< Psalms 90 >
1 A Prayer of Moses the man of God. Lord, you have been our refuge in all generations.
Àdúrà Mose ènìyàn Ọlọ́run. Olúwa, ìwọ ti jẹ́ ibùgbé wa ní gbogbo ìran dé ìran.
2 Before the mountains existed, and [before] the earth and the world were formed, even from age to age, You are.
Kí a tó bí àwọn òkè ńlá àti kí ìwọ tó dá ilẹ̀ àti ayé, láti ayérayé dé ayérayé ìwọ ni Ọlọ́run.
3 Turn not man back to [his] low place, whereas you said, Return, you sons of men?
Ìwọ yí ènìyàn padà sí erùpẹ̀, wí pé, “Padà sí erùpẹ̀, ìwọ ọmọ ènìyàn.”
4 For a thousand years in your sight are as the yesterday which is past, and as a watch in the night.
Nítorí pé ìgbà tí ẹgbẹ̀rún ọdún bá kọjá lójú rẹ, bí àná ni ó rí, bí ìgbà ìṣọ́ kan lóru.
5 Years shall be vanity to them: let the morning pass away as grass.
Ìwọ gbá ènìyàn dànù nínú oorun ikú; wọ́n dàbí koríko tuntun ní òwúrọ̀.
6 In the morning let it flower, and pass away: in the evening let it droop, let it be withered and dried up.
Lóòtítọ́, ní òwúrọ̀, ó yọ tuntun ní àṣálẹ́ ni yóò gbẹ, tí yóò sì rẹ̀ dànù.
7 For we have perished in your anger, and in your wrath we have been troubled.
A pa wá run nípa ìbínú rẹ nípa ìbínú rẹ ara kò rọ̀ wá.
8 You have set our transgressions before you: our age is in the light of your countenance.
Ìwọ ti gbé ẹ̀ṣẹ̀ wa ka iwájú rẹ, àti ohun ìkọ̀kọ̀ wa nínú ìmọ́lẹ̀ iwájú rẹ.
9 For all our days are gone, and we have passed away in your wrath: our years have spun out their tale as a spider.
Gbogbo ọjọ́ wa ń kọjá lọ lábẹ́ ìbínú rẹ; àwa ń lo ọjọ́ wa lọ bí àlá tí à ń rọ́.
10 [As for] the days of our years, in them are seventy years; and if [men should be] in strength, eighty years: and the greater part of them would be labor and trouble; for weakness overtakes us, and we shall be chastened.
Àádọ́rin ọdún ni iye ọjọ́ ọdún wá, bi ó sì ṣe pé nípa agbára tí wọn bá tó ọgọ́rin ọdún, agbára nínú làálàá pẹ̀lú ìbànújẹ́ ni, nítorí pé a kò ní pẹ́ gé e kúrò, àwa a sì fò lọ.
11 Who knows the power of your wrath?
Ta ni ó mọ agbára ìbínú rẹ? Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rù rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ìbínú rẹ.
12 and [who knows how] to number [his days] because of the fear of your wrath? So manifest your right hand, and those that are instructed in wisdom in the heart.
Kọ́ wa bí a ti ń kaye ọjọ́ wa dáradára, kí àwa ba à lè fi ọkàn wa sípa ọgbọ́n.
13 Return, O Lord, how long? and be entreated concerning your servants.
Yípadà, Olúwa! Yóò ti pẹ́ tó? Ṣàánú fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ.
14 We have been satisfied in the morning with your mercy; and we did exult and rejoice:
Tẹ́ wa lọ́rùn ní òwúrọ̀ nínú ìṣeun ìfẹ́ rẹ, kí àwa kí ó lè kọrin fún ayọ̀ kí inú wa sì dùn ní gbogbo ọjọ́.
15 let us rejoice in all our days, in return for the days wherein you did afflict us, the years wherein we saw evil.
Mú inú wa dùn bí ọjọ́ tí ìwọ ti pọ́n wa lójú, fún ọjọ́ púpọ̀ tí àwa ti rí wàhálà.
16 And look upon your servants, and upon your works; and guide their children.
Jẹ́ kí a fi iṣẹ́ rẹ̀ han àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, ògo rẹ̀ sí àwọn ọmọ wọn.
17 And let the brightness of the Lord our God be upon us: and do you direct for us the works of our hands.
Jẹ́ kí ẹwà Olúwa Ọlọ́run wa wà lára wa; fi ìdí iṣẹ́ ọwọ́ wa múlẹ̀ lára wa, bẹ́ẹ̀ ni, kí ó sì fi ìdí iṣẹ́ ọwọ́ wa múlẹ̀.