< 1 царів 12 >
1 І пішов Рехав'а́м до Сихе́му, бо до Сихему зійшовся ввесь Ізраїль, щоб настанови́ти його царем.
Rehoboamu sì lọ sí Ṣekemu, nítorí gbogbo Israẹli ti lọ síbẹ̀ láti fi í jẹ ọba.
2 І сталося, що це почув Єровоа́м, Неватів син, коли був іще в Єгипті, куди втік від царя Соломона. І осівся Єровоам ув Єгипті.
Nígbà tí Jeroboamu ọmọ Nebati, tí ó wà ní Ejibiti síbẹ̀ gbọ́, nítorí tí ó ti sá kúrò níwájú Solomoni ọba, ó sì wà ní Ejibiti.
3 І послали й покликали його. І прийшов Єровоа́м та всі Ізраїлеві збори, і вони говорили до Рехав'ама, кажучи:
Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ránṣẹ́ sí Jeroboamu, òun àti gbogbo ìjọ Israẹli sì lọ sọ́dọ̀ Rehoboamu, wọ́n sì wí fún un pé,
4 „Твій батько вчинив був тяжки́м наше ярмо́, а ти тепер полегши́ жорсто́ку роботу батька свого та тяжке́ його ярмо, що наклав він був на нас, і ми бу́демо служити тобі“.
“Baba rẹ sọ àjàgà wa di wúwo, ṣùgbọ́n nísinsin yìí, mú kí ìsìn baba rẹ̀ tí ó le, àti àjàgà rẹ̀ tí ó wúwo, tí ó fi sí wa ní ọrùn kí ó fẹ́rẹ̀ díẹ̀, àwa yóò sì sìn ọ́.”
5 А він відказав їм: „Ідіть ще на три дні, і верніться до мене“. І пішов той народ.
Rehoboamu sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ ná títí di ọjọ́ mẹ́ta, nígbà náà ni kí ẹ padà tọ̀ mí wá.” Àwọn ènìyàn náà sì lọ.
6 І радився цар Рехав'а́м зо старши́ми, що стояли перед обличчям його батька Соломона, коли був він живий, говорячи: „Як ви радите відпові́сти цьому наро́дові?“
Nígbà náà ni Rehoboamu ọba fi ọ̀rọ̀ lọ àwọn àgbàgbà tí ń dúró níwájú Solomoni baba rẹ̀ nígbà tí ó wà láààyè. Ó sì béèrè pé, “Ìmọ̀ràn wo ni ẹ̀yin yóò gbà mí láti dá àwọn ènìyàn wọ̀nyí lóhùn?”
7 І вони говорили йому, кажучи: „Якщо ти сьогодні будеш рабом цьому наро́дові, і будеш служити їм, і відповіси́ їм, і говоритимеш їм добрі слова, то вони будуть тобі рабами по всі дні“.
Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Bí ìwọ yóò bá jẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí lónìí, kí o sì sìn wọ́n, àti kí o sì sọ ọ̀rọ̀ rere sí wọn nígbà tí ìwọ bá ń dá wọn lóhùn, wọn yóò máa ṣe ìránṣẹ́ rẹ títí láé.”
8 Та він відкинув пораду старших, що радили йому, і радився з молодика́ми, що виросли ра́зом із ним, що стояли перед ним.
Ṣùgbọ́n Rehoboamu kọ ìmọ̀ràn tí àwọn àgbàgbà fún un, ó sì fi ọ̀rọ̀ náà lọ àwọn ọmọdé tí wọ́n dàgbà pẹ̀lú rẹ̀, tí wọ́n sì ń sìn ín.
9 І сказав він до них: „Що́ ви радите, і що́ відповімо́ цьому́ наро́дові, який говорив мені, кажучи: Полегши́ ярмо́, що твій батько наклав був на нас“.
