< 以西結書 31 >

1 十一年三月一日,上主的話傳給我說:「
Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù kẹta ọdún kọkànlá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:
2 人子,你要向埃及王法郎和他的民眾說:你的偉大相似誰呢﹖
“Ọmọ ènìyàn, sọ fún Farao ọba Ejibiti àti sí ìjọ rẹ̀: “‘Ta ní a le fiwé ọ ní ọláńlá?
3 看,你是一棵黎巴嫩香柏,枝葉美觀,蔭影濃密,枝幹高大,樹梢插入雲霄。
Kíyèsi Asiria, tí ó jẹ́ igi kedari ni Lebanoni ní ìgbà kan rí, pẹ̀lú àwọn ẹ̀ka dáradára tí ó ṣẹ́ ìji bo igbó náà; tí ó ga sókè, òkè rẹ̀ lókè ni ewé tí ó nípọn wà.
4 水使它長大,淵泉使它長高;河水由四周流入栽植它之地,支流灌溉田中其他的樹木。
Omi mú un dàgbàsókè: orísun omi tí ó jinlẹ̀ mú kí o dàgbàsókè; àwọn odo rẹ̀ ń sàn yí ìdí rẹ̀ ká, ó sì rán ìṣàn omi rẹ̀ sí gbogbo igi orí pápá.
5 為此它的枝幹高過田間的一切樹木,因為水多,生長時枝業繁茂,枝條特長。
Nítorí náà ó ga sí òkè fíofío ju gbogbo igi orí pápá lọ; ẹ̀ka rẹ̀ pọ̀ sí i àwọn ẹ̀ka rẹ̀ sì gùn, wọn tẹ́ rẹrẹ nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi.
6 天上的一切飛鳥在它枝幹上築巢,田間的野獸在他的枝葉下生子,各國的人民住在它的蔭影下。
Ẹyẹ ojú ọ̀run kọ ilé sí ẹ̀ka rẹ̀ gbogbo ẹranko igbó ń bímọ ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀; gbogbo orílẹ̀-èdè ńlá ń gbé abẹ́ ìji rẹ̀.
7 它的枝葉廣闊,高大華麗,因為它的根深入多水之地。
Ọláńlá ní ẹwà rẹ̀ jẹ́, pẹ̀lú títẹ́ rẹrẹ ẹ̀ka rẹ̀, nítorí gbòǹgbò rẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ sí ibi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi wà.
8 天主樂園中的香柏,都不能同它相比,扁柏不及它的枝幹,楓樹不及它的枝椏,天主樂園中所有的樹木都沒有它那樣美麗。
Àwọn igi kedari nínú ọgbà Ọlọ́run kò lè è bò ó mọ́lẹ̀; tàbí kí àwọn igi junifa ṣe déédé pẹ̀lú ẹ̀ka rẹ̀, tàbí kí a fi igi títẹ́ rẹrẹ wé ẹ̀ka rẹ̀, kò sí igi nínú ọgbà Ọlọ́run tí ó dà bí rẹ̀ ní ẹwà rẹ̀.
9 我使它枝葉茂盛而美麗,致令「伊甸」──天主樂園──中所有的樹木都嫉妒它。
Mo mú kí ó ní ẹwà pẹ̀lú ẹ̀ka lọ́pọ̀lọ́pọ̀ tó fi jẹ́ ìlara àwọn igi gbogbo ní Edeni tí í ṣe ọgbà Ọlọ́run.
10 因此吾主上主這樣說:因它枝幹高大,枝梢插入雲霄,遂因自己高大而心高氣傲。
“‘Nítorí náà, èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Nítorí pé ó ga lọ sókè fíofío, tí ó sì gbé òkè rẹ̀ ga ju ewé tí ó nípọn lọ, àti nítorí pé gíga rẹ mú kí ó gbéraga,
11 我必將它交在列國最強的人手中,他們要任意對待它;我必要因它的罪行而將它剷除;
mo fi lé alákòóso àwọn orílẹ̀-èdè náà lọ́wọ́, fún un láti fi ṣe ẹ̀tọ́ fún un gẹ́gẹ́ bí ìwà búburú rẹ̀. Mo pa á tì sí ẹ̀gbẹ́ kan,
12 列國最兇殘的人必要將它伐倒,把它拋棄在山上;它的枝椏,倒臥在山谷中,枝條折落在一切窪地上;萬國的人民都要離開它的蔭影,而棄捨它;
àwọn orílẹ̀-èdè àjèjì aláìláàánú jùlọ ké e lulẹ̀, wọn sì fi kalẹ̀. Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ ṣubú sórí òkè àti sí gbogbo àárín àwọn òkè; àwọn ẹ̀ka rẹ̀ tí ó ṣẹ nà sílẹ̀ ní gbogbo àlàfo jíjìn ilẹ̀. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé jáde kúrò ní abẹ́ ìji rẹ̀ wọn sì fi sílẹ̀.
