< 列王紀上 18 >

1 過了許久,到第三年,耶和華的話臨到以利亞說:「你去,使亞哈得見你;我要降雨在地上。」
Ó sì ṣe, lẹ́yìn ọjọ́ púpọ̀, ní ọdún kẹta, ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Elijah wá pé, “Lọ, kí o sì fi ara rẹ̀ hàn fún Ahabu, èmi yóò sì rọ òjò sórí ilẹ̀.”
2 以利亞就去,要使亞哈得見他。那時,撒馬利亞有大饑荒;
Bẹ́ẹ̀ ni Elijah lọ fi ara rẹ̀ han Ahabu. Ìyàn ńlá sì mú ní Samaria,
3 亞哈將他的家宰俄巴底召了來。(俄巴底甚是敬畏耶和華,
Ahabu sì ti pe Obadiah, ẹni tí ń ṣe olórí ilé rẹ̀. Obadiah sì bẹ̀rù Olúwa gidigidi.
4 耶洗別殺耶和華眾先知的時候,俄巴底將一百個先知藏了,每五十人藏在一個洞裏,拿餅和水供養他們。)
Nígbà tí Jesebeli sì ń pa àwọn wòlíì Olúwa kúrò, Obadiah sì mú ọgọ́rùn-ún wòlíì, ó sì fi wọ́n pamọ́ sínú ihò òkúta, àádọ́ta ní ihò kọ̀ọ̀kan, ó sì fi àkàrà pẹ̀lú omi bọ́ wọn.
5 亞哈對俄巴底說:「我們走遍這地,到一切水泉旁和一切溪邊,或者找得着青草,可以救活騾馬,免得絕了牲畜。」
Ahabu sì ti wí fún Obadiah pé, “Lọ sí gbogbo ilẹ̀ sí orísun omi gbogbo àti sí ilẹ̀ gbogbo. Bóyá àwa lè rí koríko láti gba àwọn ẹṣin àti àwọn ìbáaka là, kí a má bá à ṣòfò àwọn ẹranko pátápátá.”
6 於是二人分地遊行,亞哈獨走一路,俄巴底獨走一路。
Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì pín ilẹ̀ tí wọ́n fẹ́ dé láàrín ara wọn, Ahabu gba ọ̀nà kan lọ, Obadiah sì gba ọ̀nà mìíràn lọ.
7 俄巴底在路上恰與以利亞相遇,俄巴底認出他來,就俯伏在地,說:「你是我主以利亞不是?」
Bí Obadiah sì ti ń rìn lọ, Elijah sì pàdé rẹ̀. Obadiah sì mọ̀ ọ́n, ó dojúbolẹ̀, ó sì wí pé, “Ǹjẹ́ ìwọ ni nítòótọ́, Elijah, olúwa mi?”
8 回答說:「是。你去告訴你主人說,以利亞在這裏。」
Elijah sì dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, lọ kí o sọ fún olúwa rẹ pé, ‘Elijah ń bẹ níhìn-ín.’”
9 俄巴底說:「僕人有甚麼罪,你竟要將我交在亞哈手裏,使他殺我呢?
Obadiah sì béèrè pé, “Ẹ̀ṣẹ̀ kí ni mo ha dá tí ìwọ fi ń fi ìránṣẹ́ rẹ lé Ahabu lọ́wọ́ láti pa?
10 我指着永生耶和華-你的上帝起誓,無論哪一邦哪一國,我主都打發人去找你。若說你沒有在那裏,就必使那邦那國的人起誓說,實在是找不着你。
Mo mọ̀ dájú pé bí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti ń bẹ, kò sí orílẹ̀-èdè tàbí ìjọba kan tí olúwa mi kò ti rán ènìyàn lọ láti wò ọ́. Àti nígbà tí orílẹ̀-èdè tàbí ìjọba kan bá wí pé o kò sí, òun a sì mú kí wọ́n búra wí pé wọn kò rí ọ.
