< Книга Суддів 10 >
1 І став по Авімелехові на спасіння Ізраїля Тола, син Пуї, сина Додового, муж Іссахарів. І він сидів у Шамірі в Єфремових гора́х.
Lẹ́yìn ikú Abimeleki, ọkùnrin kan láti ẹ̀yà Isakari tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tola ọmọ Pua, ọmọ Dodo, dìde láti gba Israẹli sílẹ̀. Ní Ṣamiri tí ó wà ní òkè Efraimu ni ó gbé.
2 І судив він Ізраїля двадцять і три роки, та й помер, і був похо́ваний в Шамірі.
Ó ṣe àkóso Israẹli ní ọdún mẹ́tàlélógún. Nígbà tí ó kú wọ́n sìn ín sí Ṣamiri.
3 І став по ньому Яір ґілеадеянин, і судив Ізраїля двадцять і два роки.
Jairi ti ẹ̀yà Gileadi ni ó dìde lẹ́yìn rẹ̀, ó ṣàkóso Israẹli ní ọdún méjìlélógún.
4 І було в ньо́го тридцять синів, що їздили на тридцяти молодих ослах, а в них тридцять міст, — їх кличуть аж до цього дня: Яірові се́ла, що в ґілеадському кра́ї.
Àwọn ọgbọ̀n ọmọ tí ó n gun ọgbọ̀n kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Wọ́n ṣe àkóso ọgbọ̀n ìlú ní Gileadi, tí a pe orúkọ wọn ní Hafoti-Jairi títí di òní.
5 І помер Яір, і був похований в Камоні.
Nígbà tí Jairi kú wọ́n sin ín sí Kamoni.
6 А Ізраїлеві сини й далі чинили зло в Господніх оча́х, і служили Ваа́лам та Аста́ртам, і богам арамським, і богам сидонським, і богам моавським, і богам аммонських синів, і богам филисти́мським. І покинули вони Господа, і не служили Йому.
Àwọn ọmọ Israẹli sì túnṣe ohun tí ó burú lójú Olúwa. Wọ́n sin Baali àti Aṣtoreti àti àwọn òrìṣà Aramu, òrìṣà Sidoni, òrìṣà Moabu, òrìṣà àwọn ará Ammoni àti òrìṣà àwọn ará Filistini. Nítorí àwọn ará Israẹli kọ Olúwa sílẹ̀ tí wọn kò sì sìn ín mọ́,
7 І запалився Господній гнів на Ізраїля, і Він передав їх в ру́ку филисти́млян та в руку синів Аммонових.
ó bínú sí wọn, ó fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn ará Filistini àti Ammoni láti jẹ ẹ́ ní ìyà.
8 І вони били й мучили Ізраїлевих синів від того ро́ку, і гнобили вісімнадцять років усіх Ізраїлевих синів, що по той бік Йорда́ну в аморейському кра́ї, що в Ґілеаді.
Ní ọdún náà, wọ́n tú wọn ká wọ́n sì pọ́n wọn lójú. Fún ọdún méjìdínlógún ni wọ́n fi ni gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí ó wà ní ìlà-oòrùn odò Jordani ní ilẹ̀ àwọn ará Amori lára (èyí nì ní Gileadi).
9 І перейшли Аммонові сини Йорда́н, щоб воювати також з Юдою й з Веніями́ном та з Єфремовим домом. І Ізраїлеві було́ дуже тісно!
Àwọn ará Ammoni sì la odò Jordani kọjá láti bá Juda, Benjamini àti àwọn ará ilé Efraimu jagun: Israẹli sì dojúkọ ìpọ́njú tó lágbára.
10 І кли́кали Ізраїлеві сини до Господа, говорячи: „Згрішили ми Тобі, бо ми покинули свого Бога, і служили Ваа́лам“.
Nígbà tí èyí ti ṣẹlẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli ké pe Olúwa wí pé, “Àwa ti ṣẹ̀ sí ọ, nítorí pé àwa ti kọ Ọlọ́run wa sílẹ̀, àwa sì ń sin Baali.”
11 І сказав Господь до Ізраїлевих синів: „Чи ж не спас Я вас від Єгипту, і від аморе́янина, і від Аммо́нових синів, і від филисти́млян?
Olúwa sì dáhùn pé, “Ǹjẹ́ nígbà tí àwọn ará Ejibiti, Amori, Ammoni, Filistini,
12 А сидо́няни, і Амали́к, і Маон гноби́ли вас, і ви кли́кали до Мене, — і Я спас вас від їхньої руки.
àwọn ará Sidoni, Amaleki pẹ̀lú Maoni ni yín lára, tí ẹ sì ké pè mí fún ìrànlọ́wọ́, ǹjẹ́ èmi kò gbà yín sílẹ̀ kúrò ní ọwọ́ wọn?
13 А ви полишили Мене, і служили іншим бога́м, тому більше не спаса́тиму вас.
Síbẹ̀síbẹ̀ ẹ̀yin kọ̀ mí sílẹ̀ láti sin àwọn ọlọ́run mìíràn, torí ìdí èyí, èmi kì yóò sì tún gbà yín mọ́.
14 Ідіть, і кличте до тих богів, що ви вибрали їх, — вони спасуть вас у ча́сі вашого у́тиску“.
Ẹ lọ kí ẹ sì ké pe àwọn òrìṣà tí ẹ̀yin ti yàn fún ara yín. Jẹ́ kí wọn gbà yín sílẹ̀ ní àsìkò ìpọ́njú yín!”
15 І сказали Ізраїлеві сини до Господа: „Згрішили ми! Зроби Ти нам усе, як добре в оча́х Твоїх. Тільки спаси нас цього дня!“
Àwọn ọmọ Israẹli sì dá Olúwa lóhùn pé, “Àwa ti ṣẹ̀, ṣe ohun tí ó bá fẹ́ pẹ̀lú wa, ṣùgbọ́n, jọ̀wọ́ gbà wá sílẹ̀ náání àsìkò yìí.”
16 І повикидали вони з-поміж себе чужих богів, та й служили Господе́ві. І знетерпели́вилась душа Його через Ізраїлеве стражда́ння.
Nígbà náà ni wọ́n kó gbogbo ọlọ́run àjèjì tí ó wà láàrín wọn kúrò wọ́n sì sin Olúwa nìkan, ọkàn rẹ̀ kò sì le gbàgbé ìrora Israẹli mọ́.
17 А Аммонові сини були скли́кані, та й таборува́ли в Ґілеаді. І були зі́брані Ізраїлеві сини, та й таборува́ли в Міцпі.
Nígbà tí àwọn ará Ammoni kógun jọ ní Gileadi láti bá Israẹli jà, àwọn ọmọ Israẹli gbárajọpọ̀, wọ́n sì tẹ̀dó ogun ní Mispa.
18 І сказали той наро́д та ґілеадські князі, один до о́дного: „Хто той чоловік, що зачне воювати з Аммоновими сина́ми? Він стане головою для всіх ґілеадських ме́шканців“.
Àwọn ìjòyè: aṣíwájú àwọn ará Gileadi wí fún ará wọn pé, “Ẹnikẹ́ni tí yóò kọ́ ṣígun si àwọn ará Ammoni ni yóò jẹ́ orí fún gbogbo àwọn tí ń gbé ní Gileadi.”