< Postanak 34 >
1 Dina, kći koju je Lea rodila Jakovu, iziđe da posjeti neke žene onoga kraja.
Ní ọjọ́ kan, Dina ọmọbìnrin tí Lea bí fún Jakọbu jáde lọ bẹ àwọn ọmọbìnrin ilẹ̀ náà wò.
2 Opazi je Hivijac Šekem, sin Hamora, poglavice kraja, pa je pograbi i na silu s njom leže.
Nígbà tí Ṣekemu ọmọ ọba Hamori ará Hifi rí i, ó mú un, ó sì fi ipá bá a lo pọ̀.
3 Njegovo srce prione za Dinu, Jakovljevu kćer, i on se u djevojku zaljubi. Nastojao je pridobiti djevojčino srce.
Ọkàn rẹ sì fà sí Dina ọmọ Jakọbu gan an, ó sì fẹ́ràn rẹ̀ ó sì bá ọmọbìnrin náà sọ̀rọ̀ ìfẹ́.
4 Šekem je govorio i svom ocu Hamoru: “Onu mi djevojku uzmi za ženu!”
Ṣekemu sì wí fún Hamori baba rẹ̀ pé, “Fẹ́ ọmọbìnrin yìí fún mi bí aya.”
5 Jakov sazna da je Šekem obeščastio njegovu kćer Dinu. Ali kako su njegovi sinovi bili uz blago na polju, Jakov nije poduzimao ništa dok oni ne dođu.
Nígbà tí Jakọbu gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ pé a fi ipá bá Dina ọmọbìnrin òun ní ògo jẹ́, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ rẹ̀ wà nínú pápá níbi tí wọ́n ti ń daran nítorí náà ó mú sùúrù títí tí wọ́n fi dé.
6 Uto dođe k Jakovu Šekemov otac Hamor da se s njim sporazumije,
Hamori baba Ṣekemu sì jáde wá láti bá Jakọbu sọ̀rọ̀.
7 upravo kad su se Jakovljevi sinovi vraćali iz polja. Kad su čuli vijest, ljudi su bili ojađeni i vrlo ljuti. Što je Šekem učinio - legavši s Jakovljevom kćeri - u Izraelu je bila sramota. To se nije smjelo trpjeti.
Àwọn ọmọ Jakọbu sì ti oko dé, wọ́n sì gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ inú wọn sì bàjẹ́, ó sì ń bí wọn nínú gidigidi, nítorí tí ó ṣe ohun búburú ní Israẹli, ní ti ó bá ọmọbìnrin ọmọ Jakọbu lòpọ̀—irú ohun tí kò yẹ kí ó ṣẹlẹ̀ rárá.
8 Hamor im reče. “Moj se sin Šekem svom dušom zaljubio u vašu kćer. Dajte mu je za ženu!
Hamori sì bá wọn sọ̀rọ̀ pé, “Ọkàn ọmọ mi Ṣekemu fà sí ọmọ rẹ. Jọ̀wọ́ fi fún un gẹ́gẹ́ bí aya.
9 Oprijateljite se s nama: dajite nam svoje kćeri, a naše kćeri uzimajte sebi!
Ẹ jẹ́ kí a máa ṣe ìgbéyàwó láàrín ara wa, kí àwọn ọmọ yín kó máa fẹ́ àwọn ọmọ wa.
10 Tako možete živjeti među nama; zemlja je pred vama da se naselite, u njoj se slobodno krećete i stječete imovinu!”
Ẹ lè máa gbé láàrín wa, ibikíbi tí ó bá tẹ́ yín lọ́rùn láàrín wa ni ẹ lè gbé, ẹ máa ṣe òwò yín kí ẹ sì kó ọrọ̀ jọ fún ara yín.”
11 Potom Šekem reče njezinu ocu i njezinoj braći: “Da nađem milost u vašim očima, dat ću vam što zatražite.
Ṣekemu sì wí fún baba àti arákùnrin Dina pé, “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ jẹ́ kí n rí ojúrere yín, èmi yóò sì fún yín ní ohunkóhun tí ẹ̀yin bá fẹ́ gbà.
