< 耶利米書 8 >
1 耶和華說:「到那時,人必將猶大王的骸骨和他首領的骸骨、祭司的骸骨、先知的骸骨,並耶路撒冷居民的骸骨,都從墳墓中取出來,
“‘Ní ìgbà náà ni Olúwa wí pé, wọn yóò mú egungun àwọn ọba Juda àti egungun àwọn ìjòyè, egungun àwọn àlùfáà àti egungun àwọn wòlíì àti egungun àwọn olùgbé Jerusalẹmu kúrò nínú ibojì.
2 拋散在日頭、月亮,和天上眾星之下,就是他們從前所喜愛、所事奉、所隨從、所求問、所敬拜的。這些骸骨不再收殮,不再葬埋,必在地面上成為糞土;
A ó yọ wọ́n síta fún oòrùn àti òṣùpá àti gbogbo àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run tí wọ́n ti fẹ́ràn tí wọ́n sì ti sìn, àti àwọn tí wọ́n ti tọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti wá tí wọ́n sì ti foríbalẹ̀ fún. Kì yóò ṣà wọ́n jọ tàbí sìn wọ́n, wọn yóò dàbí ìdọ̀tí tó wà lórí ilẹ̀.
3 並且這惡族所剩下的民在我所趕他們到的各處,寧可揀死不揀生。這是萬軍之耶和華說的。」
Níbikíbi tí mo bá lé wọn lọ, gbogbo àwọn ìyókù wọn yóò fẹ́ ikú ju ìyè lọ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.’
4 你要對他們說,耶和華如此說: 人跌倒,不再起來嗎? 人轉去,不再轉來嗎?
“Wí fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “‘Bí ènìyàn bá ṣubú lulẹ̀, wọn kì í padà dìde bí? Nígbà tí ènìyàn bá yà kúrò ní ọ̀nà rẹ, kì í yí padà bí?
5 這耶路撒冷的民,為何恆久背道呢? 他們守定詭詐,不肯回頭。
Èéṣe nígbà náà àwọn ènìyàn wọ̀nyí fi yà kúrò lọ́nà rẹ̀? Kí ló dé tí Jerusalẹmu fi yà kúrò ní gbogbo ìgbà? Wọ́n rọ̀ mọ́ ẹ̀tàn; wọ́n kọ̀ láti yípadà.
6 我留心聽,聽見他們說不正直的話。 無人悔改惡行,說: 我做的是甚麼呢? 他們各人轉奔己路, 如馬直闖戰場。
Mo ti fetísílẹ̀ dáradára, wọn kò sọ ohun tí ó tọ́. Kò sí ẹnìkan tó ronúpìwàdà nínú ìwà búburú rẹ̀, kí ó wí pé, “Kí ni mo ṣe?” Olúkúlùkù ń tọ ọ̀nà rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹṣin tó ń lọ sójú ogun.
7 空中的鸛鳥知道來去的定期; 斑鳩燕子與白鶴也守候當來的時令; 我的百姓卻不知道耶和華的法則。
Kódà, ẹyẹ àkọ̀ ojú ọ̀run mọ ìgbà tirẹ̀, àdàbà, alápáǹdẹ̀dẹ̀ àti lékèélékèé mọ àkókò ìṣípò padà wọn. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi kò mọ ohun tí Olúwa wọn fẹ́.
8 你們怎麼說:我們有智慧, 耶和華的律法在我們這裏? 看哪,文士的假筆舞弄虛假。
“‘Báwo ni ẹ̀yin ṣe lè wí pé, “Àwa gbọ́n, nítorí a ní òfin Olúwa,” nígbà tí ó jẹ́ pé kálámù èké àwọn akọ̀wé ti àwọn sọ ọ́ di ẹ̀tàn.
9 智慧人慚愧,驚惶,被擒拿; 他們棄掉耶和華的話, 心裏還有甚麼智慧呢?
Ojú yóò ti àwọn ọlọ́gbọ́n, a ó dà wọ́n láàmú, wọn yóò sì kó sí ìgbèkùn. Nítorí wọ́n ti kọ ọ̀rọ̀ Olúwa, irú ọgbọ́n wo ló kù tí wọ́n ní?
10 所以我必將他們的妻子給別人, 將他們的田地給別人為業; 因為他們從最小的到至大的都一味地貪婪, 從先知到祭司都行事虛謊。
Nítorí náà, èmi yóò fi ìyàwó wọn fún àwọn ọkùnrin mìíràn àti ilẹ̀ wọn fún àwọn ẹlòmíràn. Láti èyí tó kéré jù dé èyí tó dàgbà jù, gbogbo wọn ni èrè àjẹjù ń jẹ lógún; àwọn wòlíì àti àwọn àlùfáà pẹ̀lú ń hùwà ẹ̀tàn.
