< 以斯拉記 2 >
1 巴比倫王尼布甲尼撒從前擄到巴比倫之猶大省的人,現在他們的子孫從被擄到之地回耶路撒冷和猶大,各歸本城。
Lákòókò náà, wọ̀nyí ni àwọn ènìyàn agbègbè Juda tí ó gòkè wá láti ìgbèkùn láàrín àwọn tí a kó lọ, ẹni tí Nebukadnessari ọba Babeli ti fi agbára mú ní ìgbèkùn lọ sí Babeli (wọ́n padà sí Jerusalẹmu àti Juda, olúkúlùkù sí ìlú rẹ̀.
2 他們是同着所羅巴伯、耶書亞、尼希米、西萊雅、利來雅、末底改、必珊、米斯拔、比革瓦伊、利宏、巴拿回來的。
Àwọn wọ̀nyí bá Serubbabeli, Jeṣua, Nehemiah, Seraiah, Reelaiah, Mordekai, Bilṣani, Mispari, Bigfai, Rehumu àti Baanah wá). Iye àwọn ọkùnrin àwọn ènìyàn Israẹli.
3 以色列人民的數目記在下面:巴錄的子孫二千一百七十二名;
Àwọn ọmọ Paroṣi jẹ́ ẹgbàá ó lé méjìléláàádọ́sàn-án
Ṣefatia jẹ́ òjìdínnírinwó ó lé méjìlá
Arah jẹ́ ẹgbẹ̀rin ó dín mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n
6 巴哈‧摩押的後裔,就是耶書亞和約押的子孫二千八百一十二名;
Pahati-Moabu (láti ipasẹ̀ àwọn ọmọ Jeṣua àti Joabu) jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì àti ẹgbẹ̀rin lé méjìlá
Elamu jẹ́ àádọ́ta lé lẹ́gbẹ̀fà ó lé mẹ́rin
Sattu jẹ́ ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rún ó lé márùn-ún
Sakkai jẹ́ òjìdínlẹ́gbẹ̀rin
Bani jẹ́ òjìlélẹ́gbẹ̀ta ó lé méjì
Bebai jẹ́ ẹgbẹ̀ta ó lé mẹ́tàlélógún
Asgadi jẹ́ ẹgbẹ̀fà ó lé méjìlélógún
Adonikami jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́fà
Bigfai jẹ́ ẹgbàá ó lé mẹ́rìndínlọ́gọ́ta
Adini jẹ́ àádọ́ta lé ní irinwó ó lé mẹ́rin
Ateri (nípasẹ̀ Hesekiah) jẹ́ méjìdínlọ́gọ́run
Besai jẹ́ ọrùndínnírinwó ó lé mẹ́ta
Haṣumu jẹ́ igba ó lé mẹ́tàlélógún
Gibbari jẹ́ márùndínlọ́gọ́rùn.
Àwọn ọmọ Bẹtilẹhẹmu jẹ́ mẹ́tàlélọ́gọ́fà
Netofa jẹ́ mẹ́rìndínlọ́gọ́ta
Anatoti jẹ́ méjìdínláàádóje
Asmafeti jẹ́ méjìlélógójì
25 基列‧耶琳人、基非拉人、比錄人共七百四十三名;
Kiriati-Jearimu, Kefira àti Beeroti jẹ́ ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rin ó lé mẹ́ta
Rama àti Geba jẹ́ ẹgbẹ̀ta ó lé mọ́kànlélógún
Mikmasi jẹ́ méjìlélọ́gọ́fà
Beteli àti Ai jẹ́ igba ó lé mẹ́tàlélógún
Magbiṣi jẹ́ mẹ́rìndínlọ́gọ́jọ
Elamu mìíràn jẹ́ ẹgbẹ̀fà ó lé mẹ́rìnléláàádọ́ta
Harimu jẹ́ ọ̀rìndínnírinwó.
Lodi, Hadidi àti Ono jẹ́ ọ̀rìndínlẹ́gbẹ̀rin ó lé márùn-ún
Jeriko jẹ́ ọ̀tàdínnírinwó ó lé márùn-ún
Senaa jẹ́ egbèji dín lógún ó lé ọgbọ̀n.
Àwọn àlùfáà. Àwọn ọmọ Jedaiah (láti ipasẹ̀ ìdílé Jeṣua) jẹ́ ogún dín lẹ́gbẹ̀rin ó dín méje
Immeri jẹ́ àádọ́ta lé lẹ́gbẹ̀rún ó lé méjì
Paṣuri jẹ́ ẹgbẹ̀fà ó lé mẹ́tàdínláàádọ́ta
Harimu jẹ́ ẹgbẹ̀rún ó lé mẹ́tàdínlógún.
40 利未人:何達威雅的後裔,就是耶書亞和甲篾的子孫七十四名。
Àwọn ọmọ Lefi. Àwọn ọmọ Jeṣua àti Kadmieli (ti ìdílé Hodafiah) jẹ́ mẹ́rìnléláàádọ́rin.
Àwọn akọrin. Àwọn ọmọ Asafu jẹ́ méjìdínláàádóje.
