< Psalmi 21 >

1 Zborovođi. Psalam. Davidov. Jahve, zbog tvoje se moći kralj veseli, zbog pomoći tvoje radosno kliče.
Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi. Háà! Olúwa, ọba yóò yọ̀ nínú agbára rẹ, àti ní ìgbàlà rẹ, yóò ti yọ̀ pẹ́ tó!
2 Ti mu ispuni želju srca, ne odbi molitve usana njegovih.
Nítorí pé ìwọ ti fi ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ fún un, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò sì dùn ún ní ìbéèrè ẹnu rẹ̀. (Sela)
3 Ti ga predusrete blagoslovima sretnim, na glavu mu krunu stavi od suhoga zlata.
Ìwọ ti fi àwọn ìbùkún oore kò ó ni ọ̀nà ìwọ fi adé wúrà dé e ní orí.
4 Za život te molio, i ti mu dade premnoge dane - za vijeke vjekova.
Ó béèrè fún ìyè, ìwọ sì fi fún un, àní ọjọ́ gígùn títí ayérayé.
5 Pomoću tvojom slava je njegova velika, uresio si ga veličanstvom i sjajem.
Ògo rẹ̀ pọ̀ nípasẹ̀ ìṣẹ́gun tí o fi fún un; ìwọ sì jẹ́ kí iyì ọláńlá rẹ̀ wà lára rẹ.
6 Ti ga učini blagoslovom za vjekove, veseliš ga radošću lica svojega.
Dájúdájú, ìwọ ti fi ìbùkún ayérayé fún un: ìwọ sì mú inú rẹ̀ dùn pẹ̀lú ayọ̀ ojú u rẹ̀.
7 Doista, kralj se uzda u Jahvu i po dobroti Svevišnjega neće se pokolebati.
Ọba ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa; nípasẹ̀ ìfẹ́ Ọ̀gá-ògo tí kì í kùnà kì yóò sípò padà.
8 Tvoja ruka nek' pronađe sve dušmane tvoje, desnica tvoja neka stigne one koji te mrze!
Ọwọ́ rẹ yóò wá gbogbo àwọn ọ̀tá a rẹ rí; ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò wá àwọn tí o kórìíra rẹ rí.
9 Nek' budu kao u peći ognjenoj kad se ukaže lice tvoje! Nek' ih Jahve gnjevom uništi, neka ih proguta oganj!
Nígbà tí ìwọ bá yọ ìwọ yóò mú wọn dàbí iná ìléru. Olúwa yóò gbé wọn mì nínú ìbínú rẹ̀, àti pé iná rẹ̀ yóò jó wọn run.
10 Njihovo potomstvo satri sa zemlje i rod im iz sinova ljudskih.
Ìwọ yóò pa ìrandíran wọn run kúrò lórí ilẹ̀, àti irú-ọmọ wọn kúrò láàrín àwọn ọmọ ènìyàn.
11 Ako li stanu zlo kovati protiv tebe, ako spremaju spletke, neće uspjeti.
Bí o tilẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n ro èrò ibi sí ọ wọ́n sì ń pète ìwà ìkà, wọn kì yóò ṣe àṣeyọrí.
12 Ti ćeš ih natjerati u bijeg, svoj luk ćeš usmjeriti na njih.
Nítorí pé ìwọ yóò mú wọn yí ẹ̀yìn wọn padà nígbà tí o bá pinnu láti ta wọ́n ní ọfà.
13 Ustani, Jahve, u sili svojoj! Daj nam da pjesmama slavimo snagu tvoju!
Gbígbéga ni ọ́ Olúwa, nínú agbára rẹ; a ó kọrin, a ó yín agbára a rẹ̀.

< Psalmi 21 >