12 Tražite od mene koliko hoćete: sve što god zapitate dat ću, samo mi dajte djevojku za ženu.”
Iyekíye tí owó orí rẹ̀ bá jẹ́ àti ẹ̀bùn gbogbo tí ẹ bá fẹ́, bí ó ti wù kí ó pọ̀ tó, èmi yóò san án, kí ẹ sá à jẹ́ kí ń fi ọmọ náà ṣe aya.”
13 Jakovljevi sinovi odgovore Šekemu i njegovu ocu Hamoru - govorili su s prijevarom jer je obeščastio njihovu sestru Dinu -
Àwọn ọmọ Jakọbu sì fi ẹ̀tàn dá Ṣekemu àti Hamori baba rẹ̀ lóhùn, wọ́n sì wí pé, nítorí tí ó ti ba ògo Dina arábìnrin wọn jẹ́.
14 te im rekoše: “Ne možemo pristati da svoju sestru damo čovjeku koji nije obrezan, jer bi to za nas bila sramota.
Wọ́n wí fún wọn pé, “Àwa kò le ṣe nǹkan yìí láti fi arábìnrin wa fún aláìkọlà, nítorí àbùkù ni èyí yóò jẹ́ fún wa.
15 Jedino ćemo je dati ako postanete kao i mi, ako obrežete sve svoje muškarce.
Àwa yóò fi ara mọ́ ọn bí ẹ̀yin yóò bá gbà láti dàbí i tiwa, wí pé ẹ̀yin pẹ̀lú yóò kọ gbogbo ọkùnrin yín ní ilà.
16 Onda vam možemo davati svoje kćeri i uzimati vaše sebi, s vama se naseliti i biti jedan rod.
Nígbà náà ni àwa yóò le máa fún yín ní ọmọ wa, tí àwa náà yóò máa fẹ́ ẹ yín. A ó máa gbé láàrín yín, a ó sì di ara kan pẹ̀lú yín.
17 A ako ne pristajete na obrezanje, uzet ćemo svoju kćer i otići.”
Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá kọ̀ láti kọlà, àwa yóò mú arábìnrin wa, á ó sì máa lọ.”
18 Hamoru i Šekemu, Hamorovu sinu, njihov se zahtjev učini povoljan.
Àbá náà sì dùn mọ́ Hamori àti Ṣekemu ọmọ rẹ̀.
19 Mladić nije časio da zahtjev izvrši, jer je čeznuo za Jakovljevom kćeri; a bio je najuvaženiji od svih u očevu domu.
Ọ̀dọ́mọkùnrin náà, ẹni tí ó jẹ́ ẹni iyì jùlọ ní ilé baba rẹ̀, kò jáfara láti ṣe ohun tí wọ́n wí. Nítorí tí ó fẹ́ràn ọmọbìnrin Jakọbu.
20 Tako Hamor i njegov sin Šekem dođu u svoje gradsko vijeće i obrate se svojim sugrađanima ovako:
Hamori àti Ṣekemu ọmọ rẹ̀ sì wá sí ẹnu ibodè ìlú náà wọn sì bá àwọn ará ìlú náà sọ̀rọ̀.
21 “Ovaj je svijet prijazan; neka se među nama u zemlji nasele; neka se po njoj slobodno kreću; ima dosta prostora u zemlji za njih; možemo uzimati njihove kćeri sebi za žene, a njima davati svoje.
Wí pé, “Ìwà àwọn ọkùnrin wọ̀nyí dára, ẹ jẹ́ kí wọn máa gbé ní àárín wa, kí wọn sì máa ṣòwò, ilẹ̀ kúkú wà rẹpẹtẹ tó gba ààyè dáradára. A lè fẹ́ àwọn ọmọ wọ́n, ki wọn sì fẹ́ tiwa pẹ̀lú.
22 No ljudi će pristati da među nama žive i s nama budu jedan rod samo ako se svi naši muškarci obrežu kao što su oni obrezani.
