< 詩篇 6 >
1 大衛的詩,交與伶長。用絲弦的樂器,調用第八。 耶和華啊,求你不要在怒中責備我, 也不要在烈怒中懲罰我!
Fún adarí orin. Fún ohun èlò orin olókùn. Gẹ́gẹ́ bí ti ṣeminiti. Saamu ti Dafidi. Olúwa, má ṣe bá mi wí nínú ìbínú rẹ kí ìwọ má ṣe nà mí nínú gbígbóná ìrunú rẹ.
2 耶和華啊,求你可憐我,因為我軟弱。 耶和華啊,求你醫治我,因為我的骨頭發戰。
Ṣàánú fún mi, Olúwa, nítorí èmi ń kú lọ; Olúwa, wò mí sán, nítorí egungun mi wà nínú ìnira.
3 我心也大大地驚惶。 耶和華啊,你要到幾時才救我呢?
Ọkàn mi wà nínú ìrora. Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa, yóò ti pẹ́ tó?
4 耶和華啊,求你轉回搭救我! 因你的慈愛拯救我。
Yípadà, Olúwa, kí o sì gbà mí; gbà mí là nípa ìfẹ́ rẹ tí kì í ṣákì í.
5 因為,在死地無人記念你, 在陰間有誰稱謝你? (Sheol )
Ẹnikẹ́ni kò ni rántí rẹ nígbà tí ó bá kú. Ta ni yóò yìn ọ́ láti inú isà òkú? (Sheol )
6 我因唉哼而困乏; 我每夜流淚,把床榻漂起, 把褥子濕透。
Agara ìkérora mi dá mi tán. Gbogbo òru ni mo wẹ ibùsùn mi pẹ̀lú ẹkún, mo sì fi omi rin ibùsùn mi pẹ̀lú omijé.
7 我因憂愁眼睛乾癟, 又因我一切的敵人眼睛昏花。
Ojú mi di aláìlera pẹ̀lú ìbànújẹ́; wọ́n kùnà nítorí gbogbo ọ̀tá mi.
8 你們一切作孽的人,離開我吧! 因為耶和華聽了我哀哭的聲音。
Kúrò lọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe iṣẹ́ ibi, nítorí Olúwa ti gbọ́ igbe mi.
Olúwa ti gbọ́ ẹkún mi fún àánú; Olúwa ti gba àdúrà mi.
10 我的一切仇敵都必羞愧,大大驚惶; 他們必要退後,忽然羞愧。
Gbogbo àwọn ọ̀tá mi lójú yóò tì, wọn yóò sì dààmú; wọn yóò sì yípadà nínú ìtìjú àìròtẹ́lẹ̀.