Ó sì bi wọ́n pé, “Kí ni ìmọ̀ràn yín? Báwo ni a ó ṣe dá àwọn ènìyàn yí lóhùn, tí wọ́n wí fún mi pé, ‘Ṣé kí àjàgà tí baba rẹ fi sí wa lọ́rùn kí ó fúyẹ́ díẹ̀’?”
10 І говорили до нього ті молодики́, що виросли з ним, кажучи: „Так скажеш тому наро́дові, що промовляв до тебе, говорячи: Твій батько вчинив був тяжки́м наше ярмо́, а ти дай полегшу нам. Отак скажеш до них: Мій мізи́нець грубший за сте́гна мого батька!
Àwọn ọmọdé tí ó dàgbà pẹ̀lú rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Sọ fún àwọn ènìyàn tí wọ́n wí fún ọ pé, ‘Baba rẹ̀ mú kí àjàgà wa wúwo ṣùgbọ́n ìwọ mú kí ó fúyẹ́ díẹ̀ fún wa’; sọ fún wọn pé, ìka ọwọ́ mi kékeré nípọn ju ẹ̀gbẹ́ baba mi lọ.
11 А тепер: мій батько наклав був на вас тяжке́ ярмо́, а я дода́м до вашого ярма! Батько мій карав вас бича́ми, а я каратиму вас скорпіо́нами!“
Baba mi ti gbé àjàgà wúwo lé e yín; Èmi yóò sì fi kún àjàgà yín. Baba mi ti fi pàṣán nà yín, Èmi yóò fi àkéekèe nà yín.”
12 І прийшов Єровоа́м та ввесь народ до Рехав'ама третього дня, як цар говорив, кажучи: „Верніться до мене третього дня“.
Jeroboamu àti gbogbo àwọn ènìyàn náà wá sọ́dọ̀ Rehoboamu ní ọjọ́ kẹta, gẹ́gẹ́ bí ọba ti wí pé, “Ẹ padà tọ̀ mí wá ní ọjọ́ kẹta.”
13 І цар жорсто́ко відповів народові, і відкинув пораду старши́х, що радили йому.
Ọba sì fi ohùn líle dá àwọn ènìyàn lóhùn, ó sì kọ ìmọ̀ràn tí àwọn àgbàgbà fún un,
14 І він говорив до них за порадою тих молодиків, кажучи: „Мій батько вчинив був тяжки́м ваше ярмо, а я дода́м до вашого ярма. Батько мій карав вас бича́ми, а я каратиму вас скорпіонами!“
Ó sì tẹ̀lé ìmọ̀ràn àwọn ọmọdé, ó sì wí pé, “Baba mí sọ àjàgà yín di wúwo, èmi yóò sì jẹ́ kí ó wúwo sí i, baba mi fi pàṣán nà yín èmi yóò fi àkéekèe nà yín.”
15 І не послухався цар народу, бо причина була від Господа, — щоб спра́вдилося слово Його, яке говорив був Господь через шілонянина Ахійю до Єровоама, Неватового сина.
Bẹ́ẹ̀ ni ọba kò sì fi etí sí ti àwọn ènìyàn, nítorí tí ọ̀ràn náà ti ọwọ́ Olúwa wá láti mú ọ̀rọ̀ tí ó sọ fún Jeroboamu ọmọ Nebati láti ẹnu Ahijah ará Ṣilo ṣẹ.
16 І побачив увесь Ізраїль, що цар не послухався їх, і народ відповів цареві, кажучи: „Яка нам части́на в Давиді? І спа́дщини нема нам у сині Єссе́я! До наметів своїх, о Ізраїлю! Позна́й тепер дім свій, Давиде!“І пішов Ізраїль до наметів своїх.
Nígbà tí gbogbo Israẹli rí i pé ọba kọ̀ láti gbọ́ ti àwọn, wọ́n sì dá ọba lóhùn pé, “Ìpín wo ni àwa ní nínú Dafidi, ìní wo ni àwa ní nínú ọmọ Jese? Padà sí àgọ́ rẹ, ìwọ Israẹli! Bojútó ilé ara rẹ, ìwọ Dafidi!” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ará Israẹli padà sí ilé wọn.
