< 以西結書 7 >

1 耶和華的話又臨到我說:
Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:
2 「人子啊,主耶和華對以色列地如此說:結局到了,結局到了地的四境!
“Ọmọ ènìyàn, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí sí ilé Israẹli: “‘Òpin! Òpin ti dé sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ náà!
3 現在你的結局已經臨到,我必使我的怒氣歸與你,也必按你的行為審判你,照你一切可憎的事刑罰你。
Òpin tí dé sí ọ báyìí, èmi yóò sì tú ìbínú mi jáde sí ọ, èmi yóò dájọ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ìwà rẹ, èmi yóò sì san án fún ọ gẹ́gẹ́ bí gbogbo ìwà ìríra rẹ.
4 我眼必不顧惜你,也不可憐你,卻要按你所行的報應你,照你中間可憎的事刑罰你。你就知道我是耶和華。
Ojú mi kò ní i dá ọ sì, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò ṣàánú; ṣùgbọ́n èmi yóò san án fún ọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ àti gbogbo ìwà ìríra tó wà láàrín rẹ. Nígbà náà ní ẹ̀yin yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.’
5 「主耶和華如此說:有一災,獨有一災;看哪,臨近了!
“Èyí ni Olúwa Olódùmarè wí: “‘Ibi! Ibi kan ṣoṣo. Kíyèsi, ó bọ̀ ní orí rẹ!
6 結局來了,結局來了,向你興起。看哪,來到了!
Òpin ti dé! Òpin ti dé! Ó ti dìde lòdì sí ọ. Kíyèsi, ó ti dé!
7 境內的居民哪,所定的災臨到你,時候到了,日子近了,乃是鬨嚷並非在山上歡呼的日子。
Ìparun ti dé sórí rẹ, ìwọ tó ń gbé ní ilẹ̀ náà. Àkókò náà dé! Ọjọ́ wàhálà ti súnmọ́ etílé! Kì í ṣe ọjọ́ ariwo ayọ̀ lórí òkè.
8 我快要將我的忿怒傾在你身上,向你成就我怒中所定的,按你的行為審判你,照你一切可憎的事刑罰你。
Mo ṣetán láti tú ìbínú gbígbóná mi lé ọ lórí àti láti lo ìbínú mi lórí rẹ gẹ́gẹ́ bí gbogbo ọ̀nà rẹ, èmi yóò sì dá ọ lẹ́jọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ àti gẹ́gẹ́ bí ìwà ìríra rẹ ni èmi yóò sì san án fún ọ.
9 我眼必不顧惜你,也不可憐你,必按你所行的報應你,照你中間可憎的事刑罰你。你就知道擊打你的是我耶和華。
Ojú mi kò ní i dá ọ sí, Èmi kò sì ní wò ọ́ pẹ̀lú àánú; èmi yóò san án fún ọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ àti fún gbogbo ìwà ìríra tí wà láàrín rẹ. “‘Nígbà náà ní ẹ o mọ̀ pé Èmi Olúwa lo kọlù yín.
10 「看哪,看哪,日子快到了;所定的災已經發出!杖已經開花,驕傲已經發芽。
“‘Ọjọ́ náà dé! Kíyèsi ó ti dé! Ìparun ti bú jáde, ọ̀pá ti tanná, ìgbéraga ti rúdí!
11 強暴興起,成了罰惡的杖。以色列人,或是他們的群眾,或是他們的財寶,無一存留;他們中間也沒有得尊榮的。
Ìwà ipá ti di ọ̀pá ìwà búburú; ọ̀pá láti jẹ ẹni búburú ní ìyà. Kò sí nínú wọn tí yóò ṣẹ́kù, tàbí nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn, kò sí nínú ọrọ̀ wọn, kò sí ohun tí ó ní iye.
12 時候到了,日子近了,買主不可歡喜,賣主不可愁煩,因為烈怒已經臨到他們眾人身上。
Àkókò náà dé! Ọjọ́ náà ti dé! Kí òǹrajà má ṣe yọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ki òǹtajà má ṣe ṣọ̀fọ̀; nítorí, ìbínú gbígbóná wà lórí gbogbo ènìyàn.
13 賣主雖然存活,卻不能歸回再得所賣的,因為這異象關乎他們眾人。誰都不得歸回,也沒有人在他的罪孽中堅立自己。」
Nítorí pé òǹtajà kì yóò rí gbà padà dúkìá èyí tó tà níwọ̀n ìgbà ti àwọn méjèèjì bá wà láààyè. Nítorí ìran tó kan gbogbo ènìyàn yìí kò ní yí padà. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, kò sí ọ̀kan nínú wọn tí yóò gba ara rẹ̀ là.
14 「他們已經吹角,預備齊全,卻無一人出戰,因為我的烈怒臨到他們眾人身上。
“‘Wọ́n ti fọn ìpè ogun, tí wọ́n sì pèsè ohun gbogbo sílẹ̀, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí yóò lọ ojú ogun, nítorí ìbínú gbígbóná mi ti wà lórí gbogbo ènìyàn.
