištění, a mimo zápal ustavičný s obětí suchou jeho, a s obětmi mokrými jejich.
Pẹ̀lú akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, pẹ̀lú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún ètùtù àti ẹbọ sísun gbogbo ìgbà àti ẹbọ jíjẹ rẹ̀ àti ẹbọ mímu wọn.
12 V patnáctý také den měsíce sedmého shromáždění svaté míti budete; žádného díla robotného nebudete dělati, ale slaviti budete svátek Hospodinu za sedm dní.
“‘Ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù keje, kí ẹ̀yin kí ó ní àpéjọ mímọ́, ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan. Kí ẹ̀yin kí ó sì ṣe àjọyọ̀ fún Olúwa fún ọjọ́ méje.
13 A obětovati budete zápal v obět ohnivou u vůni spokojující Hospodina, volků mladých třinácte, skopce dva, beránků ročních čtrnácte, a ti ať jsou bez poškvrny;
Kí ẹ sì rú ẹbọ sísun kan, ẹbọ tí a fi iná ṣe, tí ó ní òórùn dídùn sí Olúwa, ẹbọ tí ẹgbọrọ akọ màlúù mẹ́tàlá, àgbò méjì àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn mẹ́rìnlá tí ó jẹ́ ọdún kan, tí gbogbo rẹ̀ sì jẹ́ aláìlábùkù.
14 Též obět suchou jejich z mouky bělné olejem zadělané, tři desetiny na každého volka z třinácti volků, dvě desetiny na každého skopce z těch dvou skopců,
Àti ẹbọ ohun jíjẹ wọn, ìyẹ̀fun tí a fi òróró pò, ìdámẹ́wàá mẹ́ta òsùwọ̀n fún akọ màlúù kan, bẹ́ẹ̀ ni fún akọ màlúù mẹ́tẹ̀ẹ̀tàlá, ìdámẹ́wàá méjì òsùwọ̀n fún àgbò kan, bẹ́ẹ̀ ni fún àgbò méjèèjì,
15 A jednu desetinu na každého beránka z těch čtrnácti beránků;
àti fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀dọ́-àgùntàn kan. Bẹ́ẹ̀ ni fún ọ̀dọ́-àgùntàn mẹ́rẹ̀ẹ̀rìnlá.
16 A kozla jednoho v obět za hřích, mimo zápal ustavičný s obětí jeho suchou i mokrou.
Àti akọ ewúrẹ́ kan gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, pẹ̀lú ẹbọ sísun gbogbo ìgbà ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu rẹ̀.
17 Potom dne druhého volků mladých dvanácte, skopce dva, beránků ročních bez poškvrny čtrnácte,
“‘Àti ní ọjọ́ kejì ni kí ẹ̀yin kí ó fi ẹgbọrọ akọ màlúù méjìlá, àgbò méjì àti ọ̀dọ́-àgùntàn mẹ́rìnlá ọlọ́dún kan aláìlábùkù rú ẹbọ.
18 S obětí suchou při nich, a s obětmi mokrými jejich při každém volku, skopci i beránku vedlé počtu jejich, jakž jest obyčej;
Pẹ̀lú fún akọ màlúù, fún àgbò, àti fún ọ̀dọ́-àgùntàn kí ẹ pe ẹbọ ohun jíjẹ, àti ẹbọ ohun mímu, kí ó jẹ́ bí iye wọn, gẹ́gẹ́ bí ìlànà.
19 A kozla jednoho v obět za hřích, mimo zápal ustavičný s obětí suchou jeho a s obětmi mokrými jeho.
Àti òbúkọ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú ẹbọ sísun gbogbo ìgbà pẹ̀lú ẹbọ jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu.
20 Dne pak třetího volků jedenácte, skopce dva, a beránků ročních bez poškvrny čtrnácte,
“‘Ní ọjọ́ kẹta, pèsè akọ màlúù mọ́kànlá, àgbò méjì, akọ àgùntàn mẹ́rìnlá ti ọdún kan tí kò ní àbùkù.
21 S obětí suchou a s obětmi mokrými jejich při každém volku, skopci i beránku, vedlé počtu jejich, jakž jest obyčej;
Pẹ̀lú akọ màlúù, àgbò, àti akọ àgùntàn, pèsè ọrẹ ohun jíjẹ àti ohun mímu gẹ́gẹ́ bí iye wọn.
22 A kozla v obět za hřích jednoho, mimo obět zápalnou ustavičnou s obětí její suchou i mokrou.
Pẹ̀lú akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àti ẹbọ sísun ìgbà gbogbo pẹ̀lú ẹbọ jíjẹ àti ẹbọ mímu.
23 Dne pak čtvrtého volků deset, skopce dva, beránků ročních bez poškvrny čtrnácte,
“‘Ní ọjọ́ kẹrin, pèsè akọ màlúù mẹ́wàá, àgbò méjì, àti ọ̀dọ́-àgùntàn mẹ́rìnlá ti ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbùkù.
24 S obětí suchou i s obětmi mokrými jejich při každém volku, skopci a beránku, vedlé počtu jejich, jakž jest obyčej;
Àti akọ màlúù, àgbò àti àgùntàn, pèsè ẹbọ jíjẹ àti ẹbọ mímu gẹ́gẹ́ bí iye wọn, gẹ́gẹ́ bí ìlànà.