17 А Ізраїлеві сини, що сиділи в Юдиних містах, — тільки над ними зацарюва́в Рехав'а́м.
Ṣùgbọ́n fún ti àwọn ọmọ Israẹli tí ń gbé nínú ìlú Juda, Rehoboamu jẹ ọba lórí wọn síbẹ̀.
18 І послав цар Рехав'ам Адоніра́ма, що був над даниною, та ввесь Ізраїль заки́дав його́ камі́нням, і він помер. А цар Рехав'ам поспіши́в сісти на колесницю та втекти́ до Єрусалиму.
Ọba Rehoboamu rán Adoniramu jáde, ẹni tí ó wà ní ìkáwọ́ iṣẹ́ onírúurú, ṣùgbọ́n gbogbo Israẹli sọ ọ́ ní òkúta pa. Ọba Rehoboamu, gbìyànjú láti dé inú kẹ̀kẹ́ rẹ̀ ó sì sálọ sí Jerusalẹmu.
19 І збунтувався Ізраїль проти Давидового дому, і від нього відпав, і так є аж до цього дня.
Bẹ́ẹ̀ ni Israẹli ṣọ̀tẹ̀ sí ilé Dafidi títí di òní yìí.
20 І сталося, як увесь Ізраїль почув, що вернувся Єровоа́м, то послали й покликали його на збори, та й настанови́ли його царем над усім Ізраїлем. За домом Давида не було ніко́го, окрім одного Юдиного пле́мени.
Nígbà tí gbogbo Israẹli sì gbọ́ pé Jeroboamu ti padà dé, wọ́n ránṣẹ́, wọ́n sì pè é wá sí àjọ, wọ́n sì fi jẹ ọba lórí gbogbo Israẹli. Kò sí ẹnìkan tí ó tọ ilé Dafidi lẹ́yìn bí kò ṣe kìkì ẹ̀yà Juda nìkan.
21 І прийшов Рехав'а́м до Єрусалиму, і зібрав увесь Юдин дім та Веніяминове племе́но, сто й вісімдеся́т тисяч ви́браних військо́вих, щоб воювати з Ізраїлевим домом, щоб вернути царство Рехав'амо́ві, Соломоновому синові.
Nígbà tí Rehoboamu sì dé sí Jerusalẹmu, ó kó gbogbo ilé Juda jọ, àti ẹ̀yà Benjamini; ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ènìyàn tí a yàn, tí wọ́n ń ṣe ológun, láti bá ilé Israẹli jà àti láti mú ìjọba náà padà bọ̀ sọ́dọ̀ Rehoboamu, ọmọ Solomoni.
22 І було Боже слово до Шема́ї, чоловіка Божого, говорячи:
Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ Ṣemaiah ènìyàn Ọlọ́run wá wí pé,
23 „Скажи Рехав'амові, Соломоновому синові, цареві Юдиному, та всьому домові Юдиному й Веніяминовому, і решті народу, говорячи:
“Sọ fún Rehoboamu, ọmọ Solomoni, ọba Juda àti fún gbogbo ilé Juda àti ti Benjamini, àti fún àwọn ènìyàn tókù wí pé,
24 Так говорить Господь: Не йдіть і не воюйте з своїми брата́ми, Ізраїлевими синами! Верніться кожен до дому свого, бо ця річ сталася від Мене!“І вони послухалися Господнього слова, і вернулися, щоб піти за Господнім словом.
‘Báyìí ni Olúwa wí, “Ẹ má ṣe gòkè lọ láti bá àwọn arákùnrin yín jà, àwọn ènìyàn Israẹli. Kì olúkúlùkù yín padà sí ilé rẹ̀, nítorí nǹkan yìí láti ọ̀dọ̀ mi wá ni.”’” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, wọ́n sì tún padà sí ilé wọn, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa.
25 І збудував Єровоам Сихема в Єфремових гора́х, та й осівся в ньому. І вийшов він звідти, і збудував Пенуїла.
