< 歷代志下 15 >

1 上帝的靈感動俄德的兒子亞撒利雅。
Ẹ̀mí Ọlọ́run wá sórí Asariah ọmọ Odedi.
2 他出來迎接亞撒,對他說:「亞撒和猶大、便雅憫眾人哪,要聽我說:你們若順從耶和華,耶和華必與你們同在;你們若尋求他,就必尋見;你們若離棄他,他必離棄你們。
Ó jáde lọ bá Asa, ó sì wí fún un pé, “Tẹ́tí si mi Asa, àti gbogbo Juda àti Benjamini. Olúwa wà pẹ̀lú rẹ, nígbà tí ìwọ bá wà pẹ̀lú rẹ̀. Ti ìwọ bá wá a, ìwọ yóò rí i ní ẹ̀bá ọ̀dọ̀ rẹ ṣùgbọ́n tí ìwọ bá kọ̀ ọ́ sílẹ̀, òun yóò kọ̀ ọ́ sílẹ̀.
3 以色列人不信真神,沒有訓誨的祭司,也沒有律法,已經好久了;
Fún ọjọ́ pípẹ́ ni Israẹli ti wà láì sin Ọlọ́run òtítọ́, àti láìní àlùfáà ti ń kọ́ ni, àti láìní òfin.
4 但他們在急難的時候歸向耶和華-以色列的上帝,尋求他,他就被他們尋見。
Ṣùgbọ́n nínú ìpọ́njú wọn, wọ́n yí padà si Olúwa Ọlọ́run Israẹli, wọ́n sì wa kiri. Wọ́n sì ri i ní ẹ̀gbẹ́ wọn.
5 那時,出入的人不得平安,列國的居民都遭大亂;
Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì ó léwu kí ènìyàn máa rìn ìrìnàjò kiri, nítorí tí gbogbo àwọn olùgbé ilẹ̀ náà wà nínú làálàá ńlá.
6 這國攻擊那國,這城攻擊那城,互相破壞,因為上帝用各樣災難擾亂他們。
Orílẹ̀-èdè kan ń run èkejì àti ìlú kan sí òmíràn nítorí Ọlọ́run ń yọ wọ́n lẹ́nu pẹ̀lú oríṣìíríṣìí ìpọ́njú.
7 現在你們要剛強,不要手軟,因你們所行的必得賞賜。」
Ṣùgbọ́n fun ìwọ, jẹ́ alágbára, kí ó má sì ṣe ṣàárẹ̀. Nítorí tí a ó fi èrè sí iṣẹ́ ẹ̀ rẹ.”
8 亞撒聽見這話和俄德兒子先知亞撒利雅的預言,就壯起膽來,在猶大、便雅憫全地,並以法蓮山地所奪的各城,將可憎之物盡都除掉,又在耶和華殿的廊前重新修築耶和華的壇;
Nígbà tí Asa gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí àti àsọtẹ́lẹ̀ Asariah ọmọ Odedi wòlíì, ó mú àyà rẹ̀ le. Ó sì mú gbogbo ohun ìríra kúrò ní gbogbo ilẹ̀ Juda àti Benjamini àti kúrò nínú àwọn ìlú tí ó ti fi agbára mú ní orí òkè Efraimu. Ó tún pẹpẹ Olúwa ṣe tí ó wà ní iwájú portiko ti ilé Olúwa.
9 又招聚猶大、便雅憫的眾人,並他們中間寄居的以法蓮人、瑪拿西人、西緬人。有許多以色列人歸降亞撒,因見耶和華-他的上帝與他同在。
Nígbà náà, ó pe gbogbo Juda àti Benjamini jọ àti àwọn ènìyàn láti Efraimu, Manase àti Simeoni tí ó ti ṣe àtìpó ní àárín wọn. Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn ti wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti Israẹli nígbà tí wọ́n rí i wí pé Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀.
10 亞撒十五年三月,他們都聚集在耶路撒冷。
Wọ́n péjọ sí Jerusalẹmu ní oṣù kẹta ọdún kẹ́ẹ̀dógún ti ìjọba Asa.
11 當日他們從所取的擄物中,將牛七百隻、羊七千隻獻給耶和華。
Ní àkókò yìí, wọ́n rú ẹbọ sí Olúwa ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin akọ màlúù àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin àgùntàn àti àwọn ewúrẹ́ láti ibi ìkógun tí wọ́n ti kó padà.
12 他們就立約,要盡心盡性地尋求耶和華-他們列祖的上帝。
Wọ́n sì tún dá májẹ̀mú láti wá Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn tinútinú wọn àti tọkàntọkàn wọn.
13 凡不尋求耶和華-以色列上帝的,無論大小、男女,必被治死。
Pé ẹnikẹ́ni tí kò bá wá Olúwa Ọlọ́run Israẹli, pípa ni á ó pa á láti ẹni kékeré dé orí ẹni ńlá àti ọkùnrin àti obìnrin.
14 他們就大聲歡呼,吹號吹角,向耶和華起誓。
Wọ́n sì búra ní ohùn rara fún Olúwa àti pẹ̀lú ìhó ńlá àti pẹ̀lú ìpè àti pẹ̀lú fèrè.
15 猶大眾人為所起的誓歡喜;因他們是盡心起誓,盡意尋求耶和華,耶和華就被他們尋見,且賜他們四境平安。
Gbogbo Juda yọ̀ nípa ìbúra náà nítorí wọ́n ti búra tinútinú wọn wọ́n sì fi gbogbo ìfẹ́ inú wọn wá a, wọ́n sì rí i, Olúwa sì fún wọn ní ìsinmi yí káàkiri.
16 亞撒王貶了他祖母瑪迦太后的位,因她造了可憎的偶像亞舍拉。亞撒砍下她的偶像,搗得粉碎,燒在汲淪溪邊。
Ọba Asa sì mú Maaka ìyá ńlá rẹ̀ kúrò láti máa ṣe ayaba, nítorí tí ó yá ère kan fún Aṣerah òrìṣà rẹ̀. Asa sì ké ère náà lulẹ̀, ó sì jó o ní àfonífojì Kidironi.
17 只是邱壇還沒有從以色列中廢去,然而亞撒的心一生誠實。
Ṣùgbọ́n a kò mú àwọn ibi gíga náà kúrò ní Israẹli; síbẹ̀síbẹ̀ ọkàn Asa wà ní pípé ní ọjọ́ rẹ̀ gbogbo.
18 亞撒將他父所分別為聖、與自己所分別為聖的金銀和器皿都奉到上帝的殿裏。
Ó sì mú àwọn ohun mímọ́ náà ti baba rẹ̀ àti àwọn ohun mímọ́ ti òun tìkára rẹ̀ tirẹ̀ wá sínú ilé Ọlọ́run, wúrà àti fàdákà àti àwọn ohun èlò náà.
19 從這時直到亞撒三十五年,都沒有爭戰的事。
Kò sí ogun mọ́ títí fún ọdún márùndínlógójì ti ìjọba Asa.

< 歷代志下 15 >