< 詩篇 49 >
1 可拉後裔的詩,交與伶長。 萬民哪,你們都當聽這話! 世上一切的居民,
Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu. Ẹ gbọ́ èyí, gbogbo ènìyàn! Ẹ fi etí sí i, gbogbo ẹ̀yin aráyé.
Àti ẹni tí ó ga àti ẹni tí ó kéré tálákà àti ọlọ́lá pẹ̀lú!
Ẹnu mi yóò sọ̀rọ̀ ọgbọ́n, èrò láti ọkàn mi yóò mú òye wá
èmi yóò dẹ etí mi sílẹ̀ sí òwe, èmi yóò ṣí ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ mi sílẹ̀ lójú okùn dùùrù.
5 在患難的日子,奸惡隨我腳跟,四面環繞我, 我何必懼怕?
Èéṣe ti èmi yóò bẹ̀rù nígbà tí ọjọ́ ibi dé? Nígbà tí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ajinnilẹ́sẹ̀ mi yí mi ká,
àwọn tí o gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ wọn, tí wọn sì ń ṣe ìlérí ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ wọn.
7 一個也無法贖自己的弟兄, 也不能替他將贖價給上帝,
Kò sí ọkùnrin tí ó lè ra ẹ̀mí ẹnìkejì rẹ̀ padà tàbí san owó ìràpadà fún Ọlọ́run.
8 叫他長遠活着,不見朽壞; 因為贖他生命的價值極貴, 只可永遠罷休。
Nítorí ìràpadà fún ẹni jẹ́ iyebíye kò sì sí iye owó tó tó fún sísan rẹ̀,
ní ti kí ó máa wà títí ayé láìrí isà òkú.
10 他必見智慧人死, 又見愚頑人和畜類人一同滅亡, 將他們的財貨留給別人。
Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn rí ọkùnrin ọlọ́gbọ́n tí ó kú, bẹ́ẹ̀ ni aṣiwèrè àti aláìlọ́gbọ́n pẹ̀lú ṣègbé wọ́n sì fi ọrọ̀ wọn sílẹ̀ fún ẹlòmíràn.
11 他們心裏思想: 他們的家室必永存, 住宅必留到萬代; 他們以自己的名稱自己的地。
Ibojì wọn ni yóò jẹ́ ilé wọn láéláé, ibùgbé wọn láti ìrandíran, wọn sọ orúkọ ilẹ̀ wọn ní orúkọ ara wọn.
12 但人居尊貴中不能長久, 如同死亡的畜類一樣。
Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí o wà nínú ọlá kò dúró pẹ́ ó sì dàbí ẹranko tí ó ṣègbé.
13 他們行的這道本為自己的愚昧; 但他們以後的人還佩服他們的話語。 (細拉)
Èyí ni òtítọ́ àwọn ènìyàn tí ó gbàgbọ́ nínú ara wọn, àti àwọn tí ń tẹ̀lé wọn, tí ó gba ọ̀rọ̀ wọn. (Sela)
14 他們如同羊群派定下陰間; 死亡必作他們的牧者。 到了早晨,正直人必管轄他們; 他們的美容必被陰間所滅,以致無處可存。 (Sheol )
Gẹ́gẹ́ bí àgùntàn ni a tẹ́ wọn sínú isà òkú ikú yóò jẹun lórí wọn; ẹni tí ó dúró ṣinṣin ni yóò, jẹ ọba lórí wọn ní òwúrọ̀. Ẹwà wọn yóò díbàjẹ́, isà òkú ni ibùgbé ẹwà wọn. (Sheol )
15 只是上帝必救贖我的靈魂脫離陰間的權柄, 因他必收納我。 (細拉) (Sheol )
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò ra ọkàn mi padà kúrò nínú isà òkú, yóò gbé mi lọ sọ́dọ̀ òun fún rara rẹ̀. (Sheol )
Má ṣe bẹ̀rù nígbà tí ẹnìkan bá di ọlọ́rọ̀. Nígbà tí ìyìn ilé rẹ̀ ń pọ̀ sí i.
17 因為,他死的時候甚麼也不能帶去; 他的榮耀不能隨他下去。
Nítorí kì yóò mú ohun kan lọ nígbà tí ó bá kú, ògo rẹ̀ kò ní bá a sọ̀kalẹ̀ sí ipò òkú.
18 他活着的時候,雖然自誇為有福 (你若利己,人必誇獎你);
Nígbà tí ó wà láyé, ó súre fún ọkàn ara rẹ̀. Àwọn ènìyàn yìn ọ́ nígbà tí ìwọ ṣe rere.
Òun yóò lọ sí ọ̀dọ̀ ìran àwọn baba rẹ̀ àwọn tí ki yóò ri ìmọ́lẹ̀ ayé.
Ọkùnrin tí ó ní ọlá tí kò ní òye dàbí ẹranko tí ó ṣègbé.