25 A kozla jednoho v obět za hřích, mimo obět zápalnou ustavičnou s obětí její suchou i mokrou.
Àti akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú ẹbọ sísun gbogbo ìgbà, pẹ̀lú ẹbọ jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu.
26 Dne také pátého volků devět, skopce dva, beránků ročních bez poškvrny čtrnácte,
“‘Àti ní ọjọ́ karùn-ún, pèsè akọ màlúù mẹ́sàn-án, àgbò méjì àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn mẹ́rìnlá ti ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, tí gbogbo rẹ̀ kò ní àbùkù.
27 S obětí suchou i s obětmi mokrými jejich při každém volku, skopci i beránku, vedlé počtu jejich, jakž jest obyčej;
Pẹ̀lú akọ màlúù, àgbò àti ọ̀dọ́-àgùntàn, pèsè ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu gẹ́gẹ́ bí iye wọn sí ìlànà.
28 A kozla jednoho v obět za hřích, mimo obět zápalnou ustavičnou s obětí její suchou i mokrou.
Àti akọ ewúrẹ́ kan gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú ẹbọ sísun ìgbà gbogbo pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu.
29 A dne šestého volků osm, skopce dva, beránků ročních bez poškvrny čtrnácte,
“‘Ní ọjọ́ kẹfà, pèsè akọ màlúù mẹ́jọ, àgbò ọlọ́dún kan tí gbogbo rẹ̀ kò ní àbùkù.
30 S obětí suchou a s obětmi mokrými jejich při každém volku, skopci i beránku, vedlé počtu jejich, jakž jest obyčej;
Pẹ̀lú akọ màlúù, àgbò, àti ọ̀dọ́-àgùntàn, pèsè ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu gẹ́gẹ́ bí iye wọn.
31 A kozla jednoho v obět za hřích, mimo obět zápalnou ustavičnou s obětí její suchou i s obětmi mokrými.
Pẹ̀lú akọ ewúrẹ́ kan gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, pẹ̀lú ẹbọ sísun gbogbo ìgbà pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu.
32 Tolikéž dne sedmého volků sedm, skopce dva, beránků ročních bez poškvrny čtrnácte,
“‘Àti ní ọjọ́ keje, pèsè akọ màlúù méje, àgbò méjì, àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn mẹ́rìnlá ti ọlọ́dún kan, tí gbogbo rẹ̀ kò sì ní àbùkù.
33 S obětí suchou i s obětmi mokrými jejich na volky, skopce i beránky, vedlé počtu jejich, jakž jest obyčej;
Pẹ̀lú akọ màlúù, àgbò, àti ọ̀dọ́-àgùntàn, pèsè ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu fún wọn gẹ́gẹ́ bí iye wọn.
34 A kozla jednoho v obět za hřích, mimo obět zápalnou ustavičnou s obětí její suchou i mokrou.
Pẹ̀lú akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, pẹ̀lú ẹbọ sísun gbogbo ìgbà, pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu.
35 Dne pak osmého slavnost míti budete; žádného díla robotného nebudete dělati.
“‘Àti ní ọjọ́ kẹjọ kí ẹ̀yin kó ní àpéjọ, kí ẹ má sì ṣe iṣẹ́ kankan.
36 A obětovati budete obět zápalnou, v obět ohnivou vůně spokojující Hospodina, volka jednoho, skopce jednoho, a beránků ročních sedm bez poškvrny,
Kí ẹ̀yin ṣe ìgbékalẹ̀ ẹbọ tí a fi iná ṣe tí ó ní òórùn dídùn sí Olúwa, ẹbọ sísun ti akọ màlúù kan, àgbò ọlọ́dún kan àti ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan méje, gbogbo rẹ̀ tí kò ní àbùkù.
37 S obětí suchou i s obětmi mokrými jejich při volku, skopci i beráncích, vedlé počtu jejich, jakž jest obyčej;
Pẹ̀lú akọ màlúù, àgbò, àti ọ̀dọ́-àgùntàn, pèsè fún wọn ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu gẹ́gẹ́ bí iye wọn.
38 A kozla jednoho v obět za hřích, mimo obět zápalnou ustavičnou s obětí její suchou i mokrou.
Àti akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú ẹbọ sísun gbogbo ìgbà àti ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu.
39 Ty věci vykonávati budete Hospodinu při slavnostech vašich, kromě toho, což byste z slibu aneb z dobré vůle své obětovali, buď zápalné, aneb suché, aneb mokré, aneb pokojné oběti vaše.
“‘Pẹ̀lú ẹ̀jẹ́ yín, àti ẹbọ àtinúwá yín, kí ẹ̀yin kí o pèsè fún Olúwa ní àjọ̀dún tí a yàn yín, ẹbọ sísun, ẹbọ ohun jíjẹ, ẹbọ ohun mímu àti ẹbọ ìkẹ́gbẹ́ yín.’”
40 I oznámil Mojžíš synům Izraelským všecky ty věci, kteréž přikázal jemu Hospodin.
Mose sì sọ fún àwọn ọmọ Israẹli gbogbo ohun tí Olúwa ti pàṣẹ fún un.