< Amos 5 >

1 Hear this word that I am bearing to you, A lamentation, O house of Israel:
Gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ìwọ ilé Israẹli, ìpohùnréré ẹkún tí mo ṣe nípa rẹ:
2 'Fallen, not again to rise, hath the virgin of Israel, Left on her land — she hath no raiser up.'
“Wúńdíá Israẹli ṣubú láì kò sì le padà dìde ó di ẹni ìkọ̀tì ní ilẹ̀ rẹ̀ kò sí ẹni tí yóò gbé e dìde.”
3 For thus said the Lord Jehovah: The city that is going out a thousand, Doth leave an hundred, And that which is going out an hundred, Doth leave ten to the house of Israel.
Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: “Ìlú tí ẹgbẹ̀rún alágbára ti jáde, yóò dín ku ọgọ́rùn-ún ní Israẹli. Ìlú tí ọgọ́rùn-ún alàgbà ti jáde yóò ṣẹ́kù ẹni mẹ́wàá.”
4 For thus said Jehovah to the house of Israel: Seek ye Me, and live,
Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún ilé Israẹli: “Wá mi kí o sì yè;
5 And seek not Beth-El, and Gilgal enter not, And Beer-Sheba pass not through, For Gilgal doth utterly remove, And Beth-El doth become vanity.
ẹ má ṣe wá Beteli, ẹ má ṣe lọ sí Gilgali, ẹ má ṣe rìnrìn àjò lọ sí Beerṣeba. Nítorí dájúdájú a ó kó Gilgali ní ìgbèkùn, A ó sì sọ Beteli di asán.”
6 Seek ye Jehovah, and live, Lest He prosper as fire [against] the house of Joseph, And it hath consumed, And there is no quencher for Beth-El.
Ẹ wá Olúwa, ẹ̀yin yóò sì yè, kí ó má ba à gbilẹ̀ bí iná ní Josẹfu a sì jó o run Beteli kò sì ní rí ẹni tí yóò bu omi pa á.
7 Ye who are turning to wormwood judgment, And righteousness to the earth have put down,
Ẹ̀yin tí ẹ̀ sọ òdodo di ìkorò tí ẹ sì gbé olódodo ṣánlẹ̀.
8 The maker of Kimah and Kesil, And the turner to morning of death-shade, And day [as] night He hath made dark, Who is calling to the waters of the sea, And poureth them on the face of the earth, Jehovah [is] His name;
Ẹni tí ó dá ìràwọ̀ Pleiadesi àti Orioni ẹni tí ó sọ òru dúdú di òwúrọ̀ tí ó sọ ọjọ́ dúdú di ìmọ́lẹ̀ ẹni tí ó wọ́ omi Òkun jọ pọ̀ tí ó sì rọ̀ wọ́n sí orí ilẹ̀ Olúwa ni orúkọ rẹ̀,
9 Who is brightening up the spoiled against the strong, And the spoiled against a fortress cometh.
Ó fọ́n ìparun sí ìlú olódi tí ó sì sọ àwọn ibùgbé àwọn ọmọ-aládé di ahoro.
10 They have hated a reprover in the gate, And a plain speaker they abominate.
Ìwọ kórìíra ẹni tí ń bá ni wí ní ẹnu ibodè ó sì ń pẹ̀gàn ẹni tí ń sọ òtítọ́.
11 Therefore, because of your trampling on the poor, And the tribute of corn ye take from him, Houses of hewn work ye have built, And ye do not dwell in them, Desirable vineyards ye have planted, And ye do not drink their wine.
Ìwọ ń tẹ tálákà mọ́lẹ̀ o ń fi ipá gba ọkà lọ́wọ́ wọn. Nítorí náà, ìwọ ti fi òkúta tí a gbẹ́ kọ́lé ṣùgbọ́n ẹ kò sì ní gbé inú wọn, Nítòótọ́ ìwọ ti gbin ọgbà àjàrà tí ó lẹ́wà. Ìwọ kò ní mu wáìnì inú wọn.
12 For I have known — many [are] your transgressions, And mighty your sins, Adversaries of the righteous, taking ransoms, And the needy in the gate ye turned aside.
Nítorí mo mọ iye àìṣedéédéé rẹ mo sì mọ bí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ tí tóbi tó. Ìwọ ni olódodo lára, ìwọ sì ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ o sì ń fi òtítọ́ du tálákà ní ilé ẹjọ́.
13 Therefore is the wise at that time silent, For an evil time it [is].
Àwọn ọlọ́gbọ́n máa ń dákẹ́ jẹ́ẹ́ ní àkókò wọ̀nyí, nítorí búburú ni gbogbo ọjọ́.
