< 歷代志上 2 >
1 [以色列的十二子]以下是以色列的兒子:勒烏本、西默盎、肋未、猶大、依撒加爾、則步隆、
Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Israẹli. Reubeni, Simeoni, Lefi, Juda, Isakari, Sebuluni,
2 丹、若瑟、本雅明、納斐塔里、加得和阿協爾。[ 猶大的子孫]
Dani, Josẹfu, Benjamini; Naftali, Gadi: àti Aṣeri.
3 猶大的兒子:厄爾、敖難和舍拉。此三人是客納罕人叔亞的女兒所生。猶大的長子厄爾行了上主所厭惡的事,上主叫他死了。
Àwọn ọmọ Juda: Eri, Onani àti Ṣela, àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí ni wọ́n bí fún un láti ọ̀dọ̀ arábìnrin Kenaani, ọmọbìnrin Ṣua. Eri àkọ́bí Juda, ó sì burú ní ojú Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa sì pa á.
4 游阿的兒媳塔瑪爾給他生了培勒茲和則辣黑:猶大共有五個兒子。
Tamari, aya ọmọbìnrin Juda, ó sì bí Peresi àti Sera sì ní ọmọ márùn-ún ní àpapọ̀.
Àwọn ọmọ Peresi: Hesroni àti Hamulu.
6 則辣黑的兒子:齊默黎、厄堂、赫曼、加耳苛耳和達辣,共五人。
Àwọn ọmọ Sera: Simri, Etani, Hemani, Kalkoli àti Dara, gbogbo wọn jẹ́ márùn-ún.
7 加爾米的兒子:阿加爾,他違犯了毀滅律,使以色列受了害。
Àwọn ọmọ Karmi: Akani, ẹni tí ó mú ìyọnu wá sórí Israẹli nípa ẹ̀ṣẹ̀ ìfibú lórí mímú ohun ìyàsọ́tọ̀.
Àwọn ọmọ tí a bí fún Hesroni ni: Jerahmeeli, Ramu àti Kalebu.
10 蘭生阿米納達布,阿米納達布生納赫雄─猶大子孫的首領。
Ramu sì ni baba Amminadabu, àti Amminadabu baba Nahiṣoni olórí àwọn ènìyàn Juda.
Nahiṣoni sì ni baba Salmoni, Salmoni ni baba Boasi,
Boasi baba Obedi àti Obedi baba Jese.
13 葉瑟生長子厄里雅布,次子阿彼納達布,三子史默亞,
Jese sì ni baba Eliabu àkọ́bí rẹ̀; ọmọ ẹlẹ́ẹ̀kejì sì ni Abinadabu, ẹlẹ́ẹ̀kẹta ni Ṣimea,
ẹlẹ́ẹ̀kẹrin Netaneli, ẹlẹ́ẹ̀karùnún Raddai,
ẹlẹ́ẹ̀kẹfà Osemu àti ẹlẹ́ẹ̀keje Dafidi.
16 他們的姊妹是責魯雅和阿彼蓋耳。責魯雅生阿彼瑟、約阿布和阿撒耳三人。
Àwọn arábìnrin wọn ni Seruiah àti Abigaili. Àwọn ọmọ mẹ́ta Seruiah ni Abiṣai, Joabu àti Asaheli.
17 阿彼蓋耳生阿瑪撒;阿瑪撒的父親是依市瑪耳人耶特爾。
Abigaili ni ìyá Amasa, ẹni tí baba rẹ̀ sì jẹ́ Jeteri ará Iṣmaeli.
18 赫茲龍的兒子加肋布,由妻子阿組巴生耶黎敖特,她還生了耶舍爾、芍巴布和阿爾冬。
Kalebu ọmọ Hesroni ní ọmọ láti ọ̀dọ̀ ìyàwó rẹ̀ Asuba (láti ọ̀dọ̀ Jerioti). Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ rẹ̀: Jeṣeri, Ṣobabu àti Ardoni.
19 阿組巴死後,加肋布又娶了厄弗辣大,她生了胡爾。
Nígbà tí Asuba sì kú, Kalebu sì fẹ́ Efrata ní aya, ẹni tí ó bí Huri fún un.
Huri ni baba Uri, Uri sì jẹ́ baba Besaleli.