Nígbà náà ni Jeroboamu kọ́ Ṣekemu ní òkè Efraimu, ó sì ń gbé inú rẹ̀. Láti ibẹ̀ ó sì jáde lọ, ó sì kọ́ Penieli.
26 І сказав Єровоам у своєму серці: „Тепер ве́рнеться царство до Давидового дому!
Jeroboamu rò nínú ara rẹ̀ pé, “Ìjọba náà yóò padà nísinsin yìí sí ilé Dafidi.
27 Якщо наро́д цей буде ходити до Єрусалиму, щоб прино́сити жертви в Господньому домі, то ве́рнеться серце цього народу до їхнього пана, до Рехав'ама, царя Юдиного. І вони заб'ють мене, та й ве́рнуться до Рехав'ама, царя Юдиного“.
Bí àwọn ènìyàn wọ̀nyí bá gòkè lọ láti ṣe ìrúbọ ní ilé Olúwa ní Jerusalẹmu, wọn yóò tún fi ọkàn wọn fún Olúwa wọn, Rehoboamu ọba Juda. Wọn yóò sì pa mí, wọn yóò sì tún padà tọ Rehoboamu ọba Juda lọ.”
28 І порадився цар, і зробив два золоті тельці́, і сказав до народу: „До́сить вам ходити до Єрусалиму! Оце, Ізраїлю, бо́ги твої, що вивели тебе з єгипетського кра́ю“.
Lẹ́yìn tí ó ti gba ìmọ̀ràn, ọba sì yá ẹgbọrọ màlúù wúrà méjì. Ó sì wí fún àwọn ènìyàn pé, “Ó ti pọ̀jù fún yín láti máa gòkè lọ sí Jerusalẹmu. Àwọn Ọlọ́run yín nìyìí, Israẹli, tí ó mú yín láti ilẹ̀ Ejibiti wá.”
29 І поставив він одного в Бет-Елі, а одного в Дані.
Ó sì gbé ọ̀kan kalẹ̀ ní Beteli, àti èkejì ní Dani.
30 І була́ та річ на гріх, бо народ ходив до одно́го з них аж до Дану.
Nǹkan yìí sì di ẹ̀ṣẹ̀; àwọn ènìyàn sì lọ títí dé Dani láti sin èyí tí ó wà níbẹ̀.
31 І зробив він жертівне́ місце на па́гірку, і настановив священиків з усього народу, що не були з Левієвих синів.
Jeroboamu sì kọ́ ojúbọ sórí ibi gíga, ó sì yan àwọn àlùfáà láti inú àwọn ènìyàn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í ṣe inú àwọn ọmọ Lefi.
32 І встановив Єровоам свято в восьмому місяці, п'ятнадцятого дня місяця, подібне до свята, що в Юді, — і прино́сив жертву на жертівнику. Так зробив він у Бет-Елі, щоб прино́сити в жертву тельцям, які він зробив. І настановив він у Бет-Елі священиків па́гірків, що поробив.
Jeroboamu sì dá àsè sílẹ̀ ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù kẹjọ gẹ́gẹ́ bí àsè tí ó wà ní Juda, ó sì rú ẹbọ lórí pẹpẹ. Ó ṣe èyí ní Beteli, ó rú ẹbọ sí àwọn ọmọ màlúù tí ó ṣe. Ó sì fi àwọn àlùfáà sí ibi gíga tí ó ti ṣe sí Beteli.
33 І прино́сив він жертви на жертівнику, що зробив у Бет-Елі, п'ятнадцятого дня восьмого місяця, якого ви́мислив з свого серця. І вчинив він свято для Ізраїлевих синів, і підійшов до же́ртівника, щоб покадити.
Ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù kẹjọ, oṣù tí ó rò ní ọkàn ara rẹ̀, ó sì rú ẹbọ lórí pẹpẹ tí ó kọ́ ní Beteli. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì dá àsè sílẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli, ó sì gun orí pẹpẹ náà lọ láti rú ẹbọ.