42 守門的:沙龍的子孫、亞特的子孫、達們的子孫、亞谷的子孫、哈底大的子孫、朔拜的子孫,共一百三十九名。
Àwọn aṣọ́bodè. Àwọn ará Ṣallumu, Ateri, Talmoni, Akkubu, Hatita àti Ṣobai jẹ́ mọ́kàndínlógóje.
43 尼提寧:西哈的子孫、哈蘇巴的子孫、答巴俄的子孫、
Àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili. Àwọn ọmọ. Siha, Hasufa, Tabboati,
55 所羅門僕人的後裔,就是瑣太的子孫、瑣斐列的子孫、比路大的子孫、
Àwọn ọmọ àwọn ìránṣẹ́ Solomoni. Àwọn ọmọ Sotai, Sofereti, Peruda,
57 示法提雅的子孫、哈替的子孫、玻黑列‧哈斯巴音的子孫、亞米的子孫。
Ṣefatia, àwọn ọmọ Hattili, Pokereti ti Haṣebaimu àti àwọn ọmọ Ami.
Àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili àti àwọn ọmọ àwọn ìránṣẹ́ Solomoni jẹ́ irinwó ó dín mẹ́jọ.
59 從特‧米拉、特‧哈薩、基綠、押但、音麥上來的,不能指明他們的宗族譜系是以色列人不是;
Àwọn wọ̀nyí gòkè wá láti àwọn ìlú ti Teli-Mela, Teli-Harṣa, Kerubu, Addoni àti Immeri, ṣùgbọ́n wọn kò lè sọ pẹ̀lú ìdánilójú pé ìdílé àwọn wá láti ara ìran ẹ̀yà Israẹli.
60 他們是第來雅的子孫、多比雅的子孫、尼哥大的子孫,共六百五十二名。
Àwọn ọmọ Delaiah, Tobiah àti Nekoda jẹ́ àádọ́ta lé lẹ́gbẹ̀ta ó lé méjì.
61 祭司中,哈巴雅的子孫、哈哥斯的子孫、巴西萊的子孫;因為他們的先祖娶了基列人巴西萊的女兒為妻,所以起名叫巴西萊。
Àti nínú àwọn ọmọ àwọn àlùfáà. Àwọn ọmọ: Hobaiah, Hakosi àti Barsillai (ọkùnrin tí ó fẹ́ ọmọbìnrin Barsillai ará Gileadi a sì ń fi orúkọ náà pè é).
62 這三家的人在族譜之中尋查自己的譜系,卻尋不着,因此算為不潔,不准供祭司的職任。
Àwọn wọ̀nyí wá ìwé ìrántí ìdílé wọn, ṣùgbọ́n wọn kò rí i, bẹ́ẹ̀ ni a kò kà wọ́n kún ara àlùfáà nítorí, a kà wọ́n sí aláìmọ́.
63 省長對他們說:「不可吃至聖的物,直到有用烏陵和土明決疑的祭司興起來。」
Baálẹ̀ pa á láṣẹ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ jẹ nínú oúnjẹ mímọ́ jùlọ títí tí àlùfáà kan yóò fi ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ pẹ̀lú Urimu àti Tumimu.
Gbogbo ìjọ ènìyàn náà jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlélógún ó lé òjìdínnírinwó.
65 此外,還有他們的僕婢七千三百三十七名,又有歌唱的男女二百名。
Yàtọ̀ sí ẹgbẹ̀rin dín lẹ́gbàárin ó dín mẹ́tàlélọ́gọ́ta ìránṣẹ́ ọkùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin; wọ́n ní igba akọrin ọkùnrin àti obìnrin.
Wọ́n ní ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rin ó dín mẹ́rin ẹṣin; ìbáaka òjìlélúgba ó lé márùn-ún,
ràkunmí jẹ́ irinwó ó lé márùndínlógójì àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹgbẹ̀rin lé lọ́gbọ̀n ó dín ọgọ́rin.
68 有些族長到了耶路撒冷耶和華殿的地方,便為上帝的殿甘心獻上禮物,要重新建造。
Ní ìgbà tí wọ́n dé ilé Olúwa ní Jerusalẹmu, díẹ̀ nínú àwọn olórí àwọn ìdílé fi ọrẹ àtinúwá sílẹ̀ fún ṣíṣe àtúnkọ́ ilé Ọlọ́run ní ààyè rẹ̀.
69 他們量力捐入工程庫的金子六萬一千達利克,銀子五千彌拿,並祭司的禮服一百件。
Gẹ́gẹ́ bí agbára wọn, wọ́n fún ilé ìṣúra fún iṣẹ́ yìí ní ọ̀kẹ́ mẹ́ta ó lé lẹ́gbẹ̀rún ìwọ̀n dariki wúrà, ẹgbẹ̀rún márùn-ún fàdákà àti ọgọ́rùn-ún ẹ̀wù àlùfáà.
70 於是祭司、利未人、民中的一些人、歌唱的、守門的、尼提寧,並以色列眾人,各住在自己的城裏。
Àwọn àlùfáà, àwọn ará Lefi, àwọn akọrin, àwọn aṣọ́bodè àti àwọn ìránṣẹ́ ilé Olúwa ṣe àtìpó sínú àwọn ìlú wọn, pẹ̀lú àwọn ènìyàn mìíràn, àti ìyókù àwọn ọmọ Israẹli ṣe àtìpó sínú ìlú u wọn.