15 在外有刀劍;在內有瘟疫、饑荒。在田野的,必遭刀劍而死;在城中的,必有饑荒、瘟疫吞滅他。
Idà wà ní ìta, àjàkálẹ̀-ààrùn àti ìyàn wà nílé, idà yóò pa ẹni tó bá wà ní orílẹ̀-èdè, àjàkálẹ̀-ààrùn àti ìyàn yóò pa ẹni tó bá wà ní ìlú.
16 其中所逃脫的就必逃脫,各人因自己的罪孽在山上發出悲聲,好像谷中的鴿子哀鳴。
Gbogbo àwọn tí ó bọ́ nínú wọn yóò sálà, wọn yóò sì wà lórí òkè. Bí i àdàbà inú àfonífojì, gbogbo wọn yóò máa ṣọ̀fọ̀, olúkúlùkù nítorí àìṣedéédéé rẹ̀.
17 手都發軟,膝弱如水。
Gbogbo ọwọ́ yóò rọ, gbogbo orúnkún yóò di aláìlágbára bí omi.
18 要用麻布束腰,被戰兢所蓋;各人臉上羞愧,頭上光禿。
Wọn yóò wọ aṣọ ọ̀fọ̀, ẹ̀rù yóò sì bò wọ́n mọ́lẹ̀, ìtìjú yóò mù wọn, wọn yóò sì fá irun wọn.
19 他們要將銀子拋在街上,金子看如污穢之物。當耶和華發怒的日子,他們的金銀不能救他們,不能使心裏知足,也不能使肚腹飽滿,因為這金銀作了他們罪孽的絆腳石。
“‘Wọn yóò dà fàdákà wọn sí ojú pópó, wúrà wọn yóò sì dàbí èérí fàdákà àti wúrà wọn kò ní le gbà wọ́n ní ọjọ́ ìbínú gbígbóná Olúwa. Wọn kò ní le jẹun tẹ́ ra wọn lọ́rùn tàbí kí wọn kún ikùn wọn pẹ̀lú oúnjẹ nítorí pé ó ti di ohun ìkọ̀sẹ̀ fún wọn.
20 論到耶和華妝飾華美的殿,他建立得威嚴,他們卻在其中製造可憎可厭的偶像,所以這殿我使他們看如污穢之物。
Wọ́n ń ṣe ìgbéraga pẹ̀lú ohun ọ̀ṣọ́ wọn tí ó lẹ́wà, wọn sì ti fi ṣe òrìṣà, wọn sì tún ya àwòrán ìríra wọn níbẹ̀. Nítorí náà, èmi yóò sọ àwọn nǹkan wọ̀nyí di aláìmọ́ fún wọn.
21 我必將這殿交付外邦人為掠物,交付地上的惡人為擄物;他們也必褻瀆這殿。
Èmi yóò sì fi àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣe ìjẹ fún àjèjì àti ìkógun fún àwọn ènìyàn búburú ayé, wọn yóò sì sọ ọ́ di aláìmọ́.
22 我必轉臉不顧以色列人,他們褻瀆我隱密之所,強盜也必進去褻瀆。
Èmi yóò gbójú mi kúrò lára wọn, àwọn ọlọ́ṣà yóò sì sọ ibi ìṣúra mi di aláìmọ́; àwọn ọlọ́ṣà yóò wọ inú rẹ̀, wọn yóò sì bà á jẹ́.
23 「要製造鎖鍊;因為這地遍滿流血的罪,城邑充滿強暴的事。
“‘Rọ ẹ̀wọ̀n irin! Nítorí pé ilẹ̀ náà kún fún ẹ̀ṣẹ̀ ìtàjẹ̀ sílẹ̀, ìlú náà sí kún fún ìwà ipá.
24 所以,我必使列國中最惡的人來佔據他們的房屋;我必使強暴人的驕傲止息,他們的聖所都要被褻瀆。
Èmi yóò mú kí orílẹ̀-èdè ti ó búburú jùlọ láti jogún ilé wọn. Èmi yóò sì fi òpin sí ìgbéraga àwọn alágbára, ibi mímọ́ wọn yóò sì di bíbàjẹ́.
25 毀滅臨近了;他們要求平安,卻無平安可得。
Nígbà tí ìpayà bá dé, wọn yóò wá àlàáfíà, lórí asán.
26 災害加上災害,風聲接連風聲;他們必向先知求異象,但祭司講的律法、長老設的謀略都必斷絕。
Wàhálà lórí wàhálà yóò dé, ìdágìrì lórí ìdágìrì. Nígbà náà ni wọn yóò wá ìran lọ́dọ̀ wòlíì, ṣùgbọ́n ẹ̀kọ́ òfin yóò parun lọ́dọ̀ àlùfáà, bẹ́ẹ̀ ni ìmọ̀ràn yóò ṣègbé lọ́dọ̀ àwọn àgbàgbà.
27 君要悲哀,王要披淒涼為衣,國民的手都發顫。我必照他們的行為待他們,按他們應得的審判他們,他們就知道我是耶和華。」
Ọba yóò ṣọ̀fọ̀, ọmọ-aládé yóò wà láìní ìrètí, ọwọ́ àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà yóò wárìrì. Èmi yóò ṣe é fún wọn gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn, èmi yóò ṣe ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìgbékalẹ̀ wọn. Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé èmi ní Olúwa.’”

< 以西結書 7 >