11 他們輕輕忽忽地醫治我百姓的損傷,說: 平安了!平安了! 其實沒有平安。
Wọ́n tọ́jú ọgbẹ́ àwọn ènìyàn mi gẹ́gẹ́ bí èyí tí kò jinlẹ̀. “Àlàáfíà, àlàáfíà,” ni wọ́n ń wí, nígbà tí kò sí àlàáfíà.
12 他們行可憎的事知道慚愧嗎? 不然,他們毫不慚愧, 也不知羞恥。 因此他們必在仆倒的人中仆倒; 我向他們討罪的時候, 他們必致跌倒。 這是耶和華說的。
Ǹjẹ́ wọ́n tijú fún ìṣe ìríra wọn? Bẹ́ẹ̀ kọ́, wọn kò ní ìtìjú rárá; wọn kò tilẹ̀ mọ bí wọ́n ti ṣe ń tì jú. Nítorí náà wọn yóò ṣubú pẹ̀lú àwọn tó ti ṣubú, a ó sì wó wọ́n lulẹ̀ nígbà tí a bá bẹ̀ wọ́n wò, ni Olúwa wí.
13 耶和華說:我必使他們全然滅絕; 葡萄樹上必沒有葡萄, 無花果樹上必沒有果子, 葉子也必枯乾。 我所賜給他們的, 必離開他們過去。
“‘Èmi yóò mú ìkórè wọn kúrò, ni Olúwa wí. Kì yóò sí èso lórí igi àjàrà. Kì yóò sí ọ̀pọ̀tọ́ lórí igi, ewé wọn yóò sì rẹ̀ sílẹ̀. Ohun tí mo ti fi fún wọn ni à ó gbà kúrò.’”
14 我們為何靜坐不動呢? 我們當聚集,進入堅固城, 在那裏靜默不言; 因為耶和華-我們的上帝使我們靜默不言, 又將苦膽水給我們喝, 都因我們得罪了耶和華。
“Èéṣe tí àwa fi jókòó ní ibí yìí? A kó ara wa jọ! Jẹ́ kí a sálọ sí ìlú olódi kí a sì ṣègbé síbẹ̀. Nítorí tí Olúwa Ọlọ́run wa ti pinnu pé a ó ṣègbé. Yóò sì fún wa ní omi onímájèlé mu, nítorí àwa ti ṣẹ̀ sí i.
15 我們指望平安, 卻得不着好處; 指望痊癒的時候, 不料,受了驚惶。
Àwa ń retí àlàáfíà kò sí ìre kan, tí ó wá ní ìgbà ìmúláradá bí kò ṣe ìpayà nìkan.
16 聽見從但那裏敵人的馬噴鼻氣, 他的壯馬發嘶聲, 全地就都震動; 因為他們來吞滅這地和其上所有的, 吞滅這城與其中的居民。
Ìró ìfọn imú ẹṣin àwọn ọlọ̀tẹ̀ là ń gbọ́ láti Dani, yíyan àwọn akọ ẹṣin mú gbogbo ilẹ̀ wárìrì. Wọ́n wá láti pa ilẹ̀ náà run, gbogbo ohun tó wà níbẹ̀, ìlú náà àti gbogbo olùgbé ibẹ̀.
17 看哪,我必使毒蛇到你們中間, 是不服法術的, 必咬你們。 這是耶和華說的。
“Wò ó, èmi yóò rán àwọn ejò olóró sí àárín yín, paramọ́lẹ̀ tí ẹ kò lè pa oró wọn, yóò sì bù yín jẹ,” ni Olúwa wí.
Olùtùnú mi, nígbà tí ìbànújẹ́ ọkàn mi, rẹ̀wẹ̀sì nínú mi.
19 聽啊,是我百姓的哀聲從極遠之地而來, 說:耶和華不在錫安嗎? 錫安的王不在其中嗎? 耶和華說:他們為甚麼以雕刻的偶像 和外邦虛無的神惹我發怒呢?
Fetí sí ẹkún àwọn ènìyàn mi láti ilẹ̀ jíjìnnà wá: “Olúwa kò ha sí ní Sioni bí? Ọba rẹ̀ kò sí níbẹ̀ mọ́ ni?” “Èéṣe tí wọ́n fi mú mi bínú pẹ̀lú ère wọn, pẹ̀lú àwọn òrìṣà àjèjì tí wọn kò níláárí?”
“Ìkórè ti rékọjá, ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ti parí, síbẹ̀ a kò gbà wá là.”
21 先知說:因我百姓的損傷, 我也受了損傷。 我哀痛,驚惶將我抓住。
Níwọ́n ìgbà tí a pa àwọn ènìyàn mi run, èmi náà run pẹ̀lú, èmi ṣọ̀fọ̀, ìrora sì mú mi káká.
22 在基列豈沒有乳香呢? 在那裏豈沒有醫生呢? 我百姓為何不得痊癒呢?
Kò ha sí ìkunra ní Gileadi bí? Kò ha sí àwọn oníṣègùn níbẹ̀? Kí ló ha dé tí kò fi sí ìwòsàn fún ọgbẹ́ àwọn ènìyàn mi?