21 赫茲龍以後走近基肋阿得的父親瑪基爾的女兒,娶她時,已六十歲,她生了色古布。
Nígbà tí ó yá, Hesroni sì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú ọmọbìnrin Makiri baba Gileadi (ó sì ti fẹ́ ní aya láti ìgbà tí ó ti wà ní ẹni ọgọ́ta ọdún) ó sì bí Segubu.
22 色古布生雅依爾,他在基肋阿得佔有二十三座城市。
Segubu sì jẹ́ baba Jairi, ẹni tí ó jẹ́ olùdarí ìlú mẹ́tàlélógún ní ilẹ̀ Gileadi.
23 但以後革叔爾和阿蘭卻佔領了雅依爾的村落,以及刻納特和所屬的六十座村鎮:以上全是基肋阿得的父親瑪基爾的子孫。
(Ṣùgbọ́n Geṣuri àti Aramu sì fi agbára gba Hafoti-Jairi, àti Kenati pẹ̀lú gbogbo agbègbè rẹ̀ tí wọn tẹ̀dó sí jẹ́ ọgọ́ta ìlú.) Gbogbo wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Makiri baba Gileadi.
24 赫茲龍死後,加肋布走近父親的妻子厄弗辣大,她生了特科亞的父親阿市胡爾。
Lẹ́yìn tí Hesroni sì kú ni Kalebu Efrata, Abijah ìyàwó rẹ̀ ti Hesroni sì bí Aṣihuri baba Tekoa fún un.
25 赫茲龍的長子耶辣默耳的兒子:長子是蘭,其次是步納、敖楞、敖曾和阿希雅。
Ọmọ Jerahmeeli àkọ́bí Hesroni: Ramu ọmọ àkọ́bí rẹ̀ Buna, Oreni, Osemu àti Ahijah.
26 此外,耶辣默耳有另一個妻子,名叫阿塔辣,她是敖南的母親。
Jerahmeeli ní ìyàwó mìíràn, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Atara; ó sì jẹ́ ìyá fún Onamu.
27 耶辣默耳的長子蘭的兒子:瑪阿茲、雅明和厄刻爾。
Àwọn ọmọ Ramu àkọ́bí Jerahmeeli: Maasi, Jamini àti Ekeri.
28 敖南的兒子:沙買和雅達;沙買的兒子:納達布和阿彼叔爾。
Àwọn ọmọ Onamu: Ṣammai àti Jada. Àwọn ọmọ Ṣammai: Nadabu àti Abiṣuri.
29 阿彼叔爾的妻子名叫阿彼海耳,生子阿和班和摩里得。
Orúkọ ìyàwó Abiṣuri ni Abihaili ẹni tí ó bí Ahbani àti Molidi.
30 納達布的兒子:色肋得和阿帕殷;色肋得沒有兒子,死了。
Àwọn ọmọ Nadabu Seledi àti Appaimu. Seledi sì kú láìsí ọmọ.
31 阿帕殷的兒子:依史;依史的兒子:舍商;舍商的兒子:阿赫來。
Àwọn ọmọ Appaimu: Iṣi, ẹni tí ó jẹ́ baba fún Ṣeṣani. Ṣeṣani sì jẹ́ baba fún Ahlai.
32 沙買的兄弟雅達的兒子:耶特爾和約納堂;耶特爾沒有兒子,死了。
Àwọn ọmọ Jada, arákùnrin Ṣammai: Jeteri àti Jonatani. Jeteri sì kú láìní ọmọ.
33 約納堂的兒子:培肋特和匝匝以上:是耶辣默耳得子孫。
Àwọn ọmọ Jonatani: Peleti àti Sasa. Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Jerahmeeli.
34 舍商沒有兒子,只有女兒:舍商有個埃及僕人,名叫雅爾哈。
Ṣeṣani kò sì ní ọmọkùnrin àwọn ọmọbìnrin nìkan ni ó ní. Ó sì ní ìránṣẹ́ ará Ejibiti tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jariha.
35 舍商將女兒嫁給僕人雅爾哈為妻,給他生了阿泰。
Ṣeṣani sì fi ọmọ obìnrin rẹ̀ ní aya fún ìránṣẹ́ rẹ̀ Jariha, ó sì bí ọmọ fún tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ Attai.