14 Seek good, and not evil, that ye may live, And it is so; Jehovah, God of Hosts, [is] with you, as ye said.
Wá rere, má ṣe wá búburú kí ìwọ ba à le yè. Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun yóò wà pẹ̀lú rẹ. Òun yóò sì wà pẹ̀lú rẹ bí ìwọ ṣe wí.
15 Hate evil, and love good, And set up judgment in the gate, It may be Jehovah, God of Hosts, doth pity the remnant of Joseph.
Kórìíra búburú kí o sì fẹ́ rere dúró ní orí òtítọ́ ní ilé ẹjọ́ bóyá Olúwa Ọlọ́run alágbára yóò síjú àánú wo ọmọ Josẹfu tó ṣẹ́kù.
16 Therefore, thus said Jehovah, God of Hosts, the Lord, In all broad places [is] lamentation, And in all out-places they say, 'Alas, alas,' And called the husbandman to mourning, And to lamentation the skilful of wailing.
Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun wí: “Ẹkún yóò wà ní àwọn òpópónà igbe ìnira yóò sì wà ní àwọn gbàgede ìlú. A ó kó àwọn àgbẹ̀ jọ láti sọkún àti àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ láti pohùnréré ẹkún.
17 And in all vineyards [is] lamentation, For I pass into thy midst, said Jehovah.
Ìpohùnréré ẹkún yóò wà ní gbogbo ọgbà àjàrà, nítorí èmi yóò la àárín yín kọjá,” ni Olúwa wí.
18 Ho, ye who are desiring the day of Jehovah, Why [is] this to you — the day of Jehovah? It is darkness, and not light,
Ègbé ni fún ìwọ tí ó pẹ́ nítorí ọjọ́ Olúwa kí ni ìwọ fi pẹ́ fún ọjọ́ Olúwa? Ìmọ́lẹ̀ yóò di òkùnkùn ní ojú ọjọ́.
19 As [when] one fleeth from the face of the lion, And the bear hath met him, And he hath come in to the house, And hath leant his hand on the wall, And the serpent hath bitten him.
Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí ó sá fún kìnnìún, tí ó padà wá bọ́ sí ẹnu àmọ̀tẹ́kùn. Yóò dàbí ẹni tí ó wọ ilé rẹ̀ lọ tí ó sinmi lé ògiri ilé rẹ̀ tí ejò sì bù ú ṣán.
20 Is not the day of Jehovah darkness and not light, Even thick darkness that hath no brightness?
Ǹjẹ́ ọjọ́ Olúwa kò ha ní ṣókùnkùn dípò kí ó ní ìmọ́lẹ̀? Tí yóò sì ṣókùnkùn dúdú láìsí ìmọ́lẹ̀ kankan níbẹ̀.
21 I have hated — I have loathed your festivals, And I am not refreshed by your restraints.
“Mo kórìíra, mo kẹ́gàn àwọn àsè ẹ̀sìn in yín, Èmi kò sì ní inú dídùn sí àpéjọ yín.
22 For though ye cause burnt-offerings and your presents to ascend to Me, I am not pleased, And the peace-offering of your fatlings I behold not.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ mú ẹbọ sísun àti ọrẹ ọkà wá. Èmi kò ní tẹ́wọ́ gbà wọ́n. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ mú àṣàyàn ọrẹ àlàáfíà wá. Èmi kò ní náání wọn.
23 Turn aside from Me the noise of thy songs, Yea, the praise of thy psaltery I hear not.
Ẹ gbé ariwo orin yín sẹ́yìn! Èmi kò ní fetísí ohun èlò orin yín.
24 And roll on as waters doth judgment, And righteousness as a perennial stream.
Jẹ́ kí òtítọ́ sàn bí odò àti òdodo bí ìsun tí kò lé è gbẹ!
25 Sacrifices and offering did ye bring nigh to Me, In a wilderness forty years, O house of Israel?
“Àbí ẹ̀yin mú ẹbọ àti ọrẹ tọ̀ mí wá ní ogójì ọdún ní aginjù ìwọ ilé Israẹli?
26 And ye bare Succoth your king, and Chiun your images, The star of your god, that ye made for yourselves.
Ẹ̀yin ti gbé ibi ìrúbọ àwọn ọba yín sókè, ibùgbé àwọn òrìṣà yín, àní, ti àwọn òrìṣà yín tí ó níyì jùlọ, èyí tí ẹ̀yin fi ọwọ́ ara yín ṣe.
27 And I removed you beyond Damascus, Said Jehovah, God of Hosts [is] His name.
Nítorí náà èmi yóò rán an yín lọ sí ìgbèkùn ní ìkọjá Damasku,” ni Olúwa wí, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ọlọ́run alágbára.

< Amos 5 >