Ṣùgbọ́n kín ní kan ni a lè ṣe kí wọn tó gbà láti gbé pẹ̀lú wa, ìyẹn sì ni pé àwọn ọkùnrin wa yóò kọlà bí i tiwọn.
23 Zar tako ne bi stoka koju su stekli, sve njihovo blago - bilo naše? Pristanimo, pa neka se među nama nasele!”
Ṣe bí àwọn ẹran wọn àti ẹrú wọn àti àwọn ohun ọ̀sìn wọn ni yóò di tiwa bí a bá lè gbà bẹ́ẹ̀, wọn yóò sì máa gbé ni àárín wa.”
24 Svi odrasli muškarci koji imaju pravo izaći na gradska vrata poslušaše Hamora i njegova sina Šekema, pa bude obrezan svaki muškarac - svaki koji ima pravo izaći na gradska vrata.
Gbogbo àwọn ọkùnrin tí ń jáde ní ẹnu-bodè ìlú náà sì gbọ́ ti Hamori àti Ṣekemu ọmọ rẹ̀. Gbogbo ọkùnrin ìlú náà sì kọlà.
25 A trećega dana, dok su oni još bili u bolovima, dva Jakovljeva sina, Šimun i Levi, Dinina braća, pograbe svaki svoj mač i nesmetano dođu u grad te poubijaju sve muškarce.
Lẹ́yìn ọjọ́ kẹta, nígbà tí gbogbo wọn sì wà nínú ìrora. Àwọn ọmọ Jakọbu méjì, Simeoni àti Lefi tí ó jẹ́ ẹ̀gbọ́n fún Dina, sì mú idà wọn pẹ̀lú ìgboyà, wọ́n sì pa gbogbo ọkùnrin ìlú náà.
26 Sasijeku mačem Hamora i njegova sina Šekema, uzmu Dinu iz Šekemove kuće i odu.
Wọ́n sì fi idà pa Hamori àti Ṣekemu ọmọ rẹ̀, wọ́n mú Dina kúrò ní ilé wọn, wọ́n sì jáde.
27 Ostali Jakovljevi sinovi dođu na ubijene i opustoše grad što je njihova sestra bila obeščašćena.
Àwọn ọmọ Jakọbu sì wọlé àwọn tí a pa, wọ́n sì kó ẹrù ìlú tí a ti ba ògo arábìnrin wọn jẹ́.
28 Što je bilo krupne i sitne stoke i magaradi, u gradu i u polju, otjeraju;
Wọ́n kó màlúù wọn àti agbo ẹran wọn àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àti ohun gbogbo tí ó wà nínú ìlú àti ní oko.
29 opljačkaju sva njihova dobra, a svu im djecu i žene - sve što je bilo po kućama - odvedu u roblje.
Gbogbo ọrọ̀ wọn, gbogbo obìnrin ìlú àti àwọn ọmọ wẹẹrẹ pátápátá ni wọ́n kó. Wọ́n sì kó gbogbo ohun tí ó wà nínú ilé wọn bí ìkógun.
30 Jakov reče Šimunu i Leviju: “Uveli ste me u nepriliku omrazivši me stanovnicima zemlje, Kanaancima i Perižanima. Ako se ujedine protiv mene i napadnu me, dok je nas ovako malo na broj, istrijebit će me s mojim domom.”
Nígbà náà ni Jakọbu wí fún Simeoni àti Lefi wí pé, “Ẹ̀yin ti kó ìyọnu bá mi nípa sísọ mí di olóòórùn láàrín ará Kenaani àti Peresi, tí ó ń gbé ilẹ̀ yìí. Àwa kò pọ̀, bí wọn bá wá parapọ̀ ṣígun sí wa, gbogbo wa pátápátá ni wọn yóò parun.”
31 Oni odgovore: “Zar da prema našoj sestri postupaju kao prema kakvoj bludnici?”
Ṣùgbọ́n wọ́n dáhùn pé, “Ǹjẹ́ ó yẹ kí ó ṣe arábìnrin wa bí panṣágà?”