11 現在你說,要去告訴你主人說,以利亞在這裏;
Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ìwọ wí fún mi pé kí n lọ sọ́dọ̀ olúwa mi, kí n sì wí pé, ‘Elijah ń bẹ níhìn-ín.’
12 恐怕我一離開你,耶和華的靈就提你到我所不知道的地方去。這樣,我去告訴亞哈,他若找不着你,就必殺我;僕人卻是自幼敬畏耶和華的。
Èmi kò sì mọ ibi tí ẹ̀mí Olúwa yóò gbé ọ lọ nígbà tí mo bá fi ọ́ sílẹ̀. Bí mo bá lọ, tí mo sì sọ fún Ahabu, tí kò sì rí ọ, òun a sì pa mí. Síbẹ̀ èmi ìránṣẹ́ rẹ bẹ̀rù Olúwa láti ìgbà èwe mi wá.
13 耶洗別殺耶和華眾先知的時候,我將耶和華的一百個先知藏了,每五十人藏在一個洞裏,拿餅和水供養他們,豈沒有人將這事告訴我主嗎?
Ṣé Olúwa mi kò ha ti gbọ́ ohun tí mo ṣe nígbà tí Jesebeli ń pa àwọn wòlíì Olúwa? Mo fi ọgọ́rùn-ún wòlíì Olúwa pamọ́ sínú ihò òkúta méjì, àràádọ́ta ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, mo sì fi omi àti oúnjẹ bọ́ wọn.
14 現在你說,要去告訴你主人說,以利亞在這裏,他必殺我。」
Ìwọ sì sọ fún mi nísinsin yìí pé, kí n tọ olúwa mi lọ pé, ‘Elijah ń bẹ níhìn-ín.’ Òun a sì pa mí!”
15 以利亞說:「我指着所事奉永生的萬軍之耶和華起誓,我今日必使亞哈得見我。」
Elijah sì wí pé, “Bí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti wà, ẹni tí èmi ń sìn, nítòótọ́ èmi yóò fi ara mi hàn fún Ahabu lónìí.”
16 於是俄巴底去迎着亞哈,告訴他;亞哈就去迎着以利亞。
Bẹ́ẹ̀ ni Obadiah sì lọ láti pàdé Ahabu, ó sì sọ fún un, Ahabu sì lọ láti pàdé Elijah.
17 亞哈見了以利亞,便說:「使以色列遭災的就是你嗎?」
Nígbà tí Ahabu sì rí Elijah, ó sì wí fún un pé, “Ṣé ìwọ nìyìí, ìwọ tí ń yọ Israẹli lẹ́nu?”
18 以利亞說:「使以色列遭災的不是我,乃是你和你父家;因為你們離棄耶和華的誡命,去隨從巴力。
Elijah sì dá a lóhùn pé, “Èmi kò yọ Israẹli lẹ́nu, bí kò ṣe ìwọ àti ilé baba rẹ. Ẹ ti kọ òfin Olúwa sílẹ̀, ẹ sì ń tọ Baali lẹ́yìn.
19 現在你當差遣人,招聚以色列眾人和事奉巴力的那四百五十個先知,並耶洗別所供養事奉亞舍拉的那四百個先知,使他們都上迦密山去見我。」
Nísinsin yìí kó gbogbo Israẹli jọ láti pàdé mi lórí òkè Karmeli. Àti kí o sì mú àádọ́ta lé ní irinwó àwọn wòlíì Baali àti irinwó àwọn wòlíì òrìṣà Aṣerah tí wọ́n ń jẹun ní tábìlì Jesebeli.”
20 亞哈就差遣人招聚以色列眾人和先知都上迦密山。
Bẹ́ẹ̀ ni Ahabu ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, ó sì kó àwọn wòlíì jọ sí orí òkè Karmeli.