Attai sì jẹ́ baba fún Natani, Natani sì jẹ́ baba fún Sabadi,
Sabadi ni baba Eflali, Eflali jẹ́ baba Obedi,
Obedi sì ni baba Jehu, Jehu ni baba Asariah,
Asariah sì ni baba Helesi, Helesi ni baba Eleasa,
Eleasa ni baba Sismai, Sismai ni baba Ṣallumu,
41 沙隆生耶卡米雅;耶卡米雅生厄里沙瑪。[加肋布的子孫]
Ṣallumu sì ni baba Jekamiah, Jekamiah sì ni baba Eliṣama.
42 耶辣默耳的兄弟加肋布的子孫:他的長子是瑪勒沙,他是齊弗的父親。瑪勒沙的兒子:赫貝龍。
Àwọn ọmọ Kalebu arákùnrin Jerahmeeli: Meṣa àkọ́bí rẹ̀, ẹni tí ó jẹ́ baba fún Sifi, àti àwọn ọmọ rẹ̀ Meraṣa, ẹni tí ó jẹ́ baba fún Hebroni.
Àwọn ọmọ Hebroni: Kora, Tapua, Rekemu, àti Ṣema.
Ṣema ni baba Rahamu, Rahamu sì jẹ́ baba fún Jorkeamu. Rekemu sì ni baba Ṣammai.
Àwọn ọmọ Ṣammai ni Maoni, Maoni sì ni baba Beti-Suri.
46 加肋布的妾厄法生哈郎;摩亞和加則次。哈郎生加則次。
Efani obìnrin Kalebu sì ni ìyá Harani, Mosa àti Gasesi, Harani sì ni baba Gasesi.
47 雅赫待的兒子:勒根、約堂、革商、培肋特、厄法和沙阿夫。
Àwọn ọmọ Jahdai: Regemu, Jotamu, Geṣani, Peleti, Efani àti Ṣaafu.
Maaka obìnrin Kalebu sì ni ìyá Seberi àti Tirhana.
49 又生了瑪德瑪納的父親沙阿夫、瑪革貝納和基貝亞的父親舍瓦;加肋布的女兒:阿革撒;
Ó sì bí Ṣaafu baba Madmana, Ṣefa baba Makbena àti baba Gibeah, ọmọbìnrin Kalebu sì ni Aksa.
50 以上是加肋布得子孫。厄弗辣大的長子胡爾的兒子:克黎雅特耶阿陵的父親芍巴耳、
Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Kalebu. Àwọn ọmọ Huri, àkọ́bí Efrata: Ṣobali baba Kiriati-Jearimu.
Salma baba Bẹtilẹhẹmu àti Harefu baba Beti-Gaderi.
52 克黎雅特耶阿陵的父親芍巴耳的兒子是:勒阿雅和半個部落瑪納哈特人;
Àwọn ọmọ Ṣobali baba Kiriati-Jearimu ni: Haroe, ìdajì àwọn ará Manaheti.
53 克黎雅特耶阿陵的家族是:耶特爾人、普特人、叔瑪人和米市辣人;從他們又生出祚辣人和厄市陶耳人。
Àti ìdílé Kiriati-Jearimu: àti àwọn ara Itri, àti àwọn ará Puti, àti àwọn ará Ṣumati àti àwọn ará Miṣraiti: láti ọ̀dọ̀ wọn ni àwọn ọmọ ará Sorati àti àwọn ará Eṣtaoli ti wá.
54 撒耳瑪的子孫是:白冷、乃托法人、阿托貝特、約阿布、一半部瑪納哈特人和祚辣人。
Àwọn ọmọ Salma: Bẹtilẹhẹmu, àti àwọn ará Netofa, Atrotu Beti-Joabu, ìdajì àwọn ará Manahati, àti ará Sori,
55 住在雅貝茲的色斐爾的家族是:提辣人、沙瑪人和穌加人:他們是刻尼人,貝特勒加布的父親哈瑪特的後代。
àti àwọn ìdílé àwọn akọ̀wé, ẹni tí ń gbé ní Jabesi: àti àwọn ọmọ Tirati àti àwọn ará Ṣimeati àti àwọn ará Sukati. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ará Keni, ẹni tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Hamati, baba ilé Rekabu.