13 天上飛鳥都棲在它倒了的枝幹上,田間的各種野獸都停在它的枝條下,
Gbogbo àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ṣe àtìpó ni orí igi tí ó ṣubú lulẹ̀ náà, gbogbo àwọn ẹranko igbó wà ní àárín ẹ̀ka rẹ̀.
14 這是為使一切有水滋潤的樹木,不要因自己的軀幹高大而自負,不要再讓枝梢插入雲霄,免得各種有水滋潤的樹木,因高聳而自大,因為他們都要歸於死亡,降到陰間,到那些已降入深淵的人子中。 (questioned)
Nítorí náà kò sí igi mìíràn lẹ́gbẹ̀ẹ́ omi tí ó lè fi ìgbéraga ga sókè fíofío, tí yóò sì gbé sókè rẹ̀ ga ju ewé tí ó nípọn lọ. Kò sí igi mìíràn tí ó ní omi tó bẹ́ẹ̀ tí ó lè ga tó bẹ́ẹ̀; gbogbo wọn ni a kádàrá ikú fún, fún ìsàlẹ̀ ilẹ̀, ní àárín àwọn alààyè ènìyàn, pẹ̀lú àwọn tí o lọ sí ọ̀gbun ní ìsàlẹ̀.
15 吾主上主這樣說:在它下到陰府的那天,我要使人哀弔它;為了它我要使深淵閉塞,使江河凝結,洪水停流,使黎巴嫩為它舉哀,使田間所有的樹木因它而枯萎。 (Sheol h7585)
“‘Èyí ni Olúwa Olódùmarè wí: Ní ọjọ́ ti a mú u wá sí isà òkú mo fi ọ̀fọ̀ ṣíṣe bo orísun omi jíjìn náà, mo dá àwọn ìṣàn omi rẹ̀ dúró, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi rẹ̀ ní a dí lọ́nà. Nítorí rẹ̀ mo fi ìwúwo ọkàn wọ Lebanoni ní aṣọ, gbogbo igi igbó gbẹ dànù. (Sheol h7585)
16 當我使它下到陰府與已在深淵的人在一起時,也使列國因它下墜之聲而戰慄;那時「伊甸」中的各種樹木,黎巴嫩一切有水滋潤的華麗而高大的樹木,在陰間都感到安慰。 (Sheol h7585)
Mo mú kí orílẹ̀-èdè wárìrì sì ìró ìṣubú rẹ̀ nígbà tí mo mú un wá sí ìsàlẹ̀ isà òkú pẹ̀lú àwọn tí ó lọ sí ọ̀gbun ìsàlẹ̀. Nígbà náà gbogbo igi Edeni, àṣàyàn àti èyí tí ó dára jùlọ nínú Lebanoni, gbogbo igi tí ó ní omi dáradára ni a tù nínú ni ayé ìsàlẹ̀. (Sheol h7585)
17 那些在各國住在它蔭影下幫助過它的的人,也隨它下到陰府,同那喪身刀下的人在一起。「 (Sheol h7585)
Àwọn tí ó ń gbé ní abẹ́ òjìji rẹ̀, àwọn àjèjì rẹ ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè náà, ti lọ sí ìsàlẹ̀ isà òkú pẹ̀lú rẹ̀, ní dídárapọ̀ mọ́ àwọn tí a fi idà pa. (Sheol h7585)
18 伊甸」的樹木中,就華麗和高大說,你相似那一棵﹖你也要同「伊甸」的樹木一起被推入陰間,在未受割損的人中,同喪身刀下的人臥在一起:這是指法郎和他所有的人民說的──吾主上主的斷語。」 (questioned)
“‘Èwo lára igi Edeni ní a lè fiwé ọ ní dídán àti ọláńlá? Síbẹ̀ ìwọ, gan an wá sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn igi Edeni lọ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀; ìwọ yóò sùn ni àárín àwọn aláìkọlà, pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa. “‘Èyí yìí ní Farao àti ìjọ rẹ̀, ní Olúwa Olódùmarè wí.’”

< 以西結書 31 >