21 以利亞前來對眾民說:「你們心持兩意要到幾時呢?若耶和華是上帝,就當順從耶和華;若巴力是上帝,就當順從巴力。」眾民一言不答。
Elijah sì lọ síwájú gbogbo àwọn ènìyàn, ó sì wí pé, “Yóò ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin yóò máa ṣiyèméjì? Bí Olúwa bá ni Ọlọ́run, ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ṣùgbọ́n bí Baali bá ni Ọlọ́run, ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.” Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà kò sì wí ohun kan.
22 以利亞對眾民說:「作耶和華先知的只剩下我一個人;巴力的先知卻有四百五十個人。
Nígbà náà ni Elijah wí fún wọn pé, “Èmi nìkan ṣoṣo ni ó kù ní wòlíì Olúwa, ṣùgbọ́n, àádọ́ta lé ní irinwó ni wòlíì Baali.
23 當給我們兩隻牛犢,巴力的先知可以挑選一隻,切成塊子,放在柴上,不要點火;我也預備一隻牛犢放在柴上,也不點火。
Ẹ fún wa ní ẹgbọrọ akọ màlúù méjì. Jẹ́ kí wọn kí ó sì yan ẹgbọrọ akọ màlúù kan fún ara wọn, kí wọn kí ó sì gé e sí wẹ́wẹ́, kí wọn kí ó sì tò ó sí orí igi, kí wọn kí ó má ṣe fi iná sí i. Èmi yóò sì tún ẹgbọrọ akọ màlúù kejì ṣe, èmi yóò sì tò ó sórí igi, èmi kì yóò sì fi iná sí i.
24 你們求告你們神的名,我也求告耶和華的名。那降火顯應的神,就是上帝。」眾民回答說:「這話甚好。」
Nígbà náà ẹ ó sì ké pe orúkọ àwọn Ọlọ́run yín, èmi yóò sì ké pe orúkọ Olúwa. Ọlọ́run náà tí ó fi iná dáhùn, òun ni Ọlọ́run.” Nígbà náà ni gbogbo àwọn ènìyàn náà sì wí pé, “Ohun tí ìwọ sọ dára.”
25 以利亞對巴力的先知說:「你們既是人多,當先挑選一隻牛犢,預備好了,就求告你們神的名,卻不要點火。」
Elijah sì wí fún àwọn wòlíì Baali wí pé, “Ẹ yan ẹgbọrọ akọ màlúù kan fún ara yín, kí ẹ sì tètè kọ́ ṣe é, nítorí ẹ̀yin pọ̀. Ẹ ké pe orúkọ àwọn ọlọ́run yín, ṣùgbọ́n ẹ má ṣe fi iná sí i.”
26 他們將所得的牛犢預備好了,從早晨到午間,求告巴力的名說:「巴力啊,求你應允我們!」卻沒有聲音,沒有應允的。他們在所築的壇四圍踊跳。
Nígbà náà ni wọ́n sì mú ẹgbọrọ akọ màlúù náà, tí a ti fi fún wọn, wọ́n sì ṣe é. Nígbà náà ni wọ́n sì ké pe orúkọ Baali láti òwúrọ̀ títí di ọ̀sán gangan wí pé, “Baali! Dá wa lóhùn!” Wọ́n sì ń kégbe. Ṣùgbọ́n kò sí ìdáhùn; kò sí ẹnìkan tí ó sì dáhùn. Wọ́n sì jó yí pẹpẹ náà ká, èyí tí wọ́n tẹ́.
27 到了正午,以利亞嬉笑他們,說:「大聲求告吧!因為他是神,他或默想,或走到一邊,或行路,或睡覺,你們當叫醒他。」
Ní ọ̀sán gangan, Elijah bẹ̀rẹ̀ sí ń fi wọ́n ṣe ẹlẹ́yà ó sì wí pé, “Ẹ kígbe lóhùn rara Ọlọ́run sá à ni òun! Bóyá ó ń ṣe àṣàrò, tàbí kò ráyè, tàbí ó re àjò. Bóyá ó sùn, ó yẹ kí a jí i.”
