< 诗篇 85 >

1 可拉后裔的诗,交与伶长。 耶和华啊,你已经向你的地施恩, 救回被掳的雅各。
Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu. Ìwọ fi ojúrere hàn fún ilé rẹ, Olúwa; ìwọ mú ohun ìní Jakọbu bọ̀ sí ipò.
2 你赦免了你百姓的罪孽, 遮盖了他们一切的过犯。 (细拉)
Ìwọ dárí àìṣedéédéé àwọn ènìyàn rẹ jì ìwọ sì bó ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀. (Sela)
3 你收转了所发的忿怒 和你猛烈的怒气。
Ìwọ fi àwọn ìbínú rẹ sápá kan ìwọ sì yípadà kúrò nínú ìbínú gbígbóná rẹ.
4 拯救我们的 神啊,求你使我们回转, 叫你的恼恨向我们止息。
Yí wa padà, Ọlọ́run ìgbàlà wa, kí o sì yí ìbínú rẹ̀ padà kúrò lọ́dọ̀ wa.
5 你要向我们发怒到永远吗? 你要将你的怒气延留到万代吗?
Ìwọ yóò ha máa bínú sí wa títí láé? Ìwọ yóò ha mú ìbínú rẹ pẹ́ yí gbogbo ìran ká?
6 你不再将我们救活, 使你的百姓靠你欢喜吗?
Ìwọ kì yóò ha sọ wá jí padà mọ́, pé kí àwọn ènìyàn rẹ lè yọ nínú rẹ?
7 耶和华啊,求你使我们得见你的慈爱, 又将你的救恩赐给我们。
Fi ìfẹ́ rẹ tí kò le è kùnà hàn wá, Olúwa, kí o sì fún wa ní ìgbàlà rẹ.
8 我要听 神—耶和华所说的话; 因为他必应许将平安赐给他的百姓—他的圣民; 他们却不可再转去妄行。
Èmi ó gbọ́ ohun tí Olúwa Ọlọ́run yóò wí; ó ṣèlérí àlàáfíà fún àwọn ènìyàn rẹ̀, àní ẹni mímọ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí wọn padà sí àìmoye.
9 他的救恩诚然与敬畏他的人相近, 叫荣耀住在我们的地上。
Nítòótọ́ ìgbàlà rẹ̀ súnmọ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, pé kí ògo rẹ̀ kí ó lè gbé ní ilẹ̀ wa.
10 慈爱和诚实彼此相遇; 公义和平安彼此相亲。
Ìfẹ́ àti òtítọ́ parapọ̀; òdodo àti àlàáfíà fẹnu ko ara wọn.
11 诚实从地而生; 公义从天而现。
Òtítọ́ ń sun jáde láti ilẹ̀ wá òdodo sì bojú wolẹ̀ láti ọ̀run.
12 耶和华必将好处赐给我们; 我们的地也要多出土产。
Olúwa yóò fi ohun dídára fún ni nítòótọ́, ilẹ̀ wa yóò sì mú ìkórè rẹ̀ jáde.
13 公义要行在他面前, 叫他的脚踪成为可走的路。
Òdodo síwájú rẹ lọ o sì pèsè ọ̀nà fún ìgbésẹ̀ rẹ̀.

< 诗篇 85 >