28 他們大聲求告,按着他們的規矩,用刀槍自割、自刺,直到身體流血。
Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì kígbe lóhùn rara, wọ́n sì fi ọ̀bẹ àti ọ̀kọ̀ ya ara wọn gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn, títí tí ẹ̀jẹ̀ fi tú jáde ní ara wọn.
29 從午後直到獻晚祭的時候,他們狂呼亂叫,卻沒有聲音,沒有應允的,也沒有理會的。
Nígbà tí ọjọ́ yẹ àtàrí, wọ́n sì ń fi òmùgọ̀ sọtẹ́lẹ̀ títí di àkókò ìrúbọ àṣálẹ́, ṣùgbọ́n kò sí ohùn, kò sì ṣí ìdáhùn, kò sì ṣí ẹni tí ó kà á sí.
30 以利亞對眾民說:「你們到我這裏來。」眾民就到他那裏。他便重修已經毀壞耶和華的壇。
Nígbà náà ni Elijah wí fún gbogbo àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ súnmọ́ mi.” Wọ́n sì súnmọ́ ọn, ó sì tún pẹpẹ Olúwa tí ó ti wó lulẹ̀ ṣe.
31 以利亞照雅各子孫支派的數目,取了十二塊石頭(耶和華的話曾臨到雅各說:「你的名要叫以色列」),
Elijah sì mú òkúta méjìlá, ọ̀kọ̀ọ̀kan fún ẹ̀yà ọmọ Jakọbu kan, ẹni tí ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ wá wí pé, “Israẹli ni orúkọ rẹ̀ yóò máa jẹ́.”
32 用這些石頭為耶和華的名築一座壇,在壇的四圍挖溝,可容穀種二細亞,
Ó sì tẹ́ pẹpẹ pẹ̀lú àwọn òkúta wọ̀nyí ní orúkọ Olúwa, ó sì wa yàrá yí pẹpẹ náà ká, tí ó lè gba ìwọ̀n òsùwọ̀n irúgbìn méjì.
33 又在壇上擺好了柴,把牛犢切成塊子放在柴上,對眾人說:「你們用四個桶盛滿水,倒在燔祭和柴上」;
Ó sì to igi náà dáradára, ó sì ké ẹgbọrọ akọ màlúù náà wẹ́wẹ́, ó sì tò ó sórí igi. Nígbà náà ni ó sì wí fún wọn wí pé, “Ẹ fi omi kún ìkòkò mẹ́rin, kí ẹ sì tu sórí ẹbọ sísun àti sórí igi náà.”
34 又說:「倒第二次。」他們就倒第二次;又說:「倒第三次。」他們就倒第三次。
Ó sì wí pe, “Ẹ ṣe é ní ìgbà kejì.” Wọ́n sì ṣe é ní ìgbà kejì. Ó sì tún wí pé, “Ṣe é ní ìgbà kẹta.”
35 水流在壇的四圍,溝裏也滿了水。
Omi náà sì sàn yí pẹpẹ náà ká, ó sì fi omi kún yàrá náà pẹ̀lú.
36 到了獻晚祭的時候,先知以利亞近前來,說:「亞伯拉罕、以撒、以色列的上帝,耶和華啊,求你今日使人知道你是以色列的上帝,也知道我是你的僕人,又是奉你的命行這一切事。
Ó sì ṣe, ní ìrúbọ àṣálẹ́, wòlíì Elijah sì súnmọ́ tòsí, ó sì gbàdúrà wí pé, “Olúwa, Ọlọ́run Abrahamu, Isaaki àti Israẹli, jẹ́ kí ó di mí mọ̀ lónìí pé ìwọ ni Ọlọ́run ní Israẹli àti pé èmi ni ìránṣẹ́ rẹ, àti pé mo ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí nípa àṣẹ rẹ.
37 耶和華啊,求你應允我,應允我!使這民知道你-耶和華是上帝,又知道是你叫這民的心回轉。」
Gbọ́ ti èmi, Olúwa, gbọ́ ti èmi, kí àwọn ènìyàn wọ̀nyí lè mọ̀ pé ìwọ Olúwa ni Ọlọ́run àti pé ìwọ tún yí ọkàn wọn padà.”
38 於是,耶和華降下火來,燒盡燔祭、木柴、石頭、塵土,又燒乾溝裏的水。
Nígbà náà ni iná Olúwa bọ́ sílẹ̀, ó sì sun ẹbọ sísun náà àti igi, àti àwọn òkúta, àti erùpẹ̀, ó sì tún lá omi tí ń bẹ nínú yàrá náà.
39 眾民看見了,就俯伏在地,說:「耶和華是上帝!耶和華是上帝!」
Nígbà tí gbogbo àwọn ènìyàn sì rí èyí, wọ́n da ojú wọn bolẹ̀, wọ́n sì kígbe pé, “Olúwa, òun ni Ọlọ́run! Olúwa, òun ni Ọlọ́run!”
40 以利亞對他們說:「拿住巴力的先知,不容一人逃脫!」眾人就拿住他們。以利亞帶他們到基順河邊,在那裏殺了他們。
Nígbà náà ni Elijah sì pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ mú àwọn wòlíì Baali. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọ̀kan nínú wọn kí ó sálọ!” Wọ́n sì mú wọn, Elijah sì mú wọn sọ̀kalẹ̀ sí àfonífojì Kiṣoni, ó sì pa wọ́n níbẹ̀.
41 以利亞對亞哈說:「你現在可以上去吃喝,因為有多雨的響聲了。」
Elijah sì wí fún Ahabu pé, “Lọ, jẹ, kí o sì mu, nítorí ìró ọ̀pọ̀lọpọ̀ òjò ń bọ̀.”
42 亞哈就上去吃喝。以利亞上了迦密山頂,屈身在地,將臉伏在兩膝之中;
Bẹ́ẹ̀ ni Ahabu gòkè lọ láti jẹ àti láti mu. Ṣùgbọ́n Elijah gun orí òkè Karmeli lọ ó sì tẹríba, ó sì fi ojú rẹ̀ sí agbede-méjì eékún rẹ̀.
43 對僕人說:「你上去,向海觀看。」僕人就上去觀看,說:「沒有甚麼。」他說:「你再去觀看。」如此七次。
Ó sì wí fún ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, “Lọ, kí o sì wo ìhà Òkun, òun sì gòkè lọ, ó sì wò.” Ó sì wí pé, “Kò sí nǹkan níbẹ̀.” Ó sì wí pé, “Tún lọ nígbà méje.”
44 第七次僕人說:「我看見有一小片雲從海裏上來,不過如人手那樣大。」以利亞說:「你上去告訴亞哈,當套車下去,免得被雨阻擋。」
Nígbà keje, ìránṣẹ́ náà sì wí pé, “Àwọsánmọ̀ kékeré kan dìde láti inú Òkun, gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ ènìyàn.” Elijah sì wí pé, “Lọ, kí o sọ fún Ahabu pé, ‘Di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ, kí o sì sọ̀kalẹ̀ lọ, kí òjò ó má ba à dá ọ dúró.’”
45 霎時間,天因風雲黑暗,降下大雨。亞哈就坐車往耶斯列去了。
Ó sì ṣe, nígbà díẹ̀ sí i, ọ̀run sì ṣú fún àwọsánmọ̀, ìjì sì dìde, òjò púpọ̀ sì rọ̀, Ahabu sì gun kẹ̀kẹ́ lọ sí Jesreeli.
46 耶和華的靈降在以利亞身上,他就束上腰,奔在亞哈前頭,直到耶斯列的城門。
Agbára Olúwa sì ń bẹ lára Elijah; ó sì di àmùrè ẹ̀gbẹ́ rẹ, ó sì sáré níwájú Ahabu títí dé Jesreeli.

< 列王紀上 18 >